Dókítà Ganiyat Popoola gba ìtúsílẹ̀ lẹ́yìn oṣù mẹ́wàá ní àhámọ́ ajínigbé

Ganiyat Poopola

Oríṣun àwòrán, NARD

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Dókítà tí àwọn ajínigbé jí gbé ní nǹkan bíi oṣù mẹ́wàá sẹ́yìn, Dókítà Ganiyat Popoola ti gba ìtúsílẹ̀ kúrò ní àhámọ́ àwọn ajínigbé.

Ilé ìtọ́jú ojú National Eye Centre tó wà ní ìpínlẹ̀ Kaduna ni Ganiyat Popoola ti ń ṣiṣẹ́ kó tó kó sí ọwa àwọn ajínigbé.

Ní ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá, ọdún 2023 ni Ganiyat Popoola àti ọkọ̀ rẹ̀, Nurudeen Popoola pẹ̀lú ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kan, Folaranmi Abdul-Mugniy kó sí àkàtà àwọn ajínigbé náà.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdúnáàdúrà, àwọn ajínigbé náà tú ọkọ Ganiyat sílẹ̀ lọ́jọ́ Kẹjọ, oṣù Kẹta ọdún 2024 lẹ́yìn tí wọ́n gba owó ìtúsílẹ̀ àmọ́ tí wọ́n fi Ganiyat àti àbúrò sí àhámọ́ láti ìgbà náà.

Èyí fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye láàárín àwọn dókítà Nàìjíríà tí wọ́n sì ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn láti rọ ìjọba àpapọ̀ lórí bí dókìtà náà yóò ṣe ìtúsílẹ̀ kúrò ní àkàtà àwọn ajínigbé.

Nínú oṣù Kẹjọ, àwọn dókítà ní lọ fún ìyanṣẹ́lódì ọ̀sẹ̀ kan láti jẹ́ kí ìjọba àpapọ̀ le tètè wá ìtúsílẹ̀ Ganiyat Popoola àti àbúrò rẹ̀.

Èyí mú kí mínísítà fétò ìlera, Ọ̀jọ̀gbọ́n Muhammad Pate kọ̀wé sí olùbádámọ̀ràn ààrẹ lórí ètò ààbò, Nuhu Ribadu àti ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Kayode Egbetokun láti dá sí ọ̀rọ̀ dókítà náà, kí wọ́n sì wá bí ó ṣe máa gba ìtúsílẹ̀ kúrò ní àhámọ́ àwọn ajínigbé náà.

Lẹ́yìn-o-rẹ̀yìn dókítà Ganiyat Popoola ti gba ìtúsílẹ̀ kúrò ní àháma àwọn ajínigbé náà ní ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù Kẹwàá, ọdún 2024.

Gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ìròyìn Daily Trust ṣe sọ, ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn dókítà ní Nàìjíríà, Tope Osundara fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé dókítà Popoola àti àbúrò rẹ̀ ti kúrò ní àkàtà àwọn ajínigbé náà.

Ìròyìn náà fi kun pé Osundara ní ọjọ́rú ni ó gba ìtúsílẹ̀ náà àti pé àwọn kò fẹ́ kó tíì máa yọjú sí ẹnikẹ́ni nítorí àwọn nǹkan tó là kọjá ní àkàtà àwọn ajínigbé.

Bákan náà ló fi kun pé àwọn kò san owó ìtúsílẹ̀ kankan láti fi gba Ganiyat àti àbúrò kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé náà.

Ẹ̀wẹ̀, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kaduna kò ì tíì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé dókítà náà ti gba ìtúsílẹ̀.