Ta ni Kemi Badenoch, ọmọ Nàìjíríà tó di adarí ẹgbẹ́ òṣèlú Conservative ní UK?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kemi Badenoch, ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti fìtàn balẹ̀ bí ó ṣe di adarí ẹgbẹ́ òṣèlú Conservative Party ní orílẹ̀ èdè UK.
Badenoch ṣèlérí láti mú àyípadà ọ̀tun bá ẹgbẹ́ òṣèlú náà lẹ́yìn tí wọ́n dìbò yàn án tan.
Robert Jenrick ló ba du ipò náà tó sì jámọ́ Kemi Badenoch lọ́wọ́.
Badenoch ní ìbò 53,806 nígbà tí Jenrick rí ìbò 41,388. Èyí ni èsì ìbò tó súnmọ́ ara wọn jùlọ láti ọdún 1998 tí ẹgbẹ́ òṣèlú Conservative ti ń fi ìbò yàn àwọn adarí sípò.
Badenoch, ẹni ọdún mẹ́rìnlélógójì náà ni yóò jẹ́ adarí ẹgbẹ́ òṣèlú Conservative kẹfà láàárín ọdún mẹ́jọ.
Ẹgbẹ́ òṣèlú tó wà ní bèbè láti túká ló ń jogún lọ́wọ́ Rishi Sunak.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tó jáwé olúborí, Kemi Badenoch ní àsìkò láti ṣiṣẹ́ àti ṣíṣe àtúntò ẹgbẹ́ àwọn ló délẹ̀ báyìí.
Ó sọ pé ẹgbẹ́ àwọn gbọdọ̀ gbajúmọ̀ bí wọ́n yóò ṣe ri pé àwọn ará ìlú tó máa ń dìbò fẹ́gbẹ́ àwọn tẹ́lẹ̀ àmọ́ tí wọ́n fi àwọn sílẹ̀ padà ń dìbò fún wọn.

Oríṣun àwòrán, EPA
“Ẹgbẹ́ wa ṣe pàtàkì sí àṣeyọrí orílẹ̀ èdè wa.
“Àmọ́ tí a bá fẹ́ kí àwọn èèyàn gbọ́ ti wa, a nílò láti ṣe òótọ́.”
Badenoch, tó ti jẹ́ aṣòfin láti ọdún méje sẹ́yìn, sọ pé àwọn gbọ́dọ̀ gbà pé ẹgbẹ́ àwọn ṣe àṣìṣe láti nǹkan bíi ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yìn ní ìjọba.
Nǹkan tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fẹ́ mọ̀ báyìí ni àwọn tí Badenoch máa yàn láti jọ ṣètò ẹgbẹ́ náà lójúnà àti dá ògo ẹgbẹ́ òṣèlú wọn padà ṣáájú ètò ìdìbò gbogbogboò ní UK.
Ó kan sáárá sí Jenrick tó gba ipò Kejì, tó sì sọ ṣáájú pé gbogbo àwọn mẹ́fà tí àwọn jọ du ipò náà ni wọ́n máa ní ipò kan tàbí òmíràn tí wọ́n máa dìmú nínú ìṣèjọba òun.
BBC gbọ́ pé ní ọjọ́rú ni Badenoch yóò ṣàfihàn àwọn tí yóò bá ṣe ìjọba ṣáájú kí ètò ìbò àbá ìsúná tó wáyé àtàwọn ìbéèrè fún ipò Olóòtú ìjọba.
Jenrick tí kò bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n kéde èsì ìbò náà rọ àwọn èèyàn lórí ayélujára láti ṣe àtìlẹyìn fún Kemi láti gba agbára lọ́wọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour.
Bákan náà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó ṣe àtìlẹyìn fún un níbi ètò ìdìbò náà.
Bob Blackman tó ṣe àmójútó ètò ìdìbò Conservative, sọ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú náà ti dínkù sí 132,000. Èyí tó jẹ́ àdínkù àwọn èèyàn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì sí ti odun 2022.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn ni wọ́n ti kí Badenoch kú oríire tó fi mọ́ àwọn tó ti dípò náà mú ṣáájú rẹ̀.
Rishi Sunak nínú nǹkan tó kọ sójú òpó ayélujára rẹ̀ ní òun mọ̀ pé Kemi Badenoch yóò jẹ́ adarí tó dára fún ẹgbẹ́ òṣèlú àwọn.
Olóòtú ìjọba UK tẹ́lẹ̀ rí, Boris Johnson ní obìnrin tó gbójú gbóyà ni Badenoch àti pé yóò tẹ ẹgbẹ́ náà síwájú.
Àmọ́ alága ẹgbẹ́ òṣèlú Labour, Ellie Reeves ní ìpolongo ẹgbẹ́ Conservative ṣàfihàn pé wọn kò kọ́ ẹ̀kọ́ kankan lórí ìdí tí àwọn èèyàn kò ṣe dìbò fún wọn níbi ètò ìdìbò gbogbogboò tó wáyé nínú oṣù Keje.
Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Badenoch

Ní oṣù kìíní, ọdún 1980 ni wọ́n bí Kemi Badenoch ní ìlú Wimbledon, Britain.
Iṣẹ́ dókítà àti olùkọ́ ni àwọn òbí rẹ̀ ń ṣe ní UK.
Ó fìgbà kan gbé ní ìlú Èkó àti Amẹ́ríkà.
Nígbà tó pè ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ni àwọn ẹbí rẹ̀ tún padà sí Britain.
Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ Computer Engineering ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì University of Sussex, tó sì tún gboyè ìmọ̀ òfin ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì University of London.
Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ló wà tó fi darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Conservative.
Ní ọdún 2012 ló ṣojú ẹgbẹ́ òṣèlú Conservative níbi ètò ìdìbò ilé aṣòfin London.
Ọdún yìí kan náà ló ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ tó sì ti bí ọmọ méjì báyìí.
Ọdún 2015 ni wọ́n yàn án sí House of Commons láti gba ipò lọ́wọ́ Victoria Borwick.
Lẹ́yìn náà ló du ipò aṣòfin lórúkọ ara rẹ̀ lọ́dún 2016 tó sì gbégbá orókè.
Ó wà lára àwọn èèyàn tó jà pé kí Britain kúrò lára àjọ Yúróòpù, EU èyí tó ti wà sí ìmúṣẹ báyìí.
Ó dupò Olóòtú ìjọba UK lọ́dún 2022 àmọ́ tí ipò náà já mọ́ Rishi Sunak lọ́wọ́.















