Makinde buwọ́lu N80,000 gẹ́gẹ́ bíi owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ l’Oyo, àmọ́, nígbà wo ni sísan owó ọ̀hún yóò bẹ̀rẹ̀?

Oríṣun àwòrán, SeyiMakinde/X
Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti buwọlu N80,000 gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ nipinlẹ naa.
Kọmiṣọna eto iroyin, Ọmọba Dotun Oyelade lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita.
Kọmiṣọna eto iroyin ṣalaye ninu atẹjade naa wi pe gomina ipinlẹ Oyo fi ontẹ lu owo oṣu tuntun naa lẹyin ti igbimọ kan ti ijọba gbe dide lori ọrọ owo naa jabọ iṣẹ ti wọn ṣe fun ijọba.
Ọmọba Oyelade ni awọn oṣiṣẹ yoo bẹrẹ si ni gbowo oṣu tuntun naa lẹyin ti igbimọ to n ri si ọrọ owo oṣu naa ba ti pari iṣẹ atunṣe ti wọn n ṣe lori owo oṣu tuntun naa tan.
Awọn abẹnugan ninu ẹgbẹ oṣiṣẹ atawọn aṣoju ijọba lo wa ninu igbimọ ọhun.
Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC lu Makinde lọgọ ẹnu lori owo oṣu tuntun
Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC, ẹka ti ipinlẹ Oyo ti gboṣuba rabandẹ fun Makinde lẹyin ti o buwọlu N80,000 gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ nipinlẹ naa.
Alaga ẹgbẹ NLC, ẹka ti ipinlẹ Oyo, Kọmureedi Kayode Martins, sọ pe igbesẹ gomina ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi ẹni to nifẹẹ awọn oṣiṣẹ.
Kọmureedi ni Makinde tun ti fihan wi pe gomina to n maa n gbọ ohun ti araalu n sọ ni i ṣe.
Alaga ẹgbẹ NLC ni igbesẹ Makinde yii tun fihan pe ajiṣe bi Oyo ni gomina i ṣe ti o si tun jẹ aṣaaju rere.
O wa fi da gomina loju wi pe awọn oṣiṣẹ naa yoo jara mọ iṣẹ wọn sii lẹyin ti ijọba ti ṣe koriya fun wọn pẹlu alekun owo oṣu wọn.
Kọmureedi Martins ko ṣai rọ awọn ọmọ ẹgbẹ igbimọ to n ṣatunṣe lori owo oṣu tuntun naa pe ki wọn ṣiṣẹ naa daadaa ki gbogbo oṣiṣẹ lati ọga de ori ọmọṣẹ le jẹ anfaani owo oṣu tuntun naa.
Bakan naa ni o tun dupẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ naa fun suuru ati ifarada wọn lati igba ti ijiroro ti bẹrẹ lori owo oṣu tuntun.
Alaga NLC tun rọ awọn oṣiṣẹ wi pe ki wọn ma ja ijọba kulẹ lẹnu iṣẹ wọn, lẹyin ti gomina ti buwọlu alekun owo oṣu wọn.















