''Àtúnṣe tí UK fẹ́ ṣe lórí òwò-ẹrú tó wáyé ní Áfíríkà kìí ṣe nípa fifi owó ránṣẹ́ ṣáwọn orílẹ́èdè tọ́rọ̀ kàn''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Nkechi Ogbonna
- Role, BBC Africa
- Reporting from, Lagos
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Akọwe ijọba UK to n ri si ọrọ ilẹ okeere, David Lammy, ti sọ pe ọrọ atunṣe lori bi Ilẹ Gẹẹsi ti kawọn orilẹede lẹru kii ṣe nipa sisan owo fawọn ọrilẹede tọrọ kan naa.
Ọgbẹni Lammy ṣalaye wi pe ijọba UK ti sọ tẹlẹ naa pe oun ko ni sanwo lati ṣatunṣe fun bi Ilẹ Gẹẹsi sẹ ko awọn orilẹede kan lẹru.
O ni ohun ti ijọba sọ ni pe awọn ọna mii loun yoo gba lati ṣe ododo fawọn orilẹede tọrọ kan naa, eyi ti ko ni la owo sisan lọ.
Lammy sọ pe ''ọrọ atunṣe nipa owo-ẹru ko ni nnkan ṣe pẹlu fifi owo ranṣẹ sawọn orilẹede tọrọ kan papaa julọ pẹlu bi ọwọngogo nnkan ṣe gbode kaakiri agbaye bayii to fi mọ UK gan an.''
Nigba ti o n sọrọ niluu Eko to jẹ ọkan lara ibi ti wọn maa n lo lati ko ẹru ni Naijiria lọ si oke okun lasiko owo ẹru, lammy sọ pe o ṣe pataki bi ijọba UK ṣe kọkọ tọrọ aforijin lori owo ẹru to waye.
Lammy to ṣabẹwo si Afirika fun igba akọkọ ni oriṣiiriṣii iṣẹlẹ buruku lo waye lasiko owo ẹru.
Ọgbẹni Lammy apa owo ẹru to waye si wa lara awọn orilẹede ti Ilẹ Gẹẹsi ko lẹru titi di oni.
Lammy sọ pe idi gan an niyi ti ijọba UK fi tọrọ aforijin lori owo ẹru.
Lammy ṣalaye pe awọn orilẹede Caribbean ti Ilẹ Gẹẹsi ko lẹru ti ṣe agbekalẹ koko mẹwaa fun atunṣe ati ododo lori owo ẹru.
Akọwe ijọba UK fun ọrọ ilẹ okeere sọ pe o ni igbagbọ pe awọn orilẹede Afirika naa yoo janfaani ninu eto yii.
Lara awọn eto atunṣe ti ijọba UK fẹ ṣe ọhun ni nipa kikọ awọn eeyan lẹkọọ imọ sayẹnsi ati imọ ijinlẹ.
Ọpọ awọn olori orilẹede ti Ilẹ Gẹẹsi ṣe owo ẹru nibẹ ni wọn ti n ke pe ijọba UK lati sanwo fawọn orilẹede tọrọ kan tori owo ẹru ti wọn ṣe nibẹ.
Ṣaaju aoero to waye ni Samoa lori ọrọ naa ni ijọba ti kọkọ sọ pe asiko ko tii to lati sọrọ lori atunṣe owo ẹru to waye lawọn orilẹede ti ijọba Ilẹ Gẹeṣi ko lẹru.
Amọ, Olootu Ijọba UK, Sir Keir Starmer, ti buwọlu iwe to da lori pipe fun ododo lori ọrọ owo ẹru.
Sir Starmer buwọlu iwe yii pẹlu awọn olori orilẹede ti Ilẹ Gẹeṣi ko lẹru.

Oríṣun àwòrán, FCDO
Lammy to ba BBC sọrọ ki o to gunle irinajo rẹ si ilẹ Afirika nibi ti yoo ti de Naijiria ati South Africa ṣalaye pe oun fẹ ṣe ifilọlẹ itakurọsọ pẹlu awọn orilẹede Afirika eyi ti yoo waye fun oṣu marun un.
Lammy ni oriṣiiriṣii nkan ni iyatọ ti de ba lati igba ti ẹgbẹ oṣelu oun ti wa ni ijọba ni UK lasiko Olooto Ijọba Tony Blair ati Gordon Brown.
O ni ijọba Blair ati Brown mu ọrọ ilẹ Afirika ni ọkunkundun lasiko ijọba wọn.
Lammy ni oun ti ri oriṣiiriṣii ọna ti ijọba UK ti le ṣiṣẹ pọ pẹlu Naijiria papaa julọ pẹlu awọn nnkan toun ti ri niluu Eko.
Lammy fidi rẹ mulẹ pe ọrọ mii to tun jẹ ijọba logun yatọ si ọrọ owo ẹru ni rogbodiyan to n ṣẹlẹ ni Sudan.
O ni ijọba ṣetan lati ṣiṣẹ lori ọrọ naa loṣu Kọkanla yii.
Ọgbẹni Lammy ni bi ẹmi awọn eeyan ṣe n ṣofo lorilẹede Sudan n kọ ijọba UK lominu.
''UK ti di alaga igbimọ apaṣẹ lori eto abo ni ajọ iṣọkan agbaye, UN, mo maa jẹ ki ọrọ Sudan wa lori ọrọ ti a fẹ ṣiṣẹ le lori loṣu yii.
Mo maa wa niluu New York nibi ipade ajọ iṣokan agbaye, nibẹ ni mo ti maa sọrọ orilẹede Sudan.
Kii ṣe ẹkun ila oorun ilẹ Afirika nikan rogbodiyan to n ṣẹlẹ ni Sudan ni ipa le lori, ọrọ naa kan gbogbo ilẹ Afirika, koda o tun kan ilẹ Yuroopu naa,'' Lammy lo sọ bẹẹ.















