Ṣé ìbò àwọn ọmọ Amẹ́ríkà tó ń gbé ilẹ̀ òkèrè le nípa lórí èsì ìbò tó ń bọ̀?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Fernando Duarte
- Role, BBC World Service
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kọkànlá tí ètò ìdìbò sípò ààrẹ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà yóò wáyé ti ń súnmọ́ etílé.
Àwọn ìdìbò lórí ayélujára ń ṣàfihàn pé ìyàtọ́ díẹ̀ ló wà láàárín Kamala Harris, igbákejì ààrẹ Amẹ́ríkà tó ń díje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Democrat àti Donald Trump tó ń díje lẹ́gbẹ́ òṣèlú Republican.
Àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà tó ń gbé ní orílẹ̀ èdè mìíràn ni wọ́n ní ẹ̀tọ́ láti dìbò lásìkò ètò ìdìbò náà níwọ̀n ìgbà tí ọjọ́ orí wọn bá ti kọjá ọdún méjìdínlógún.
Lára àwọn ọmọ Amẹ́ríkà tó ń gbé orílẹ̀ èdè mìíràn ni Katie Benson tó ní láti ìgbà tí òun ti wà ní ọmọ ọdún méjìlá ni ó ti ń wu òun láti dìbò. Ó ní ọdún 2016 ni òun àti ìyá òun ti rò pé àwọn máa ní obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò jẹ́ ààrẹ Amẹ́ríkà nígbà tí Hilary Clinton díje dupò náà.
Katie Benson tó ń kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ Geography ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Cambridge, UK ní ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún òun nígbà tí wọ́n kéde Trump gẹ́gẹ́ bí ààrẹ, tí ètò ìdìbò náà sì jẹ́ ìtanijí fún òun láti túnbọ̀ mọ̀ nípa ètò òṣèlú Amẹ́ríkà.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orílẹ̀ èdè Britain ni wọ́n bí Benson sí àmọ́ tó ní ìwé ìgbélú Amẹ́ríkà lọ́wọ́. Ó ti pé ẹni ogún báyìí, tó sì dìbò fún ìgbà àkọ́kọ́ nígbà tó kópa orí ayélujára nínú oṣù Kẹsàn-án.
Ó ní òun ri ní dandan láti kópa nínú ètò ìdìbò náà fún ọjọ́ ọ̀la Amẹ́ríkà.
Àwọn ẹbí ìyá rẹ̀, tó máa ń ṣe àbẹ̀wò sí ní gbogbo ìgbà, ń gbé ní ìpínlẹ̀ Wisconsin. Ibẹ̀ sì ni ìbò tí ó bá dì máa kà sí gẹ́gẹ́ bí òfin ìdìbò Amẹ́ríkà ṣe là á kalẹ̀.
Wisconsin wà lára àwọn ìpínlẹ̀ alágbára méje tó máa ń ṣe àfihàn ẹni tí yóò wọlé ìbò ní Amẹ́ríkà. Àwọn ìpínlẹ̀ yòókù ni Arizona, Georgia, Michigan, Nevada, North Carolina àti Pennsylvania.
Ààlà ìbò
Nínú ètò ìdìbò Amẹ́ríkà, ààrẹ kìí gbégbá orókè nípa níní ìbò tó pọ̀ jùlọ bíkòṣe bíborí àwọn ìbò ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan.
Ohun tí wọ́n ń pè ní “electoral college” ni wọ́n fi máa ń mọ ẹni tó bá borí ìbò ní Amẹ́ríkà. Èyí tó túmọ̀ sí pé ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní iye ìbò tí olùdíje kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan bí ìpínlẹ̀ náà bá ṣe tóbi sí. Olùdíje tó bá ní ìbò 270 nínú ìbò 538 electoral college ló wọlé gẹ́gẹ́ bí ààrẹ.

Ó hàn gbangba bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpínlẹ̀ ṣe máa ń dìbò wọn àmọ́ àwọn ìpínlẹ̀ méje, tó jẹ́ ojú ogun gangan máa ń yípadà nígbàkúgbà.
