Èlóò gan-an ni owó oṣù ààrẹ America?

Joe Biden ati owo Dọla

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gẹgẹ bi eeyan ti ko si ninu iṣejọba, o ṣe e ṣe ki o maa ro pe owo gọbọi, bi ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ni aarẹ America n gba gẹgẹ bi owo oṣu.

Ko si irọ nibẹ, nitori pe aarẹ orilẹ-ede America jẹ olori orilẹ-ede ọkan lara awọn orilẹ-ede to lami-laaka, ati ọkan lara awọn eeyan to l’agbara julọ ni agbaye.

Ṣugbọn ṣe ka ma parọ tan yin, ọrọ ko ri bẹẹ rara.

Idi ni pe oṣiṣẹ ilu ni ẹnikẹni to ba jẹ aarẹ America, owo ori ti awọn araalu n san si ni wọn fi n san owo oṣu fun wọn.

Aarẹ to wa nibẹ lọwọlọwọ, Joe Biden, n gba $400,000 lọdun.

O si ṣe e ṣe ko jẹ pe iye ti aarẹ to n bọ, yala Donald Trump tabi Kamala Harris, naa yoo gba.

Eyi ko ṣẹyin bo ṣe jẹ pe owo oṣu aarẹ ko yipada lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin.

Fun Kamala Harris, a jẹ pe owo rẹ yoo ni afikun lati $235,100 to n gba gẹgẹ bi igbakeji aarẹ lọwọlọwọ, to ba fi bori ninu eto idibo to n lọ lọwọ.

Fun ọdun mẹrin to lo ni iṣakoso, Donald Trump ko gba owo oṣu naa, dipo bẹẹ, o dari rẹ si oriṣiriṣi ileeṣẹ ijọba ni oṣu mẹta-mẹta.

Gẹgẹ bi akọwe agba fun ijọba America ṣe sọ, lọdun 2029, o dari owo naa si ileeṣẹ to n mojuto eto ilera lati sẹ atilẹyin fun akitiyan wọn lori itankalẹ Coronavirus.

Trump ni ẹni to lowo julọ ninu gbogbo awọn to ti jẹ aarẹ America ri.

Atupalẹ owo oṣu ati ajẹmọnu fun aarẹ America

  • Apapọ owo oṣu lọdọọdun - $400,000
  • Awọn ajẹmọnu miran, to fi mọ owo aṣọ - $50,000
  • Owo igbalejo - $19,000
  • Owo lati sẹ atunṣe ile ijọba ‘White House’ nigba to ba ṣẹṣẹ ko de ibẹ - $100,000. Owo naa lo tun w afun itọju awọn oṣiṣẹ bii alase, ọmọ ọdọ ati awọn to n tun ọgba ṣe
  • Bakan naa ni aarẹ ni anfaani si eto ilera ọfẹ, irinna ọfẹ ninu ọkọ ijọba, ọkọ ofurufu ileeṣẹ ologun ori omi ati ti oju ofurufu
  • O tun n gba $100,000 owo irinna lọdọọdun, lai san owo ori lori rẹ

Awọn igba ti atunṣe ti ba owo oṣu aarẹ America

Lati ọdun 1789, lasiko ti George Washington ti jẹ aarẹ akọkọ, igba maarun-un pere ni atunṣe ba owo oṣu aarẹ ni United States.

Ṣaaju, $25,000 ni aarẹ kọkọ n gba. Amọ lode oni, ti a ba fẹ ẹ ṣe odinwo bi nnkan ṣe ri, owo naa yoo wọ $895,700, gẹgẹ bi igbelewọn ti ẹrọ iṣiro bi nnkan ṣe ti wọn si i ṣe.

Idi ti wọn fi n san owo oṣu fun awọn aarẹ ni lati dena ki wọn o maa ki ọwọ bọ owo ilu.

Ọdun 2001 ni atunṣe ti ba owo oṣu aarẹ America kẹyin, nigba ti awọn ọmọ ile aṣofin sọ ọ di ilọpo meji lati $200,000 si $400,000.

  • 1789: $25,000
  • 1873: $50,000
  • 1909: $75,000
  • 1949: $100,000
  • 1969: $200,000
  • 2001: $400,000

Ti eeyan ba wo ti owo oṣu nikan, iye ti aarẹ n gba ni America ko to ti oṣiṣẹ to n gba owo julọ ni America.

$788,000 ni oṣiṣẹ to wa ni ipele akọkọ, eyi to jẹ ida kan pere, n gba.

Amọ o, aarẹ to ba jẹ ni America yoo ṣi maa gba to $244,000 lọdọọdun, lẹyin to ba fi ipo silẹ.

Bakan naa ni yoo ni eto aabo, iwosan ọfẹ ati owo irinna.