Láé, n kò jẹ́ tàpá sí Oníṣẹ̀ṣe, èmi gan ti gbé Egúngún rí - Yinka Ayefele

Gbajugbaja Olorin ti o tun jẹ oludasilẹ ileeṣẹ redio Fresh Fm, Yinka Ayefẹlẹ ti sọrọ sita lori awuyewuye to rọ mọ alejo to kopa lori eto kan ti wọn pe ni 'Ọpẹyẹmi' ni bii ọsẹ kan sẹyin.
Wọn ko fi oju alejo ti a n sọ nipa rẹ yii han lori eto naa, ṣugbọn ohun rẹ nikan ni awọn eeyan gbọ lori eto naa. Awọn ọrọ ti alejo yii sọ lagbara pupọ, nitori pe o ni ohun se pẹlu awọn iwa laabi ti o ti hu sẹyin, bii jijẹ ẹran ara eeyan, igbenipa ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ṣugbọn eyii to fa awuyewuye gan an ninu gbogbo ọrọ ti alejo naa sọ fun Ayefẹlẹ lori eto naa ni bi oun ṣe pa awọn eeyan mejidinlọgọrin, ti si ta ẹjẹ wọn silẹ fun Oriṣa.
Eyii lo bi awọn ẹgbẹ Oniṣẹṣe ninu, ti wọn si pariwo sita nigba ti wọn se iwọde l sileesẹ redio Ayefele wi pe Oriṣa kii gba ẹbọ tabi etutu ti a fi ẹmi ẹniyan ṣe.
"Ọrọ ti alejo mi sọ lori redio ko fi ẹsun kan awọn Oniṣẹṣe rara, itan igbesi aye ara rẹ lo n sọ"
Awuyewuye to rọ mọ eto yii lati ọdọ awọn Onisẹse lo mu ki Ayefẹlẹ gbe igbesẹ lati tan imọlẹ si ọrọ naa.
Ninu alaye to ṣe lasiko ti o pe wọle si ori eto 'Yinka TNT' lori ikanni ibanidọrẹ Facebook, Ayefẹlẹ ni Arakunrin to kopa lori eto oun kii ṣe Oniṣẹṣe tabi Oloriṣa.
"Iṣẹ agbenipa gan an lo n ṣe tẹlẹri, awọn ilu to si ti lọ ṣe oogun bii Tapa ati Ṣaki si ni wọn ti ba ṣe etutu 'Apayọ',
Apayọ yii lo maa n jẹ ki apaniyan naa ji pada saye, ti wọn ba pa a lẹnu iṣẹ.
Ayefẹlẹ fi kun ọrọ rẹ wi pe, ọrọ ti alejo oun sọ ko fi ẹsun kan awọn Oniṣẹṣe rara, nitori pe itan igbesi aye ara rẹ lo n sọ.
O ni gbogbo ohun ti o si sọ lori redio kii ṣe nnkan to n ṣẹlẹ lọwọlọwọ, nitori pe ẹni ti a n sọ nipa rẹ yii ti di atunbi, o si ti wa nile ẹkọ Bibeli ti a mọ si 'Seminary' lati ọdun mẹrin sẹyin.
Ayefẹlẹ ni oun ko le tabuku awọn Oniṣẹṣe ati ẹsin abalaye rara, nitori oun gan ti gbe eegun ri nigba ti oun wa l'ọmọde niluu Ipoti Ekiti.
Kí ni Yinka Ayefele ṣe fún Tani Olorun àtàwọn Oníṣẹ̀ṣe tí wọn fi ṣe ìwọ́de níléeṣẹ́ Rédíò rẹ̀?

