EFCC gbé Ifeanyi Okowa, gómìnà àná ní Delta lórí ẹ̀sùn lílo 40BN láti ra afẹ́fẹ́ gáàsì àtàwọn ẹ̀sùn míì

Aworan Gomina ana nipinlẹ Delta, Ifeanyi Okowa

Oríṣun àwòrán, Facebook/Dr. Ifeanyi Arthur Okowa

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ to n gbe ogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, EFCC ti mu gomina ana nipinlẹ Delta, Ifeanyi Okowa, fun ẹsun siṣe owo to 1.3 trilọnu naira to jẹ owo ilu mọkumọku laaarin ọdun 2015 ati 2023.

Ọjọ Aje, ọjọ kẹrin Oṣu kọkanla ọdun 2024 ni ọwọ tẹ Okowa niluu Port Harcourt nipinlẹ Rivers nigba ti o farahan fun ara rẹ ni ọfisi EFCC lẹyin ti wọn ransẹ pe.

Ẹsun ti wọn fi kan Okowa ni o da lori bi o ṣe kuna lati ṣalaye bo se na owo toto ogoji biliọnu naira to ni oun fi ra afẹfẹ gaasi.

Bakan naa ni wọn tun fi ẹsun kan Okowa pe o ra pin idokowo toto Ogoji bilọnu naira ni awọn ileeṣẹ ifowopamọ lorilẹede Naijiria.

EFCC tun ni wọn Okowa tun lo owo ijọba lati awọn ilegbe kan niluu Abuja ati Asaba nipinlẹ Delta.

Okowa sun ọfisi EFCC mọju niluu PortHarcourt.

Bẹẹ ba gbagbe, Okowa ni igbakeji oludije sipo aarẹ labẹ aisa ẹgbẹ oṣelu PDP ni ọdun 2023.

Awọn Gomina mii to tun n rojọ niwaju ajọ EFCC

Okowa kọ ni gomina ana akọkọ ti yoo wọ gau ajọ EFCC lorilẹede Naijiria.

Ni ọdun 2018, Gomina tẹlẹri nipinlẹ Ekiti naa dero ọfisi EFCC fun ẹsun iwa ibajẹ lorisirisi, ti ọrọ naa ti de ile ẹjọ.

Ni ọdun 2022, Gomina ana nipinlẹ Anambra, Willie Obiano, naa dero atimọle EFCC lẹyin to gbe ijọba silẹ fun Gomina Charles Soludo.

Bakan naa, Gomina, Abdulfatah Ahmed ti ipinlẹ Kwaran jẹjọ lọwọ ni ile ẹjọ lori ẹsun sise owo ilu mọkumọku lasiko to jẹ Gomina.