Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
O di gbere, o darinako, o tun doju ala firi
Ọga agba fun ileesẹ ologun Naijiria, Taoreed Lagbaja, ti jade laye o
Agbẹnusọ Aarẹ Tinubu, Bayo Onanuga lo kede iku rẹ laarọ oni
Ṣaaju ni iroyin ti kọkọ gbode pe Lagbaja ti papo da
Amọ ileeṣẹ ologun ni irọ pọmbele ni iroyin naa
Ọdun merindinlọgọta ni Lagbaja lo loke eepẹ ki ọlọjọ to de
Nilẹ Amẹrika
Donald Trump ni yoo di Aarẹ Amẹrika tuntun o
Lẹyin to ti ni kọja iye ibo ti oludije gbọdọ ni lati jawe olubori ibo Aarẹ nibẹ
Ọpọ awọn olori ijọba kaakiri agbaye lo ti bẹrẹ si n ki ku oriire
Ara meeriri, awakọ dana sun oṣiṣẹ LASTMA niluu Eko, lọrọ ba di boolọ o yago fun mi
Agbegbe Mile 2 ni iṣẹlẹ naa ti waye, lẹyin ti awọn oṣiṣẹ LASTMA mu awakọ ọhun pe o ru ofin oju popo
Ka to wi, ka to fọ, awakọ naa ti gbe epo bẹntiro jade, to si ṣana si
Nibo wa ni awakọ ero naa wa bayii?