Kí ni Peter Obi sọ tí ọ̀pọ̀ ẹnu fi ń kùn ún lórí ayélujára?

Aworan Peter Obi

Oríṣun àwòrán, X/Honest Bunch

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party ninu eto idibo ọdun 2023, Peter Obi ni pupọ awọn nnkan ti oun sọ nipa siṣe iso ooun ni awọn ile ijọsin ni awọn eeyan kan ti gba sodi, to si yatọ ohun ti ohun sọ.

Gomina tẹlẹ nipinlẹ Anambra ni ọpọ bu ẹnu atẹlu lẹyin ifọrọwerọ to ṣe lori Honest Bunch lọjọ Satide to kọja.

Nigba to n tẹnu bọrọ lori iniran ti ọpọ awọn ọmọ Naijiria n la kọja ati iha ti awọn araalu kọ si oṣelu ati ẹṣin, Obi ni ọpọlọpọ akoko ni awọn araaalu n lọ lati wa ni ile ijọsin lati Ọjọ Aje si Ọjọ Ẹti.

Ọrọ yii ni ko dun mọ ọpọ awọn ọmọ Naijiria, ti wọn si bu ẹnu atẹlu pe ko yẹ ki ọrọ naa jade lẹnu Peter Obi.

Nini atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Ibrahim Umar gbe sita lori ayelujara, Gomina tẹlẹ naa ni ọrọ naa ni ọpọ gba sodi, ti ko si ri bẹ.

“Wọn ti pe akiyesi wa ọrọ kan to n ja lori ayelujara pe ifọrọwerọ ti mo se laipẹ, mo n pe fun ituka ile ijọsin lorilẹede Naijiria.

“Pẹlu awọn akọle ti mo ri lori iwe iroyin, ọrọ mi ni ọpọ ti si gbọ, ti wọn si ti gba sodi.

“Olori ẹgbẹ oṣelu Labour Party ni ọpọ mọ pe o jẹ onigbagbọ ti o ni ọpọ ibọwọ fun eyikeyi ẹsin, ti o si sọrọ nibi ifọrọwerọ naa nipa bi ẹsin ṣe le ni ipa ninu igbesi aye awọn araalu.

“Obi, nnkan to n sọ lo da lori ohun ti Apostle James sọ ninu iwe ‘Igbgbọ lai si iṣẹ’ ko ni ipa kankan. Nigba ti Obi ni oun yoo yii iso ooru si iṣẹ alẹ to lere, oun to n sọ lo da lori siṣe iṣin fun Ọlọran lati ara iṣẹ.

“Koda Jesu Kristi ko mu eyikeyi awọn ọmọ lẹyin rẹ nigba ti wọn gba dura sugbọn o mu wọn nigba ti wọn ṣe iṣẹ pẹjapẹja, gbigba owo ori ati bẹbẹ lọ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

"Ọpọ ọkunrin ni yoo maa mura bii obinrin ti ofin ijọba ba gbe fun awọn obinrin nikan"

Peter Obi gba ijọba apapọ ni imọran pe ki wọn yọ awọn amuludun silẹ paapa awọn ọkunrin to n mura bi obinrin kuro ninu awọn ofin kan.

O gba imọran yii nigba to n sọrọ nipa Idris Okuneye, ẹni ti ọpọ mọ si Bobrisky, o ni Bobrisky ati awọn yooku bẹrẹ si ni mura ibi obinrin nitori bi eto Aje ṣe mẹhẹ.

Gomina tẹlẹri nipinlẹ Anambra ni ọpọ awọn ọkunrin ni o ṣeeṣe ki wọn ma mura bi obinrin ti ijọba ba pinnu lati ma gbe awọn ilana to wa fun obinrin nikan.

“Nigba ti awọn eeyan sọ fun nipa Bobrisky, mo ni awọn ọdọ to nse amuludun kan wa ti o yẹ ki ofin fi aye gba wọn.

“Amuludun ree. Ti ijọba ba sọ pe epo di N800 lonii sugbọn N400 fun awọn obinrin, ọpọ ọkunrin ni yoo ma mura bi obinrin.”