Ìgbìmọ̀ Democratic National Committee ní mílíọ̀nù èèyàn ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà tó ń gbé orílẹ̀ èdè mìíràn ló lẹ́tọ̀ọ́ láti dìbò ní àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n wà.
Àmọ́ tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa iye èèyàn tí yóò dìbò, díẹ̀ àlàbá nínú ìbejì ni ọ̀rọ̀ àwọn tó ń gbé nílẹ̀ òkèrè jẹ́ tí a bá fi wé mílíọ̀nù 161 èèyàn tó dìbò lọ́dún 2016. Àwọn èèyàn tó dìbò láti ilẹ̀ òkèrè nígbà náà kò tó 900,000.
Ìgbà mìíràn náà sì wà tí ìbò àwọn tó wà nílẹ̀ òkèrè ti ṣe ìrànwọ́ fún olùdíje láti jẹ́ kó lékè nínú ìbò.
Ètò ìdìbò Bush àti Gore
Ọ̀jọ̀gbọ́n Jay Sexton tó jẹ́ adarí ní ẹ̀ka Kinder Institute on Constitutional Democracy ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Missouri, US ní àwọn olùdìbò tó wà ní ilẹ̀ òkperpe ti ṣàfihàn lọ́pọ̀ ìgbà pé wọ́n ní ipá lórí ìbò pàápàá nígbà tí ìbò àwọn olùdíje bá súnmọ́ ara wọn.
Lára irófẹ́ bẹ́ẹ̀ tó ti wáyé ni ìbò ààrẹ ọdún 2000 láàárín George Bush àti Al Gore. Ìbò ìpínlẹ̀ Florida tó súnmọ́ ara wọn nígbà náà ló yẹ kó sọ ẹni tọ jáwé olúborí nígbà náà.
Lẹ́yìn tí wọ́n tún àwọn ìbò náà kà fún ọ̀pọ̀ ìgbà, àtàwọn ìgbésẹ̀ òfin tó wáyé lẹ́yìn rẹ̀, ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Amẹ́ríkà kéde pé Bush ló gbégbá orókè ní Florida àti ètò ìdìbò náà lápapọ̀ pẹ̀lú ìyàtọ̀ ìbò 537.
Lásìkò tí àtúnkà ìbò náà ń wáyé ni àwọn ìbò tún ń wọlé láti ilẹ̀ òkèrè tí wọ́n sì ń kà wọ́n papọ̀ – àwọn awuyewuye kan wáyé pé kí wọ́n má ka àwọn ìbò náà fáwọn ìdí pé wọ́n pẹ́ kí wọ́n tó dé tàbí pé àwọn àmì iléeṣẹ́ tó pín wọn kò tọ̀nà.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọ̀jọ̀gbọ́n Sexton ní tó bá jẹ́ pé àwọn ìbò ìpínlẹ̀ Florida nìkan ni wọ́n kà, ó ṣeéṣe kí Gore gbégbá orókpe níbi ìdìbò náà pẹ̀lú ìbò 202.
Ní ọdún 2020, ààrẹ Joe Biden borí ìbò ní àwọn ìpínlẹ̀ méjì tí ẹgbẹ́ òṣèlú Republican ti máa ń ní ìbò púpọ̀ ìyẹn Georgia àti Arizona.
Sharon Manitta tó jẹ́ olùpolongo ìbò fún ẹgbẹ́ òṣèlú Democrats nílẹ̀ òkèrè ní ìwádìí ti fi hàn pé àwọn ìbò ilẹ̀ òkèrè máa ń ní ipa tó pọ̀ lórí ìbò.
Ààrẹ Biden borí ìbò ní Arizona pẹ̀lú ìbò 10,457 àti Georgia pẹ̀lú ìbò 11,719. Àwọn ọmọ Amẹ́ríkà tó ń gbé nílẹ̀ òkèrè ló di ìbò 18,000 ní àwọn ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan yìí.
