Kí ló ń ṣokùnfà bí iná mọ̀nàmọ́ná ní Nàìjíríà ṣe ń dẹnukọlẹ̀ léra léra?

Aworan opo ina

Oríṣun àwòrán, TCN

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọ eeyan lo tun ti wa ninu okunkun birimu birimu bayii lẹyin ti ina mọnamọna Naijiria tun dẹnukọlẹ ni Ọjọbọ, ọjọ keje oṣu Kọkanla ọdun 2024 yii.

Ina mọnamọna ọhun lo lulẹ ni nnkan bii ago mọkanla kọja iṣẹju mejidinlọgbọn lonii l'Ọjọbọ.

Igba keji ree ti eyi yoo ṣẹlẹ lọsẹ yii lẹyin ti ina ọhun ti kọkọ dẹnukọlẹ lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii.

Ayẹwo ti BBC ṣe lori itakun agbọrọkaye ileeṣẹ ina mọnamọna fihan pe ko si ina ni gbogbo ileeṣẹ to maa n gbe ina ọba kaakiri orilẹede Naijiria.

To fi di akoko yii, ileeṣẹ TCN to n ṣe agbatẹru pinpin ina ọba ko tii sọ ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ yii.

Ki lo n ṣokunfa bi ina mọnamọna ni Naijiria ṣe n dẹnukọlẹ lera lera?

Aworan oṣiṣẹ ina mọnamọna

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọpọ awọn akọṣẹmọṣẹ nipa ina amuṣagbara lo ti sọ wi pe awọn ẹrọ ati irinṣẹ amunawa ti Naijiria n lo ni ọjọ ti lọ lori wọn.

Bakan naa ni wọn sọ pe awọn ẹrọ yii ko lagbara pupọ lati maa gbe ẹru to wa lori wọn mọ.

Awọn akọmọṣẹmọṣẹ naa tun sọ pe ai maa ṣe itọju awọn ẹrọ yii daadaa wa lara ohun to n jẹ ki ina mọnamọna maa dẹnukọlẹ ni gbogbo igba ni Naijiria.

Heather Onoah to n ṣiṣẹ pẹlu igbimọ GENCOS to n ri si pinpin ina mọnamọna sọ pe ai si irinṣẹ agbenaka to wa lara nnkan to n jẹ ki ina maa dẹnukọlẹ.

‘’A o ni irinṣẹ to to lati maa fi pin ina kaakiri ibi gbogbo tawọn araalu yoo ti maa lo ina.

Nigba mii ina yii gan an maa n pada si ileeṣẹ amunawa nitori ai si irinṣẹ agbenaka to to,’’ Onoah lo sọ bẹẹ.

Ọna abayọ si ina mọnamọna to n dẹnukọlẹ ni gbogbo igba

Awọn akọṣẹmọṣẹ ti sọ pe ti Naijiria ba fẹ fopin si ina mọnamọna to n foni ku fọla dide, orilẹede Naijiria gbọdọ ṣe isọdọtun ati atunṣe awọn irinṣẹ ẹrọ amunawa.

Wọn tun sọ pe Naijiria gbọdọ bẹrẹ si ni lo awọn ọna miran to jẹ ọna igbalode lati maa pese ina ọba bi lilo oorun lati pese ina ọba atawọn ọna igbalode mii.

Akọṣẹmọṣẹ kan nipa ọrọ ina mọnamọna, John Adebayo, sọ fun BBC Pidgin pe o ṣe pataki ki ijọba ṣe agbeyẹwo oriṣiiriṣii ọna lati ṣe atunṣe ina mọnamọna to n ku pipi bi ina fitila ni Naijiria.

Ọgbẹni Adebayo ni lara ọna abayọ si iṣoro ina ọba ni Naijiria ṣiṣe atunṣe gbogbo irinṣẹ amunawa ti ko ṣiṣẹ daadaa mọ ki ina le maa de ọdọ awọn araalu fun lilo.

Victoria Ibrahim toun naa jẹ akọṣẹmọṣẹ nipa ọrọ ina ọba sọ pe iṣoro ina mọnamọna yoo dinku gan an ti ijọba ba le maa lo oorun fun ipese ina.

O fikun ọrọ rẹ pe lilo idọti fun ipese ina ọba naa le sẹ iranwọ nipa wiwa ojutuu si iṣoro ina mọnamọna to daku daji.