'Kekeré ni mo wà tí ẹsẹ̀ mi kán nílùú Share ni Kwara àmọ́ mo padà fi ìtàn rere lélẹ̀ fún Africa'
Ilu Sare, nipinlẹ Kwara, ni wọn ti bi Bolaji Eniola Mariam.
Bolaji ni ẹni akọkọ to gba ami ẹyẹ ninu idije Badminton fun awọn to ni ipenija ara nilẹ Africa.
Lọwọlọwọ, Bolaji ma n tiro ẹsẹ rin ni.
Gẹgẹ bo sẹ sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC, o ni kii ṣe bi wọn ṣe bi oun niyẹn.
"Nigba ti mo wa ni kekere ni mo jabọ lati ori ile alaja, to si jẹ ki ẹsẹ mi o kan."
Gẹgẹ bo ṣe sọ, iya-agba rẹ lo ta gbogbo ọja to n ta ninu ṣọọbu rẹ lati fi gba iwosan fun ẹsẹ naa debi to de duro lonii.
Lọdun 2023, o kopa nibi ipagọ idanilẹkọọ kan ti ajọ Badminton ni Africa ṣe lorilẹ-ede Egypt, nibẹ lo si ti pade akọnimọọgba lati orilẹ-ede spain, eyi to fi ifẹ ọkan rẹ han lati di olukọni fun un, to ba wu u.
Ipade naa lo sọ Eniola di ẹni to n gbe ni orilẹ-ede Spain, to si ti gba ibẹ kopa ninu awọn idije ni Dubai, Egypt, ati Paris.
O ni o jẹ nnkan ayọ fun oun lati jẹ ẹni akọkọ to gba ami ẹyẹ wura laarin awọn akanda ẹda nilẹ Africa.

Oríṣun àwòrán, Eniola Bolaji
Ṣaaju Eniola, ko si ẹni kankan ni Africa to ti i gba ami ẹyẹ ri nidii ere idaraya Badminton.
O ni nnkan ti inu oun dun julọ su ninu anfaani to ni, ni bi oun ṣe ri owo lati gbe ṣọọbu iya-iya oun to fi owo rẹ tun ẹsẹ oun ṣe dide pada.



