Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Olufemi Oluyede, adelé Ọ̀gá Iléèṣẹ́ ológun tí Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn

Olufemi Oluyede

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti kede iyansipo adele ọga agba ileeṣẹ ologun Naijiria.

Ọjọru ni aarẹ kede Major General Olufemi Olatubosun Oluyede, gẹgẹ bi ẹni ti yoo dele, lati gba ipo lọwọ Lt-Gen Taoreed Lagbaja.

Lati igba diẹ sẹyin ni Ọgagun Lagbaja ko ti yọju si gbangba.

Gẹgẹ bi ikede ti oludamọran fun aarẹ, Bayo Onanuga, fi sita, ọga ologun tuntun naa yoo jẹ adele titi di igba ti Lagbaja yoo pada si ẹnu iṣẹ.

Iyansipo yii waye lẹyin ọjọ diẹ ti iroyin jade sori ayelujara nipa ibi pato ti Lt-Gen Lagbaja, wa.

Sugbọn nigba naa, olu ileeṣẹ ologun sọ pe ayederu ni iroyin to n lọ kiri pe aisan jẹjẹrẹ ti pa Lagbaja.

Ninu atẹjade kan ti adele oludari ẹka iroyin nileeṣẹ ologun, Brig-Gen Tukur Gusau fi sita niluu Abuja lọsẹ diẹ sẹyin, o ni alaafia ni Ọgagun Lagbaja wa, yoo si pada sẹnu iṣẹ laipẹ.

Taa ni Olufemi Oluyede ti Tinubu yan?

Ẹni ọdun mẹrindinlọgọta ni Major General Olufemi Oluyede.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O ti fi igba kan jẹ olori ikọ ologun

Elite Infantry Corps ti ileeṣẹ ologun to wa ni Jaji, Kaduna.

Oluyede gba igbega sipo 2nd lieutenant lọdun 1992.

O de ipo Major-General ninu oṣu Kẹsan-an, ọdun 2020.

O ti ṣiṣẹ gẹgẹ Platoon Commander ati adjutant ni ikọ ologun 65 Battalion, company commander ni 177 Guards Battalion, Staff Officer Guards Brigade, Commandant ni ile-ẹkọ Amphibious Training School.

Adele ọga agba ologun ti kopa ninu awọn ogun jija bi Economic Community of West African States Monitoring Group (ECOMOG) Mission ni Liberia, Operation HARMONY IV ni Bakassi, ati Operation HADIN KAI ni ila-oorun Ariwa Naijiria gẹgẹ bi Balogun command 27 Task Force Brigade.

Oriṣiriṣi ami ẹyẹ ni Oluyede ti gba, fun iṣẹ takuntakun to n ṣe gẹgẹ bi ologun.

Lara awọn ami ẹyẹ naa ni Corps Medal of Honour, Grand Service Star, Passing Staff Course, Field Command Medal, Field Command Medal of Honour, ati Field Training Medal.

Ṣaaju iyansipo yii, Oluyede ti gba ami ẹyẹ Chief of Army Staff Commendation Award.