Ibí yìí ní iṣẹ́ dé lórí ìdásílẹ̀ iléeṣẹ́ amúnáwá tí yóò máa pèsè ìná fún ìpínlẹ̀ Ekiti

Ileeṣẹ amunawa

Oríṣun àwòrán, Biodun Oyebanji/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina Biodun Oyebanji ipinlẹ Ekiti ti ṣalaye ibi ti iṣẹ de duro lori idasilẹ ileeṣẹ amunawa ti yoo maa pese ina mọnamọna ni ipinlẹ naa.

Eleyii yatọ si ina ọba ti ijọba apapọ n ṣe agbatẹru rẹ eyi to n dẹnukọlẹ loore koore.

Gomina Oyebanji fi ọrọ yii lede loju opo X rẹ l’Ọjọbọ, ọjọ keje oṣu Kọkanla ọdun 2024.

Gomina ipinlẹ Ekiti ni ijọba oun ti fun awọn olokowo mẹrinla ni ẹka ina mọnamọna ni iwe ẹri lati le ṣiṣẹ ni ipinlẹ naa.

Ninu ọrọ rẹ, gomina ni ijọba ipinlẹ Ekiti ti fun ileeṣẹ apinaka mẹta ati ileeṣẹ to n pese ina mẹrin ni iwe ẹri lati maa ṣiṣẹ ni ipinlẹ naa.

Bakan naa ni gomina tun sọ pe ijọba ti fun ileeṣẹ kereje meji to n pese ina ati ileeṣẹ marun un mii to n pese mita ina ọba ni iwe ẹri lati le maa ṣiṣẹ nipinlẹ Ekiti.

Gẹgẹ bi gomina ti ṣalaye, igbesẹ yii yoo jẹ ki ipese ina mọnamọna pọ si, ati pe yoo tun jẹ ki awọn araalu le maa ri ina lo daadaa.

Gomina ipinlẹ Ekiti ni igbesẹ yii yoo tun jẹ kawọn araalu ti ko ni mita nile wọn ri mita gba.

Lọwọ yii, iwọn ina 20-25 MW lo n kan ipinlẹ Ekiti ninu ina ti ijọba apapọ n pin fawọn ipinlẹ ni Naijiria.

Eleyii si kere pupọ tori ipinlẹ Ekiti nilo iwọn ina mọnamọna 120 MW.

Ijọba ni iwọn ina 130 MW ni afojusun ipinlẹ Ekiti ki ina le sun ipinlẹ naa bọ laipẹ.

Igbesẹ yii wa ni ibamu pẹlu ofin ti ijọba gbe kalẹ lọdun 2023, eyi to fawọn ipinlẹ lagbara lati ni ileeṣẹ to n pese ati eyi to n pin ina ka ti wọn.

Gomina Oyebanji ki gbogbo eeyan to gbaruku ti ijọba rẹ lori ati pese ileeṣẹ ina mọnamọmọna adani nipinlẹ Ekiti.

O ni igbesẹ yii jẹ ọpakuntẹlẹ fun idagbasoke ọrọ aje, ipese iṣẹ fawọn ọdọ ati igbayegbadun gbogbo eeyan ipinlẹ Ekiti.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post