Á bẹ̀rẹ̀ ìforúkọsílẹ̀ fún àwọn àjòjì tó wà ni Kano - Ìjọba

Ijọba ipinlẹ Kano ti gbe igbimọ kan kalẹ ti yoo ri si gbigba orikọ awọn ajoji to n gbe niluu Kano, paapa awọn to n se okowo silẹ fun ijọba ipinlẹ naa.
Ijọba ni awọn gbe igbesẹ yii lati mọ iye ajoji to n gbe niluu Kano ti wọn ko ki n ṣe ọmọ ipinlẹ Kano tabi ọmọ orilẹede Naijiria, ti wọn si jẹ oniṣowo, lati le mu alekun ba eto aabo, pipa owo wọle ati lati pese iṣẹ fun araalu.
Igbimọ yii lo wa labẹ ọfisi akọwe agba si ijọba Kano, ti yoo si ma gba iroyin nipa awọn ajoji ti wọn n sisẹ ni ileeṣẹ ni Kano tabi ni okowo.
Alaga igbimọ naa, Lawan Isa Kibiya ni iṣẹ awọn ni lati ri pe igbimọ naa ran awọn ajoji lọwọ lati san owo ori gẹgẹ bii ofin se gbekalẹ.
O fikun pe igbesẹ yii yoo jẹ iwuri fun ijọba lati wa ọna lati pese aabo fun awọn ajoji.
Kọmisana fun Okowo nipinlẹ Kano, Alhaji Adamu Aliyu Kabiya, ẹni to jẹ ọmọ ẹgbẹ igbimọ ni iṣẹ igbimọ naa ko ki n se lati gba owo ori nikan sugbọn lati ri pe wọn tẹlẹ ofin ti ilu gbe kalẹ.
“Ti ẹ ba wo inu ọja, paapa awọn sọọbu, e ri pe awọn ajoji n se okowo.
“Igbesẹ yii yọ fọ ohun to jọ mọ okowo mọ nipinlẹ Kano, yoo rọnu lati ṣawari awọn ajoji ti wọn ni ero lati lu awọn eeyan ni jibiti.”
Igbimọ ni igbeṣẹ yii ko wa fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria to n gbe nipinlẹ Kano
"Ìkùnà àwọn gómìnà lẹ́kùn Àríwá ló jẹ́ kí àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn máa jẹ́jọ́ ìdìtẹ̀gbàjọba"

Oríṣun àwòrán, Sahara Reporters
Ọpọ araalu kaakiri Naijiria lo ti bẹrẹ si n bu ẹnu atẹ ijọba apapọ lẹyin ti fidio awọn ọmọde ti wọn fẹsun iditẹ mọ ijọba kan fa ori ayelujara ya.
Fidio naa ṣafihan awọn ọmọ ọhun ti iya ti jẹ wọn lẹyin ti wọn ti lo ọpọ ọsẹ ni atimọle, ilera awọn kan ninu wọn buru to bẹẹ ti awọn mii ninu wọn ko le da dide duro mọ.
Awọn ajafẹtọ ọmọniyan atawọn alẹnulọrọ lawujọ ti sọrọ lodi si ipo ti awọn ọmọ naa wa ati ohun ti ijọba n foju wọn ri, ti pupọ ninu awọn alẹnulọrọ naa si sọ pe ijọba ti tẹ ẹtọ awọn ọmọde ọhun loju mọlẹ.
Nigba to n da si ọrọ ọhun, gomina ipinlẹ Bauchi, Bala Abdulkadir Muhammad, sọ fun BBC pe oun ti bẹrẹ si n gba ipe lati ọdọ awọn eeyan kaakiri agbaye lori ọrọ naa.
Muhammad ni “Ọrọ naa jẹ ohun to buru jọjọ, ki eeyan fi ọdaju gbe awọn ọmọ kekere lọ sile ẹjọ lati jẹjọ.
“Awa gẹgẹ bii gomina, eyii n fi han wa pe a ko ṣe ojuṣe wa lati ṣetọju awọn ọmọ kekere.
Gomina ọhun sọ siwaju si pe o lodi si ofin ki wọn fi awọn ọmọde sinu ahamọ kan naa ti wọn n fi awọn agbalagba ọdaran si nitori o lewu fun wọn.
O sọ siwaju si pe “A ko mọ pe ọlọpaa mu awọn ọmọ kekere naa titi di igba ti a ri aworan wọn lori ayelujara.”
Bala Muhammad tun ke si gomina ipinlẹ Kano ti pupọ ninu awọn ọmọ ọhun ti wa lati ṣe ohun to yẹ lati daabo bo awọn afurasi naa.
Bala ni “A mọ pe ọlọpaa ti mu wọn, ṣugbọn yoo dara ti wọn ba ko wọn sinu ile awọn ọjẹ wẹwẹ ki wọn si fun wọn lounjẹ ki wọn tun ṣe itọju wọn, aworan wọn ti a ri ba wa lọkan jẹ.
“A ko faramọ ẹsun ti ijọba apapọ fi kan wọn nitori oniruru ofin lo wa ni Naijiria, eyii to daabo bo ẹtọ awọn ọmọde ti a ti tọwọ bọ gẹgẹ ni alakalẹ ajọ United nations.
O pari ọrọ rẹ pe ijọba gbọdọ fi awọn ọmọ naa silẹ ni kankan nitori ọmọdẹ ni wọn, ati pe ko tọ lati maa fi oju ọmọde wina ofin gẹgẹ bi agbalagba.
















