Ohun tó wáyé rèé bí Auxiliary ṣe padà sílé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Oyo Police
Wamuwamu awọn oṣiṣẹ alaabo pejọ si ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo lọjọ Aje, Ọjọ kerin Oṣu kọkanla ọdun 2024 nigba alaga tẹlẹ fun ẹgbẹ awakọ nipinlẹ Oyo, Mukaila Lamidi farahan ni ile ẹjọ.
Idi ti ọpọ ẹsọ alaabo fi duro wamuwamu ni ile ẹjọ lo da lori iroyin kan to gbode pe awọn ọmọlẹyin alaga tẹlẹ fun ẹgbẹ awakọ ero nipinlẹ Oyo, ni ero lati yawọ ile ẹjọ.
Kete ti awọn to n ṣọ ẹnu ọna ileẹjọ gboorun pe wahala n bọ, ni wọn sọ agadagodo si ẹnu ọna ile ẹjọ, ti wọn ko si fun ẹnikẹni ni anfani lati wọle.
Bẹẹ ba gbagbe, ninu oṣu karun un ni iroyin jade pe awọn agbofinro mu Auxillary lẹyin ọpọlọpọ ọjọ ti wọn kede sita pe wọn n wa.
Iroyin kan fidi rẹ mulẹ pe ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS lo lọ gbe alaga igbimọ alamojuto awọn gareeji ọkọ, PMS, tẹlẹri l’Oyo, Auxiliary.
Sugbọn Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo jẹ ko di mimọ pe ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Auxillary wa.
Eṣun ijinigbe, iṣekupani ati idigunjale wa lara ẹsun ti wọn fi kan Auxillary pe wọn furasi pe o lọwọ ninu wọn.
Adajọ O.A. Adetujoye wa palaṣẹ pe igbẹjọ lori ẹsun ti wọn fi Auxillary ni ki wọn gbe lọ siwaju adajọ agba nipinlẹ Oyo lati gbe lọ si ile ẹjọ mii.
Igbesẹ yii lo waye lẹyin ti wọn agbẹjọro kuna fi ẹnu ko lori bi igbẹjọ olupẹjọ na yoo se waye.
Mukaila Lamidi, ẹni to wa ni ile ẹjọ lasiko igbẹjọ naa ni wọn ka ẹsun mẹtadinlogun si lẹsẹ .
Bakan naa lo ni ti ẹsun mẹta mii niwaju ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo.
Ọkan ninu awọn ẹsun naa lo waye ni ile Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ni ọjọ Kọkandinlọgbọn Oṣu karun un ni ọdun 2020. Igbẹjọ naa lo yẹ ko waye ni ana ọjọ Aje sugbọn ko le waye.
Ẹsun keji to wa niwaju ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo lo waye niluu Igbora lasiko ipolonmgo ibo fun eto idibo ọdun 2023.















