"Tọkọtaya tó ń wa kẹ̀kẹ́ Márúwá ni wà àmọ́ epo tó wọ́n là ń sìn, ọjọ́ Iléyá ni inú mi ti dùn gbẹ̀yìn"

Àkọlé fídíò, Tricycle Couple: "Owó wà nídìí wíwa kẹ̀kẹ́ tẹ́lẹ̀ àmọ́ ọ̀wọ́n epo ti mú kí iṣẹ́ náà sú wa"
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Yoruba ni isẹ ori ran mi ni mo n se, ẹni to ba jale lo ba ọmọ jẹ, Oluwa nikan lo si mọ isẹ asela.

Awọn tọkọtaya kan ree, Olukoya ati Adenike Akinbo, to jẹ pe isẹ kannaa ni awn mejeeji yan laayo, ti wọn n pawo wọle lati ri ọwọ bu lọ si ẹnu.

Isẹ naa ni isẹ wiwa kẹkẹ maruwa nilu Abeokuta, wọn sa ni ohun ti ọkunrin n se, awọn obinrin naa le se.

N jẹ ki lo sun tọkọ taya naa de idi isẹ yii?

Isẹ wo ni wọn n se tẹlẹ, ki wọn to maa wa kẹkẹ Maruwa, awọn ipenija wo si lo n koju wọn?

Ọna lati wa idahun sawọn ibeere yii lo mu ki BBC Yoruba tọ tọkọtaya Akinbo lọ, tawọn mejeeji si sọrọ, ti ilẹ kun.

Olukoya ati Adenike Akinbo

"Alaye ree lori idi ti mo se gba pe ki iyawo mi maa sisẹ wiwa kẹkẹ Maruwa pẹlu mi"

Nigba ti wọn ba BBC Yoruba sọrọ, Olukoya ati Adenike Akinbo salaye pe ilu to le lo gbe awn de idi isẹ wiwa kẹkẹ Maruwa.

Wọn ni ọkọ lo kọkọ n wa kẹkẹ Maruwa, to si n mu owo wọle eyi to wu iyawo rẹ lori, ti oun naa se pinnu lati maa sisẹ naa.

Olukoya Akinbo ni "Isẹ ayaworan si ara asọ adirẹ ni mo n se amọ isẹ naa ko ya deedee ni mo se fi isẹ Maruwa kun.

Idi ree ti mo se gba idi isẹ wiwa Maruwa lọ, to si n mu owo wa, eyi ti emi ati mọlẹbi mi fi n jẹun.

Ọdun kẹrinla ti mo ti n wa kẹkẹ ree, nigba ti mo di ẹni to n wa Maruwa, owo to n wọle yatọ.

Nigba ti iyawo mi ni oun naa fẹ se isẹ wiwa kẹkẹ Maruwa, mo yari pe ko le se isẹ naa amọ o ni se emi nikan ni maa ma sisẹ ni."

Olukoya ati Adenike Akinbo

"Mo kọ isẹ ọwọ aransọ amọ awọn onibara n ran asọ lai fun oun lowo isẹ, ni mo se n wa kẹkẹ Maruwa"

Ninu ọrọ tiẹ naa, Adenike Akinbo sọ fun BBC Yoruba pe oun kọ isẹ ọwọ aransọ amọ se ni awọn onibara n ran asọ lai fun oun lowo isẹ.

"Nigba to ya, mo tun n ta ohun mimu ẹlẹrindodo amọ owo ti mo n mu wọle ko to nnkan.

Amọ isẹ Maruwa n jẹ ki n maa ri owo pa wọle bi o tilẹ jẹ pe ọkọ mi taku tẹlẹ pe n ko le sisẹ naa.

Amọ bukata wa to pọ lo jẹ ko gba pe ki n dara pọ mọ oun lati maa wa kẹkẹ Maruwa.

Emi kii se ọlẹ, emi ati ọkọ mi dijọ n sisẹ papọ ni, ti a si dijọ n fi ọwọ wẹ ọwọ.

A ko fi nnkan pamọ fun ara wa, amọ a dijọ n fi ọwọ sowọpọ lati pa owo wọle ni."

Adenike Akinbo

"Tori ọwọn epo, isẹ wiwa kẹkẹ Maruwa ko mu owo wọle mọ, epo la n sin"

Nitẹsiwaju ninu ọrọ wọn, tọkọtaya Akinbo wa n fi ika hanu pe isẹ wiwa Maruwa ko mu owo gidi wọle mọ.

Olukoya salaye pe "Epo la n fi ọpọ owo ta n pa ra, owo ti a n pa nidi wiwa Maruwa ko da bii ti tẹlẹ mọ.

Ọjọ kan tiẹ wa, ti mo sisẹ lati aarọ di alẹ amọ ti n ko ri owo kankan pa wọle."

Bakan naa ni iyawo rẹ, Adenike ni "Isẹ wiwa Maruwa ko mu owo wọle mọ, ti n ba ri owo miran ni, maa lọ si sọọbu, maa maa ta ọja.

Ọjọ dun Ileya ni inu mi ti dun julọ tori isẹ naa ti ko dabi m.

Mo maa n gba epo nibikan ni awin, maa si lọ sanwo pada ni alẹ amọ epo to wọn ko jẹ ki ọkan mi balẹ mọ.

Ọjọ kan wa ti mo fi epo ẹgbẹrun mẹtala Naira pa ẹgbẹrun mẹrindinlogun Naira, mo ro pe aye n se mi ni."