Ara ko rọ okun, bẹẹ ni ko rọ adiẹ niwaju ileesẹ redio Fresh FM, to jẹ ti Olokiki akọrin nni, Yinka Ayefele, eyi to wa ladugbo Challenge, nilu Ibadan.
Se ni ariwo sọ nigba ti Gbajugbaja Oniṣẹṣe, Adegbola Abdulazeez ti ọpọ mọ si 'Tani Olohun' lewaju iwọde lọ si ileeṣẹ redio naa lọjọ Aiku.
Awọn Onisẹse naa lo lọ fi ẹhonu han lori alejo kan to kopa lori eto kan ti wọn pe ni "Opeyẹmi" eleyii ti Ayefẹlẹ n ṣe atọkun fun ni bii ọsẹ kan sẹyin.
Lori eto yii ni alejo naa, to sọrọ labẹ aṣọ, ti n jẹwọ awọn iṣẹ buruku to ti gbe ṣe sẹyin gẹgẹ bii agbenipa ati ọdaran to n fi ẹmi awọn eniyan ṣe etutu aṣeyọri.
Lara awọn nnkan ti alejo naa sọ ninu fọnran ti awọn eniyan n pin kaakiri ori ayelujara ni pe eeyan bii mejidinlọgọrin ni oun ti fi rubọ fun Oriṣa.
Ikede yii si lo ti n fa awuyewuye lati ọdọ awọn araalu, koda, awọn eeyan kan n ke si ileesẹ ọlọpaa lati lọ gbe ọkunrin naa, ko le jiya ẹsẹ ipaniyan rẹ.

Tani Olohun ati awọn akẹgbẹ rẹ ṣe, ni wọn ti fi aidunu wọn han pe Oriṣa kii gba ẹjẹ eeyan
Koda, lara awọn eeyan to n tutọ soke, fi oju gba a, ni awọn Onisẹse, ninu eyi ti a ti ri awọn Ologboni.
Koda, fidio kan tiẹ n ja ranin lori ayelujara nibi ti Onisẹse kan ti n fi apa janu pe ọrọ ti alejo ori redio naa sọ ta abuku ba ẹsin Isẹse.
Awọn Onisẹse, ti ọrọ naa si bi wọn ninu pupọ, gẹgẹ bi wọn ṣe n fi ọrọ lede, salaye pe Oriṣa kii gba ẹjẹ eeyan.
Eyi si lo se okunfa bi ọpọ awọn oniseẹse naa se se iwọde lọ sileesẹ Redio Yinka Ayefele naa.
Ni ibi iwọde naa, ti Tani Olohun ati awọn akẹgbẹ rẹ ṣe, ni wọn ti fi aidunu wọn han lori igbesẹ yii.

"Ẹsin ilẹ Yoruba ti a mọ si Iṣẹṣe, ko fi aye gba lilo ẹjẹ eniyan fun etutu tabi irubọ."
Ọkanojọkan akọle ni wọn gbe lọwọ lati fi ẹhonu han, ti wọn si n sọ awọn ọrọ bii, "Ayefẹlẹ, ma ba ilẹ Yoruba jẹ", "Ẹsin Alaafia ni Iṣẹṣe", "Ko si ipaniyan ninu ẹsin Iṣẹṣe" ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bakan naa ni agbarijọpọ ẹgbẹ awọn Onifa lagbaye, 'International Council of Ifa Religion’, fi atejadẹ ranṣẹ si awọn oniroyin lẹyin eto naa.
Ninu atẹjade ọhun si ni Aarẹ ẹgbẹ naa, Ọmọwe Fayemi Fatunde Fakayode ti n ke si ileeṣẹ Ọlọpaa lati ṣe iwadii gbogbo ọrọ ti alejo Ayefẹlẹ sọ lori redio 'Fresh Fm’.
Fakayode ni, "A ti sọ ọ tẹlẹri, a o si tẹsiwaju lati maa sọ ọ wi pe ẹsin ilẹ Yoruba ti a mọ si Iṣẹṣẹ ko fi aye gba lilo ẹjẹ eniyan fun etutu tabi irubọ."
"Gbogbo awọn to n sọ iru ọrọ yii ni wọn n gba gbogbo ọna lati tabuku ohun ti Ẹlẹda fun wa lati maa bu ọla fun un, ṣugbọn awa o tẹsiwaju lati maa tako wọn.
Lilo ẹjẹ eeyan fun etutu ọla tabi fun ohunkohun ṣe ajeji si ẹsin wa, a o si tẹsiwaju lati maa tako igbesẹ naa."

Lara awọn koko mii ti a le fi idi wọn mulẹ nipa fọnran to fa awuyewuye yii ni wi pe, alejo to sọrọ lori redio Ayefẹlẹ yii ti ṣẹwọn ri fun o kere tan, igba mẹta ọtọọtọ fun awọn iwa ọdaran to hu.
Bakan naa si ni iroyin tun fi idi rẹ mulẹ wi pe ki o to di atunbi ni o ti ṣe awọn iṣẹ laabi naa.
















