Kínni àwọn ọmọ ilẹ̀ Africa ń fẹ́ nínú ètò ìdìbò ààrẹ America?

Annette Njau

Oríṣun àwòrán, Annette Njau

    • Author, Chimezie Ucheagbo
    • Role, BBC News
    • Reporting from, Lagos
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Annette Njau to jẹ amofin lati orilẹede Sierra-Leone l'Amẹrika sọ pe ohun ti ọpọ alawọdudu to n gbe lorilẹede Amerika n fẹ ni pe ki wọn lanfaani lati maa ṣe okowo wọn, ki wọn si dibo bakan naa.

Njau jẹ ọkan lara awọn ẹgbẹrun lọna ọdunrun un ọmọ ilẹ Afirika to n gbe ni Texas lorilẹede Amerika.

Wọn si ti sa ipa wọn lati ri wi pe gbogbvo awọn ọmọ ilẹ Afirika to ti to ibo di ni yoo dibo lọjọ Iṣẹgun ọjọ karun un oṣu Kọkanla yii.

Nneka Achapu, ọmọbibi orilẹede Naijiria to n gbe orilẹede Amerika sọ pe ‘’oriṣiiriṣii iyapa ati inunibini lo wa l’Amẹrika lori ọrọ ẹlẹyamẹya ati wiwa si orilẹede Amẹrika lati ilẹ okeere.

Eleyii si n ni ipa to lagbara gidi gan an lori awujọ wa lorilẹede Amẹrika.’’

Texas jẹ ibikan ti ẹgbẹ oṣelu Republican ti maa n rọlẹ gan an tẹlẹ lati aye igba ti idile Bush ti jẹ aarẹ Amẹrika.

Amọ, ibo diẹ naa ni Donald Trump ri ju Joe Biden lọ to fi wọle nibẹ lọdun 2020.

Nkan tun ti yatọ sii ni Texas bayii tori ibẹ ni ọpọ eeyan lati ilẹ Afirika n gbe lorilẹede Amẹrika.

Udeme Anthony sọ pe gẹgẹ bi ọdọ, ohun to wa lọkan oun toun ro n ro ni bi oun ṣe maa gbe igbe aye to ni itumọ ti oun yoo si lanfaani lati fowo pamọ fun ọjọ iwaju oun.

Awọn ọmọ ilẹ Africa pọ ni Texas lorilẹede Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọ ilẹ Africa pọ ni Texas lorilẹede Amẹrika

Igbe aye ilẹ Afirika ni Texas

Orilẹede Naijiria kekere ni wọn maa n pe ilu Texas l'Amẹrika pẹlu bawọn ọmọ Naijiria ṣe pọ nibẹ.

Bii 60,000 ọmọ Naijiria lo n gbe niluu Texas, koda, bi wọn ṣe maa n ṣe loju popo nigba mii dabi wi pe ilu Eko ni wọn wa.

O wọpọ ki eeyan ri kawọn olugbe ilu Texas wọ aṣọ orilẹede Naijiria nibẹ.

Koda, o tun wọpọ ki eeyan maa gbọ orin Naijiria nile itaja tabi nile ounjẹ.

Ivy Okoro

Oríṣun àwòrán, Ivy Okoro

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn ọmọ ilẹ Afirika ti ṣiṣẹ takun takun lẹka ọrọ aje ipinlẹ Texas.

Ọpọ ọmọ ilẹ Afirika lo n ṣiṣẹ adani, awọn mi-in n ṣiṣẹ lẹka eto ilera nigba tawọn miran n ṣiṣẹ nile epo rọbi.

Ivy Okoro ọmọ Naijiria to n gbe ni Amẹrika sọ pe ẹsin tun jẹ nnkan kan pataki to n ṣapejuwe ọmọ Naijiria lajo yala ẹlẹsin musulumi ni ọ ni tabi kristẹni.

Lawọn ṣọọṣi, gbọngan nla ati ibi okowo ni eto iforukọsilẹ fun eto idibo ti waye ni Texas.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọ ilẹ Afirika n pọ si Texas, iwadii fihan pe bii ida 61% awọn alawọdudu lo n dibo nipinlẹ Texas.

Maazi Okoro to jẹ baba Ivy ṣalaye pe nigba toun de si Amẹrika lọdun 1977, ohun to jẹ oun atawọn tawọn jọ wa logun ni lati kawe awọn kawọn pada si Naijiria.

O ni eyi gan an ni ko jẹ ki ọpọlọpọ awọn ọmọ ilẹ Africa maa dasi ọrọ eto idibo Amẹrika nigba naa.

Ọgbẹni Okoro fikun ọrọ rẹ wi pe awọn ko tiẹ fẹ nkan to le de awọn mọlẹ ni Amẹrika nigba naa.

Amọ, lẹyin ọpọlọpọ ọdun bayii, awọn ọmọ ilẹ Afirika to kọkọ wa si Amẹrika ti di ọmọ ilẹ naa, wọn si ti ni ẹbi ati okowo nibẹ.

