Ìdí márùn ún tó fi ṣeéṣe kí Trump tàbí Harris borí ìbò Ààrẹ Amẹrika

US election

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ni bayii to ku ọjọ kan ṣosọ ki eto idibo Aarẹ ilẹ amẹrika waye, awọn onimọ ti sọ pe eyikeyi ninu Donald Trump tabi Kamala Harris lo le bori idibo naa.

Lootọ awọn mejeji ni wọn ni awọn ololufẹ wọn, ti awọn ololufẹ naa si gbagbọ pe ẹni ti awọn n fẹ ni yoo wọle.

Wayin o, awọn onimọ nipa oṣelu ilẹ Amẹrika kan ti sọ pe o ṣeeṣe ki wọn tun dibo yan Trump lẹẹkan si lẹyin to ti kọkọ lulẹ ninu ibo to kọja gẹgẹ bii Aarẹ, eyi ti yoo jẹ akọkọ iru rẹ lati aadoje ọdun sẹyin.

Idi to fi ṣeeṣe ki Trump jawe olubori ree

election

Oríṣun àwòrán, Galllup

1. Kii ṣe oun lo wa lori ipo lọwọ

Ọrọ aje jẹ ohun kan gboogi to ṣe pataki si awọn oludibo lọwọ yii, ọwọngogo si ti gbode nilẹ Amẹrika, eyii ti wọn ko tii ri iru rẹ ri lati ọdun 1970.

Lati ibẹrẹ ọdun 2020 ti arun Covdi-19 mi agbaye titi lawọn oludibo ti bẹrẹ si n dibo fun ẹgbẹ alatako latari ọwọngogo to gbode lẹyin arun naa.

Lọwọ yii, ida marindinlọgbọn awọn ọmọ Amẹrika pere lo sọ pe inu awọn dun si bi nkan ṣe ri nilẹ naa, ti ida aadọta ninu wọn si sọ pe awọn n fẹ ayipada.

2. Awọ iroyin bururu nipa Trump ko ṣe ipalara fun un

Bo tilẹ jẹ pe oniruru ipenija ni Trump ti dojukọ, bii ifẹhonuhan to waye ni gbagede US Capitol lọdun 2021 atawọn oniruru igbẹjọ, awọn ololufẹ rẹ ko dẹyin lẹyin rẹ.

Lootọ ni awọn ọmọ ẹgbẹ Democrat kan n sọ pe ọknrin naa ko yẹ ni ẹni ti yoo maa tukọ Amẹrika, pupọ ninu awọn ọmọ ẹgẹ Republican lo n sọ pe oun gan lawọn n fẹ.

3. Ko faramọ bi awọn atọhunrinwa ṣe n wọ ilẹ Amẹrika lọna aitọ

Ki eeyan ti yoo bori eto idibo ilẹ Amẹrika ni lati ṣe awọn nnkan ti awọn eeyan n fẹ.

Fun awọn ọmọ ẹgbẹ Democrat kan, ọrọ oyun ṣiṣẹ jẹ wọn logun, fun awọn ti Republican, ọrọ awọn ọmọ ilẹ mii si orilẹede wọn lo jẹ awọn logun.

Awọn oludibo Amẹrika ni igbagbọ ninu Trump pe yoo tilẹkun mọ awọn ọmọ ilẹ okere to fẹ maa wọ ilẹ naa lọna aitọ.

election

Oríṣun àwòrán, Pew Research Center

4. Ko ta awọn ti ko kawe sẹyin

Lara awọn oludibo ti Trump n ko mọra lawọn ti awujọ ti ta nu latari pe wọn ko kawe.

4. Ọpọ n ri bii akinkanju ọkunrin

Ọpọ ọmọ Amẹrika lo n binu si ijọba to wa lori oye latari bo ṣe n fi owo ranṣẹ si Ukraine ati Israel fun ogun to n lọ lọwọ nibẹ.

Awọn eeyan naa ni agbara Amẹrika ti dinku labẹ ijọba Biden, awọn si n fẹ Aarẹ mii to jẹ akikanju.

Idi to fi ṣeeṣe ki Kamala Harris jawe olubori ree

1. Kii ṣe Trump

Harris ni awọn ibo kan lati le dije ninu ẹgbẹ Republican lọdun 2020 amọ o lulẹ lẹyin ti miliọnu meje eeyan ṣatilẹyin fun Biden.

Iwadii kan ti ileeṣẹ iroyin Reuters ati Ipsos ṣe ninu oṣu Keje ọdun 2024 fi han pe ọpọ ọmọ Amẹrika lo gbagbọ pe nnkan ko lọ dede nilẹ naa, Harris si gbagbọ pe awọn eeyan yoo dibo fun oun dipọ Trump nitori iyatọ iwuwasi awọn mejeji.

2. Kii tun ṣe oun ni Biden

Diẹ lo ku ki ireti ẹgbẹ Democrat ja kulẹ ki Biden to kede pe oun ko ni dije mọ, eyii to mu ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ gbaruku ti Harris lati le fidi Trump janlẹ.

Nipa ti ọjọ ori, awọn kan ti kọkọ sọ pe Biden ko tọ si ipo Aarẹ naa latari ọjọ ori rẹ, amọ bayii, ti Trump ba wọle, yoo jẹ Aarẹ to dagba ju nipo naa.

US Election

Oríṣun àwòrán, Getty Images

3. O n ja fun ẹtọ awọn obinrin

Ọpọlọpọ awọn to n ṣatilẹyin fun Harris lo n ṣe bẹẹ nitori o fọwọ si ki awọn obinrin maa ṣẹ oyun gẹgẹ bii ẹtọ wọn labẹ ofin.

Yatọ si eyii, o tun ṣeeṣe ko jẹ oun ni yoo jẹ Aarẹ obinrin akọkọ nilẹ Amẹrika.

4. O ṣeeṣe ki ọpọ ninu awọn olulufẹ rẹ jade lati dibo fun

Pupọ ninu awọn eeyan to n ṣatilẹyin fun Harris, bii awọn ọmọ ile ẹkọ ni yoo jade lati dibo, iyẹn gẹgẹ bii ohun ti awọn onimọ sọ.

5. O ti na ọpọlọpọ owo

Kii ṣe ohun aṣiri pe ọpọ owo ni ibo maa n jẹ l’Amẹrika ati kaakiri agbaye, a si gbọ pe owo ti wọn n na lori idibo Amẹrika ọdun yii yoo pọ ju ti atẹyinwa lọ.

To ba jẹ nipa owo nina, Harris ko kere.

Lati igba ti wọn ti kede rẹ gẹgẹ bii oludije lawọn eeyan ti bẹrẹ si n kowo jọ fun un, owo ti wọn si da fun pọ ju eyii ti wọn da fun Trump lọ.

Iroyin ni o ṣeeṣe ki ẹni to na owo julọ gba ipo naa lẹyinorẹyin.

US Election

Oríṣun àwòrán, AdImpact