Obìnrin kan bọ́ ara rẹ̀ sí ìhòhò ní fásitì kan nílẹ̀ Iran láti tako wíwọ Hijab

Aworan obinrin to jokoo ni fasiti Islamic Azad niluu Tehran lorilẹede Iran

Oríṣun àwòrán, Telegram

Àkọlé àwòrán, Aworan obinrin to jokoo ni fasiti Islamic Azad niluu Tehran lorilẹede Iran
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Parham Ghobadi

BBC News Persian

Awọn ajafẹtọọ ọmọniyan ti ke pe awọn alaṣẹ ijọba orilẹede Iran lati tu obinrin kan to bọ aṣọ ara rẹ ni ile ẹkọ giga fasiti Azad niluu Tehran lorilẹede naa silẹ ni atimóle.

Ijọba ni obinrin yii gbe igbesẹ naa lati tako ofin wiwọ hijaabu fawọn obinrin ti ijọba gbe kalẹ ni.

Lọjọ Abamẹta ọsẹ to kọja ni fọnran kan ṣafihan obinrin kan to ku aṣọ awọtẹlẹ lasan lara rẹ nibi to ti jokoo ni fasiti Azad niluu Tehran.

Fidio mii tun ṣafihan bi obinrin naa ti bọ aṣọ awọtẹlẹ to wa lara rẹ gan an.

Lẹyin naa lawọn ẹṣọ fi tipa tipa mu wọ inu ọkọ lọ.

Ẹwẹ, fasiti Azad ti sọ pe arun ọpọlọ lo n da obinrin naa laamu, ati pe wọn ti gbe e lọ si ile iwosan awọn alarun ọpọlọ fun itọju.

"Obinrin yii n ja fawọn obinrin ni lori oriṣiiriṣii ofin ti ijọba fi de wọn lati ori lilo ibori titi de wiwọ aṣọ gigun"

Ọpọ obinrin lorilẹede Iran lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu ọrọ ti ile ẹkọ giga fasiti fi sita lori obinrin naa.

Wọn ni obinrin yii n ja fawọn obinrin ni lori oriṣiiriṣii ofin ti ijọba fi de wọn lati ori ki wọn maa bori titi debi ofin to ni awọn obinrin gbọdọ maa wọ aṣọ gigun.

O le ni ẹẹdẹgbẹta eeyan to ku lasiko iwọde to waye lọdun meji sẹyin lẹyin ti obinrin kan, Mahsa Amini, ki si atimọle ọlọpaa lori ẹsun wi pe ko wọ hijaabu daadaa.

Iwe iroyin Amirkabir to wa lori itakun Telegram lo kọkọ gbe iroyin naa wi pe ede-ai-yede bẹ silẹ obinrin naa ati awọn agbofinro lori ẹsun wi pe ko we sikaafu rẹ daadaa.

Bayii ni ifanfa ṣe bẹrẹ laarin obinrin yii atawọn agbofinro ti obinrin naa si bọ aṣọ ara rẹ.

Iwe iroyin naa sọ pe obinrin fori gba ilẹkun ọkọ ti wọn fẹ gbe e wọ ni tipa tipa, eyi to n si n ṣẹjẹ, amọ, wọn pada gbe e lọ ibi ti ẹnikẹni ko mọ ni.

Aworan obinrin to jokoo ni fasiti Islamic Azad niluu Tehran lorilẹede Iran

Oríṣun àwòrán, Telegram

Awọn oṣojumikoro ṣalaye pe obinrin naa sọ fawọn akẹkọọ wi pe oun wa lati daabo bo wọn ni

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O ṣoju mi koro kan sọ fun BBC Persian ṣadeedee ni obinrin naa wọ yara ikẹkọọ awọn ti o si bẹrẹ si ni ṣe fidio awọn akẹkọọ.

O sọ pe nigba ti olukọ tako o ni o bẹrẹ sii pariwo ti o si binu jade.

Awọn o ṣoju mi koro mii ṣalaye pe obinrin naa sọ fawọn akẹkọọ wi pe oun wa lati daabo bo wọn ni.

Ileeṣẹ iroyin orilẹede Iran gbe fidio ọkunrin kan sita ẹni ti wọn pe ni ọkọ obinrin yii tẹlẹ ri.

Ọkunrin yii ti eeyan ko le ri oju rẹ daadaa ninu fidio ọhun lo rọ awọn eeyan wi pe ki wọn maa pin fidio obinrin ka ori ayelujara tori awọn ọmọ rẹ.

BBC ko tii le fi idi ọrọ ti ọkunrin naa sọ mulẹ.

Azam Jangravi to jẹ ajafẹtọọ ni Canada ṣalaye pe nigba to sẹ ifẹhonuhan tako wiwọ hijaabu, awọn ẹṣọ mu oun, wọn si sọ fun ẹbi oun lati kede pe oun ti larun ọpọlọ.

Jangravi sa lọ Canada lọdun 2018 lati lọ ṣe atipo lẹyin ti ijọba dajọ ẹwọn ọdun mẹta fun un lori ẹsun wi pe o bọ hijaabu rẹ lasiko iwọde.

Ẹwẹ, ajọ ajafẹtọọ Amnesty International ti ke pe ijọba Iran lati tu akẹkọọ tawọn agbofinro fi tipa tipa mu silẹ ni kiakia.

Aṣoju ajọ iṣọkan agbaye UN lori ọrọ naa, Mai Sato, naa ti sọrọ loju opo X rẹ pe oun n wo ibi ti ọrọ naa yoo yọri si.

Narges Mohammadi ọmọ Iran to ti gba ami ẹyẹ Nobel Prize fun alaafia amọ to wa lẹwọn bayii ni Iran sọ pe ọrọ obinrin tawọn ẹṣọ mu n kọ oun lominu.