Bàbá kan tó bá ọmọ rẹ̀ kọ ìdánwò JAMB, rí ẹ̀wọ̀n he

Oríṣun àwòrán, Others
Ile ẹjọ Magistrate ton jokoo niluu Abuja ti ran Ọgbọn Jide Josiah Jisos lọ si ẹwọn oṣu mẹfa fun bi o se ba ọmọ rẹ obinrin joko fun idanwo UTME ni ọdun 2019.
Onidajọ Folashade Oyekan lo gbe idajọ naa kalẹ niluu Abuja.
Jisos ni ọwọ awọn oṣiṣẹ JAMB tẹ lasiko ti idanwo naa n lọ lọwọ ni ile ẹkọ Brix Academy niluu Abuja.
Atẹjade ti agbẹnusọ fun ajọ JAMB, Dokita Dabian Benjamin fi sita ni Jisos ṣe afihan ara rẹ gẹgẹ aṣoju ileeṣẹ kan ti ki se ti ijọba to wa se amojuto idanwo naa.
Ọwọ palaba rẹ segi nigba ti awọn olori ẹgbẹ to n se amojuto idanwo naa bẹrẹ si ni beere ibeere lọwọ rẹ.
“Asiri rẹ tun nigba ti a ni ko sọ bi o ṣe jẹ, ti ko si ri ohun kankan wi sita.
“A fa le ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ, ti wọn si se iwadii to yẹ lori rẹ.
“Lasiko iwadii, ni o jẹwọ pe oun ki i se aṣoju ileeṣẹ kan ati pe o wa sinu yara idanwo lati se iranlọwọ fun ọmọ rẹ obinrin to se idanwo UTME lọwọ ni ọdun 2019.”
Lẹyin ọlọpọ atotonu, Onidajọ Folashade Oyekan ni Jisos jẹbi ẹsun ti wọn fi kan, ti o si ran lọ si ẹwọn oṣu mẹfa tabi ki o san owo itanran Ẹgbẹrun lọna ọgọrun un nairan.















