Ṣe lóòtọ́ làwọn agbébọn gba ibùdó ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà tó wà ní ìpínlẹ̀ Niger?

Aworan awọn ologun pẹlu ibọn ti wọn gbe dani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Laipẹ yii ni iroyin kan gbode, pe awọn agbebọn yabo ibudo ẹkọṣẹ awọn ologun to wa ni ipinlẹ Niger, ati pe wọn ti gba ibẹ mọ awọn ologun lọwọ.

Koda, iroyin kan sọ pe ijọba ipinlẹ naa fidi ọrọ yii mulẹ.

Aṣiri nipa ibudo ti a mọ si Nagwamatse, lagbegbe Kontagora naa tu nigba ti

Aṣofin to n ṣoju ijọba ibilẹ Kontagora keji,Abdullahi Isa, rọ ile igbimọ pe ki wọn kede ilu o fararọ lagbegbe ti oun n ṣoju.

Ipinlẹ Niger jẹ ọkan ninu awọn agbegbe ti Boko Haram n da laamu l’Oke-ọya.

Bẹẹ naa si ni awọn ajinigbe ati awọn agbesunmọmi ti sọ awọn ibi kan di tiwọn nipinlẹ naa.

Lọsẹ to kọja yii, ti ina ko si lapa Ariwa Naijiria, awọn agbebọn ni ijọba di ẹbi ọrọ naa ru.

Wọn ni awọn ni wọn ba awọn opo agbara to wa ni Shiroro, nipinlẹ Niger jẹ ti ina ko fi tan, ti wọn si ju gbogbo ilu si okunkun fun ọjọ mẹwaa gbako.(lasiko ti a n kọ iroyin yii.)

Ohun tí BBC rí gbọ́

Ohun ti BBC gbọ ni pe awọn agbebọn ti gba ibudo ẹkọṣẹ awọn ologun naa, gẹgẹ bi wọn ṣe sọ fun wa.

Aṣoju ijọba ibilẹ Tapa, to tun jẹ Igbakeji alaga igbimọ to n gbe iroyin jade nile igbimọ ijọba ibilẹ Niger, Sani Idris, sọ fun BBC pe awọn sọrọ lori iṣẹlẹ naa.

"Ile igbimọ ti sọrọ lori ẹ, a ni a fẹẹ ba ijọba sọrọ, ki wọn le sọ fawọn ologun pe ki wọn fi kun agbara wọn, ki wọn le le awọn agbebọn kuro ninu igbo Kontagora."

Sani Idris lo sọ bẹẹ.

Bakan naa ni ẹnikan to ni ka ma darukọ oun, sọ fun BBC pe ileeṣẹ ologun ti beere afikun ṣọja lati awọn agbegbe to wa nitosi, ki wọn le ri ibudo naa gba pada.

"Ibudo yii tobi gan-an, igbo nla lo si yi i ka, eyi lo jẹ ko ṣee fun awọn ṣọja lati pagọ sibẹ.

‘’Eyi naa lo jẹ kijọba ni kawọn eeyan maa dako nibẹ, ko le baa din bawọn agbebọn ṣe n wọbẹ ku.

‘’Ijọba ibilẹ Mariga jẹ ọkan lara awọn ibi ti awọn agbebọn pọ si ju, nitori igbo to yi i ka. Awọn igbo yii jẹ aala Zamfara ati Kebbi."

’’Àwọn darandaran ló ń rìn kiri inú igbó náà, kì í ṣe aráàlú’’

Gẹgẹ bi ileeṣẹ ologun Naijiria ṣe wi, wọn ni awọn ti wọn n da ẹran jẹ lo n rin kiri lagbegbe naa, awọn agbebọn kọ.

Ileeṣẹ ologun tako iroyin to gbode, ninu atẹjade kan ti Ọgagun Onyema Nwachukwu, fi sita l’Ọjọruu ọsẹ yii.

Atẹjade naa ka pe, "Iroyin to sọ pe wọn ti gba ibudo wa, pe wọn ti le awọn eeyan abule mẹtaleogun kuro labule wọn ki i ṣe irọ nikan, o tun lewu pẹlu.

‘’O lewu nitori wọn n gbe e kiri lati ko ipaya ba awọn eeyan Kontagora ati Mariga ni.

" Iwadii ti a fi ẹsọ pẹlẹ ṣe, fidi ẹ mulẹ pe awọn eeyan ti wọn ri lagbegbe naa jẹ darandaran to n wa ohun ti awọn ẹran wọn yoo jẹ.

‘’Wọn ko ni ero aburu lọkan rara, a ko si ri aburu kan nipa wọn".

Bẹẹ ni atẹjade awọn ologun naa ṣalaye.