Ṣé lóòótọ́ ni Oluwo lé Ooni kúrò ní Ààfin? Olugbon ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́

Aworan Oluwo ati Ooni ti ilu Ile Ife

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Olugbon ti Orile Igbon, Oba Francis Alao ti ṣalaye idi pataki to fi yẹ ki alaafia jẹ jọba laaarin awọn ọba ilẹ Yoruba.

Bakan naa ni Olugbon ṣalaye ohun to waye laaarin Ooni ti Ilu Ile Ife, Oba Enitan Adeyeye Ogunwusi ati Oluwo ti Ilu Iwo, Oba Adewale Akanbi.

Bẹẹ ba gbagbe, iroyin kan lu sita loṣu to kọja nigba ti fọnran kan jade sori ayelujara nibi ti Ooni ti ni Oluwo le oun kuro ni aafin rẹ.

Bo ti lẹ jẹ pe Ileeṣẹ BBC ko le fidi ọrọ naa mulẹ tabi sọ pe ojulowo ni fọnran naa.

Olugbọn tẹnu bọ ọrọ lasiko to n ba BBC Yoruba lori idi ti ipade lọbalọba ilẹ Yoruba fi fẹ waye.

N ko mọ bi wọn se gbe fọnran ohun sita ati pe eewọ ni pe ki Ọba le Ọba kuro ni aafin - Ooni

Nigba to n ba BBC sọrọ, Oba Francis Alao ni oun kan si Ooni ti Ilu Ile Ife lẹyin ọjọbi rẹ, ti Ooni si bura pe ọrọ ko ri bi o ṣe wa lori ayelujara.

“Ooni ni oun ko lọ si ọdọ Oluwo, koda Ooni ni oun ko mọ bi wọn se gbe fọnran naa sita ati pe eewọ ni pe ki Ọba le Ọba kuro ni aafin.

“Mo wa pe Oluwo, Oluwo ni Ooni ko wa si ọdọ oun, ki oun ma sọrọ."

'Gbogbo Oba Yoruba ni lati ṣe ara wọn ni ọkan'

Aworan Olugbon ti Orile Igbon

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Mo kan si Ooni pe ki gbogbo Oba Yoruba pe ipade ti yoo pari ija abẹle, ka si se ara wa lọkan - Olugbon

Oba Alao ni idi ree ti oun fi kan si Ooni pe o ṣe pataki ki gbogbo Oba ilẹ Yoruba se ara wọn ọkan, ki irẹpọ si wa laarin wa.

Kabiyesi ni ipade ti awọn n gbero yii yoo fi aye silẹ lati ba ara wọn sọ otitọ ọrọ ati lati jẹ ki irẹpọ wa ni ilẹ Yoruba.

“A gbọdọ gbe ilẹ Yoruba larugẹ, a gbọdọ mu irẹpọ wa laarin awọn Ọba.

Ítiju ni ki a gbọ lori ayelujara pe Oluwo le Ooni kuro ni aafin, ko pọn wa le, iyẹn ko gbọdọ waye.

“Gbogbo ija abẹle yoo wa sopin pẹlu ipade.”

Ki ni pataki ipade lọbalọba yii?

Olugbon ti Orile Igbon ni ọpọlọpọ awọn Oba igbalode lo n pe ara wọn ni nnkan ti wọn ko jẹ, ti oun si gbagbọ pe ipade awọn lọbalọba yii yoo tan imọlẹ si ọpọ nnkan.

Bakan naa Oba Alao fẹsun kan awọn lọbalọba kan to n yi itan pada.

“Awọn Ọba mii, ọtọ ni bi ilu rẹ se jẹ laye atijọ, ọtọ ni bi o se ni awọn jẹ lonii nitori o fẹ gbe ara rẹ ga, pe ko si bi o se jẹ.

“Ki ni yii n fa wahala, ko si kan awọn oloselu, ti wọn si gba wọle, to si n fa iwa ibajẹ,eyi ti ko jẹ ki ọba ni iyi mọ.

“Iru awa bayii, ta ni ko mọ itan wa, Olugbon ni, Aresa ni, Onikoyi, itan jẹ nnkan ti a ko le fi pamọ.

“Sugbọn Ọba to de lẹyin wa, wọn ni ko si bi awọn o se jẹ.

“Ti ẹ ba de si ẹsẹ ifa, ẹ ma ba Olugbon n bẹ, Aresa n bẹ ati Onikoyi

“Ai fi ọwọ fagba, ni ko jẹ ki aye gun nitori ẹ ni Baalẹ ilu yoo ni Ọba alaye ni oun, ti awọn oloselu yoo si sọ di Ọba alade.

“Eyi ti da ọpọ nnkan ru sugbọn emi ati Ooni ti a wa ojutu si ọrọ naa.