Àwọn kan dáná sun àpótí ìbò ní America

Àkọlé fídíò, Wo fọnran bí apoti ibo ṣe gbana
    • Author, Merlyn Thomas and Mike Wendling
    • Role, BBC Verify and BBC News
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ FBI lorilẹede Amẹrika ti bẹrẹ iwadii lẹyin ti apoti ibo meji gbana ni agbegbe Portland, Oregon ni ọjọ Aje.

Ọpọ ibo ni wọn dana sun ni Vancouver, ilu kekere kan ni Washington to jẹ kilomita mẹwaa si Portland, ti awọn ileeṣẹ iroyin abẹle si ni wọn fi ado oloro sinu apoti ibo.

Ẹwẹ, ní guusu ìwọ oorun Portland, wọn sawari ado oloro kekere kan ninu apoti ibo to dana sun ibo.

Ileeṣẹ Ọlọpaa lasiko ti wọn ba awọn akọroyin sọrọ lọjọ Aje ni, iṣẹlẹ mejeeji naa ni ajọsepọ ti wọn si jọ ohun to waye ni ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹwaa lasiko ibo.

Iru ibo ti wọn n di lọwọ yii lo fun awọn oludibo ni anfaani lati dibo saaju ki eto idibo to waye.

Ni oṣu Kẹsan an, ẹka to n risi eto aabo ṣe ikilọ pe awọn eeyan kan lori ayelujara n gbero lati da eto alaafia ibo laamu saaju kí ọjọ idibo to waye.

Greg Kimsey, oṣiṣẹ to n risi eto idibo ni awọn ti rọpo awọn apoti ibo ti o bajẹ, ti awọn osisẹ si ti bẹrẹ iṣẹ lati ṣawari awọn ibo to jona.

Awọn ọlọpaa sọ fun BBC pe awọn ẹsọ alabo ti wa ni gbogbo ayika agbegbe naa, wọn si tun sẹ afihan aworan ọkọ ayọkẹlẹ awọn afurasi iṣẹlẹ naa.

"A n sisẹ lati ri pe iṣẹlẹ ko waye mọ," Kimsey salaye.

Bakan naa ni awọn alaṣẹ ni awọn ti n sisẹ lati kan si awọn oludibo lati wa tun ibo wọn di.