Èyí ni bí ètò ìsìnkú Charles Olumo ‘Agbako’ ṣe lọ sí ní ìlú Atan Ota

Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe Alagba Abdulsalam Sanyaolu ti ọpọ awọn eeyan mọ si Charles Olumọ Agbako ti jade laye.
Ile Charles Olumọ Agbako to wa lagbegbe Onibuku, Atan Ọta, ipinlẹ Ogun lo dakẹ si loni, Ọjọbọ.

Agba oṣerebinrin nni, Arabinrin Idowu Phillips ti ọpọ mọ si Mama Rainbow, to fi mọ awọn ololufẹ Agbako ni wọn wa nile rẹ lati kẹdun iku agba oṣere ọhun.
Gbogbo eto lo ti n lọ lati sin oku Agbako to jade laye lẹni ọdun mọkanlelọgọrun-un.

Gbajúgbajà òṣèré tíátà nnì, Abdulsalam Ishola ẹni tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Charles Olúmọ Àgbákò lagbo tiata, ti jáde l'áyé.
Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣèré ní Nàìjíríà, Bolaji Amusan tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Mr Latin ló kéde ikú rẹ̀ nínú àtẹ̀jáde kan lórí Instagram rẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́, òwúrọ̀ ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Kẹwàá, ọdún 2024 ni Charles Olumo jáde láyé lẹ́yìn tó ní òun fẹ́ rẹjú.
Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Agbako, Motunrayo Iwa tó fìdí ikú bàbá rẹ̀ múlẹ̀ ní ago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ òní ni ètò ìsìnkú máa wáyé.
Ní ọdún 2022 ni Charles Olumo Agbako bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ tó sì sọ̀rọ̀ nípa àìsàn tó ń ba fínra nígbà náà.
Taa ni Charles Olumo Agbako?
Abdulsalam Ishola ni orúkọ tí ìyá àti bàbá rẹ̀ sọ ọ́ àmọ́ Charles Olumo Agbako mọ̀ ọ́ sí.
Agbako sọ fún BBC News Yorùbá lọ́dún 2022 pé bí iṣẹ́ tíátà ṣe rí tó jẹ́ pé èèyàn gbọ́dọ̀ ní orúkọ kan ni òun fi ń jẹ́ Agbako àti pé òun ni òun fún ara òun lórúkọ náà.
Ó ní nítorí pé Agbako jẹ́ nǹkan ìbẹ̀rù ni òun fi mú orúkọ náà.
Ní ọdún 1923 ni wọ́n bí Charles Olumo Agbako sáyé tó sì ppapodà lọ́dún 2024 lẹ́ni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rùn-ún.
Ó ní bí wọ́n ṣe máa ń jó nínú eré láyé ìgbà àwọn Ogunnde ló mú òun náà lo darapọ̀ mọ́ eré tíátà ní nǹkan bíi ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn.
Agbako ní ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni òun kò lè gbàgbé láyé òun pàápàá ọjọ́ tí ọmọ òun jáde láyé lásìkò tí òun ń ṣeré lọ́wọ́, tí òun kò sì lè kúrò níbẹ̀.
Àmọ́ ó ní ọjọ́ tí ìyá òun kú ni òun kò lè gbàgbé láyé.
Agbako gbajúmọ̀ fún ipa líle tó máa ń kó nínú eré àtàwọn èdè òyìnbó ńláńlá tó máa ń sọ nínú àwọn fíìmù.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù ni Agbako ti ṣe tó sì ti gba àmì ẹ̀yẹ lọ́kan-ò-jọ̀kan.














