Iléẹjọ́ da ẹjọ́ àwọn olùwọ́de ebi ń pa wá nù, ó tú àwọn afurasí sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

Oríṣun àwòrán, Others
Adajo Obiora Egwatu tile ẹjọ giga ijọba apapọ nilu Abuja ti wọgile awọn ẹsun ti wọn fi kan awọnafurasi adaluru to kopa ninu iwọde ẹfopin si ijọba ti ko dara.
Adajọ Egwatu ni oun gbe igbesẹ naa nibamu pẹlu imọran amofin to n soju Agbẹjọro agba nilẹ wa, Abubakar M.D , to ni oun fẹ funra oun tẹwọ gba ẹjọ naa ati pe ki oun yọwọ ninu ẹjọ naa.
Nibi igbẹjọ to waye lonii ni Agbẹjọro agba, Lateef Fagbemi, ti oludari ẹka agbefọba, Mohammed Abubakar soju fun, ni wọn ti kede igbesẹ naa.
Adajọ naa ni ki wọn ko gbogbo awọn afurasi ọhun kuro ni ahamọ ọgba ẹwọn
Lẹyin naa ni agbẹjọro agba wa beere pe ki wọn lo ẹsẹ kẹrinlelaadọjọ ofin ọdun 1999 lati wọgile igbẹjọ awọn eeyan to n jẹjọ naa, ti wọn jẹ mọkandinlọgọfa.
Nitori bi awọn agbẹjọro kankan to lọwọ ninu ẹjọ naa ko se tako ibeere yii, adajọ Egwatu wa fontẹ lu ibeere ọhun, to si wọgile ẹjọ naa.
Bi o tilẹ jẹ pe kii se gbogbo awọn afurasi adaluru naa lo yọju sile ẹjọ, amọ adajọ naa ni ki wọn ko gbogbo awọn afurasi ọhun kuro ni ahamọ ọgba ẹwọn.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ana ọjọ Aje ni aarẹ Bola Ahmed Tinubu kede pe ki agbẹjọro agba wọgile awọn ẹsun ti wọn fi kan awọn afurasi ọhun, ti ọpọ wọn jẹ ọmọde eyi ti ofin ko faaye gba lati koju igbẹjọ.
Wọn ti ko awọn ọmọde to kopa ninu iwọde lọ si ile ijọba nilu Abuja, nibi ti wọn yoo ti fa wọn le gomina ipinlẹ Kano, Abba Yusu, lọwọ
Wayi o, wọn ti ko awọn ọmọde naa lọ si ile ijọba nilu Abuja, nibi ti wọn yoo ti fa wọn le gomina ipinlẹ Kano, Abba Yusu, lọwọ.
Lẹyin naa ni wọn yoo fi baalu gbe wọn lọ sipinlẹ Kano ni irọlẹ oni fun eto atunse, ki wọn to fa wọn le awọn mọlẹbi wọn.
Tinubu pàṣẹ ìtúsílẹ̀ àwọn ọmọdé táwọn ọlọ́pàá jù sí àtìmọ́lé lórí ìwọ́de 'ebi ń pa wá'

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga/X
Aarẹ Bola Tinubu ti paṣẹ itusilẹ gbogbo awọn ọmọde tawọn ọlọpaa ju si atimọle tori wọn kopa ninu iwọde ‘’ebi n pa wa.’’
Awọn ọmọde ọhun ti wọn din diẹ lọgbọn wa lara awọn afurasi mẹrindinlọgọrin ti ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria gbe lọ ile ẹjọ lọjọ Ẹti ọsẹ to kọja.
Ẹsun iditẹmọ ijọba ni wọn fi kan wọn latari bi wọn ṣe kopa ninu ifẹhonuhan ‘ebi n pa wa’ to waye kaakiri Naijiria loṣu Kẹjọ ọdun yii.
Ninu atẹajde ti oludamọran aarẹ lori ọrọ iroyin, Bayo Onanuga, fi sita loju opo X rẹ nirọlẹ ọjọ Aje ni o ti fidi ọrọ yii mulẹ.
Onanuga ṣalaye ninu atẹjade naa wi pe Aarẹ Tinubu ti sọ fun agbẹjọro agba ati minisita eto idajọ wi pe ko ri pe gbogbo awọn ọmọ naa gba ominira.
O ni Tinubu fẹ kawọn ọmọ naa gba ominira nigba ti iwadii yoo maa lọ lori ohun to gbe wọn de ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa eyi to n lọ lọwọ nile ẹjọ.
Onanuga ni ‘’Tinubu tun ti sọ fun ileeṣẹ ijọba to n ri si iranwọ araalu wi pe lati ri pe gbogbo awọn ọmọ yii lo pada sọdọ ẹbi wọn lalaafia.’’
Ọpọ eeyan lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu aarẹ wi pe ijọba rẹ ju awọn ọmọde si atimọle fun oṣu mẹta lati oṣu Kẹjọ tawọn ọlọpaa ti mu wọn lasiko iwọde ‘’ebi n pa wa.’’
Mẹrin ninu awọn ọmọ naa lo ṣubu nigba ti wọn ko wọn wa sile ẹjọ lọjọ Ẹti to kọja, ti wọn si gbe wọn digba digba lọ si ile iwosan fun itọju.
O kere tan mẹtadinlọgbọn ninu awọn ọmọ naa ni ọjọ ori wọn ko tii to ọdun mejidinlogun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Koda, awọn mii ninu wọn ko tii ju ọmọ ọdun mẹrinla lọ, gẹgẹ bi BBC ṣe ri i ninu iwe ti wọn fi pe wọn lẹjọ.
Ẹsun nina asia orilẹede Russia soke lasiko iwọde ni wọn fi kan ọpọ ninu wọn.
Lara ẹsun ti wọn tun fi kan wọn ni pe wọn fẹ ditẹ gbajọba.
Miliọnu mẹwaa naira nile ẹjọ fi gba beeli ẹnikọọkan awọn afurasi naa.















