Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
O ṣe ilẹ̀ ń jẹẹyan
Agba oṣere tiata, Abdulsalam Ishola ti ọpọ mọ si Charles Olumo Agbako ti jade laye
Owurọ Ọjọbọ ni Agbako dagbere faye lẹni ọdun mọkanlelọgọrun-un
Ẹkunrẹrẹ iroyin, pẹlu bi isinku rẹ yoo ṣe lọ wa ni bbc.com/yoruba
Ǹjẹ́ o ti gbọ́?
Pe kini?
Pe o le jokoo ni kọrọ yara rẹ ki ajọ to n ri iwọle-wọdeni Naijiria si mu iwe irinna rẹ wa ba ọ
Ni Naijiria yii naa abi nilẹ okeere?
Naijiria yii naa ni o, Immigration ti kede ilana mẹjo ti ẹni to ba fa gba iwe irinna yoo gbe lai ni de ọfiisi wọn
O o si jami si
Kan si oju opo bbc.com/yoruba fawọn igbesẹ naa
Ṣo o ranti Ganiyat Popoola, dokita tawọn agbẹbọn jigbe lati oṣu Kejila ọdun to kọja
Ṣeyi tawọn ẹgbẹ dokita tori rẹ yanṣẹlodi fọsẹ kan ninu oṣu kẹjọ
Ehn o, o ti gba itusilẹ lẹyin to lo oṣu mẹwaa ni ahamọ awọn ajinigbe naa
Ṣe wọn san owo itusilẹ ni?
Kan si oju opo bbc news Yoruba ti o ba fẹ mọ ẹkunrẹrẹ