Maazi Okoro sọ pe awokọṣe awọn lawọn ọmọ tawọn n bi wo pẹlu bi awọn kii ṣe dasi ọrọ oṣelu orilẹede Amẹrika.

O ni awọn ni lati ṣe atunṣe lori ọrọ naa bayii ki awọn si bẹrẹ sii dasi ọrọ oṣelu Amẹrika tori ipa to n ni lori awọn ọmọ ilẹ Afirika.

 Nneka Achapu ni aisi ọmọ ilẹ Afirika ninu awọn to n ṣejọba ipinlẹ Texas ko ṣẹnu 're fawọn alawọdudu to n gbe nibẹ.

Oríṣun àwòrán, Nneka Achapu

Àkọlé àwòrán, Nneka Achapu ni aisi ọmọ ilẹ Afirika ninu awọn to n ṣejọba ipinlẹ Texas ko ṣẹnu 're fawọn alawọdudu to n gbe nibẹ.

'Ọrọ ibo yii pakasọ'

Ọrọ bawọn ọmọ ilẹ Afirika ṣe n wa si orilẹede Amẹrika lo wa lọkan ọpọ alawọdudu lori eto idibo aarẹ ọjọ Iṣẹgun to n bọ.

Ọpọ lo n kọminu lori ati ri iwe irinna gba rinrin ajo lọ si orilẹede Amẹrika.

Ọpọ lo tiẹ n ro pe pe ijọba n mọ ọn mọ ṣe ni pe ko nira fawọn eeyan lati Afirika lati maa ri Amerika wọ.

Nneka ni ohun tawọn ọmọ ilẹ Afrika n fẹ ni pe ki ẹnikẹni to ba wọle ibo aarẹ Amẹrika ṣe eto ti yoo maye dẹrun fawọn ọmọ ilẹ Afirika to n gbe ni Amẹrika.

O ni o maa wu oun ki ijọba ṣe eto ti yoo jẹ ko rọrun fawọn ẹbi lati le wa maa bawọn eeyan l'Amẹrika.

Bakan naa lo tun sọ pe o maa dara ti ijọba ba tun le ṣeto ti yoo pese iṣẹ fawọn alawọdudu l'Amẹrika.

Aworan Maazi Okoro

Oríṣun àwòrán, Maazi Okoro

Yatọ si ọrọ akanṣe eto, bi awọn oloṣelu ti n ṣapejuwe awọn eeyan to wa si Amẹrika lati ilẹ okeere gẹgẹ bi ọdaran n kọ ọpọ lominu.

Ọjọgbọn Christian Ulasi to jẹ olukọ ni fasiti kan nipinlẹ Texas sọ pe ohun to buru ni ki oludije ibo maa tabuku awọn eeyan kan ki o si maa parọ mọ wọn.

O ni nkan to buru jai ni ki oludije kan maa sọ pe awọn ẹya kan larun lara wi pe ọdaran ni wọn.

Ọjọgbọn Ulasi o yẹ kawọn eeyan fiya jẹ iru oludije bẹẹ lasiko idibo to n bọ.

Njau to wa lati Sierra Leone to jẹ amofin sọ pe ẹbi oun loun tẹle wa si Amẹrika.

O ni orilẹede Amẹrika si ni oun ti lọ ile ẹkọ ti oun fi di amofin.

Njau ni niṣe lo yẹ ki ọrọ ipolongo oṣelu da lori awujọ, o ni ko yẹ ko ni ohun kan ṣe pẹlu ẹlẹyamẹya.

Ọpọ awọn ọmọ ilẹ Afirika to n gbe ni Texas lo sọ pe ijọba ipinlẹ naa ko ri tawọn ro bo tilẹ jẹ pe awọn alawọdudu pọ ni ipinlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọpọ awọn ọmọ ilẹ Afirika to n gbe ni Texas lo sọ pe ijọba ipinlẹ naa ko ri tawọn ro bo tilẹ jẹ pe awọn alawọdudu pọ ni ipinlẹ naa.

Gbogbo agbaye n wo Amẹrika lori ibo aarẹ to n bọ

Eto orilẹede Amẹrika nipa ilẹ okeere wa lara nkan to n kọ awọn ọmọ ilẹ Afirika to wa l’Amẹrika lominu.

Akoṣilẹ fihan pe o din diẹ ni miliọnu meji abọ ọmọ ilẹ Afirika lo n gbe l’Amẹrika lọdun 2021.

Ọpọ awọn ọmọ ilẹ Afirika lo lanfaani lati maa lọ orilẹede abinibi wọn maa bọ si Amẹrika.

Maazi Okoro ni ohun toun fẹ ni ijọba ti yoo ni ibaṣepọ to dan mọran pẹlu awọn orilẹede Afrika

Udeme gẹgẹ bim ọdọ sọ pe bi ọrọ aje Amẹrika ba ṣe ri lo maa sọ bi oun yoo ṣe dibo.