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Democrats tó wà nílẹ̀ òkèrè ni wọ́n ti rí owó tó lé ní $300,000 gbà látọwọ́ ẹgbẹ́ náà láti fi ṣe ìpolongo fún àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà tó wà nílẹ̀ òkèrè láti kópa nínú ètò ìdìbò ọdún yìí pàápàá ní àwọn orílẹ̀ èdè táwọn ọmọ Amẹ́ríkà pọ̀ sí bíi Canada, Mexico, Uk àti Israel.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Greg Swenson tó jẹ́ alága fún ẹgbẹ́ Republican tó wà nílẹ̀ òkèrè, ẹgbẹ́ tó ń ṣe ìpolongo fáwọn èèyàn tó wà nílẹ̀ òkèrè láti dìbò fún Trump, ní àwọn ń gbìyànjú.
Ó ní àwọn ń sa ipá àwọn láti ri pé àwọn ológun tó wà nílẹ̀ òkèrè dìbò fún ọmọ ẹgbẹ́ àwọn. Ìtàn fi hàn pé ẹgbẹ́ Republican ni àwọn ológun sábà máa ń ṣe àtìlẹyìn fún.
Swenson ní kò ní bá òun lójijì tí ẹgbẹ́ Democrats bá rí ìbò tó pọ̀ jùlọ láti ilẹ̀ òkèrè àmọ́ àwọn èèyàn ti ń ṣe àtìléyìn fẹ́gbẹ́ Republican báyìí láti ilẹ̀ òkèrè kódà tó fi mọ́ àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìbò fún ìgbà àkọ́kọ́.
Lára àwọn èèyàn yìí ni Chris tó ti ń gbé ní ilẹ̀ òkèrè láti ọdún mẹ́ẹ̀dógún sẹ́yìn. Ó ní òun kò dìbò rí láti ìgbà tí òun ti wà nílẹ̀ òkèrè bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ń ṣe àtìlẹyìn fún Trump àma òun ti bèèrè láti dìbò níbi ètò ìdìbò yìí.
Ó ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ń kojú wàhálà ọ̀wọ́n gógó lásìkò yìí tó nílò àmójútó kíákíá. “Mo mọ̀ pé Trump kò lè ṣe é tán àmọ́ ó sàn ju Harris láti kojú àwọn ìṣòro yìí.”
Kò sí ọmọ Republican tó ti gbégbá orókè ní New Jersey rí láti ọdún 1988 àmọ́ Chris gbàgbọ́ pé àwọn èèyàn le ní irú ìròrí òun, kí wọ́n dìbò fún wọn lọ́tẹ̀ yìí.
“Mo gbàgbọ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe àtìlẹyìn fún Trump àma tí wọn kò sọ ọ́ jáde.”

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìpejọ́
Ọ̀rọ̀ ìbò àwọn tó ń gbé orílẹ̀ èdè òkèrè ti ń fa awuyewuye tó pọ̀ níbi ètò ìdìbò yìí bí ẹgbẹ́ Republicans ṣe ti pe ẹjọ́ ní ìpínlẹ̀ mẹ́ta lórí ọ̀rọ̀ náà.
Ní North Carolina àti Michigan, àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan ni pé báwo ni ẹni tó ń gbé ilẹ̀ òkèrè má ṣe ni àǹfàní láti dìbò ní ìpínlẹ̀ tí kò gbé rí àmọ́ táwọn ẹbí wọn ń gbé. Àwọn adájọ́ ti da ẹjọ́ náà nù àmọ́ Republicans ní àwọn máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.
Ní Pennsylvania, ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn ni pé àwọn aláṣẹ kò máa ṣe ìwádìí tó láti ṣàyẹ̀wò àwọn olùdìbò ilẹ̀ òkèrè náà.
Àwọn aṣòfin ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Democrats fẹ̀sùn kan ẹgbẹ́ Republicans pé wọ́n fẹ́ fi àwọn ẹjọ́ tí wọ́n ń pè náà dá wáhàlá sílẹ̀ ni.
Tí èsì ìdìbò tó ń bọ̀ yìí bá tún súnmọ́ ara wọn, ipa ìbò àwọn ará ilẹ̀ òkèrè yóò tún fojú hàn si.












