''Èèyàn mílíọ̀nù mẹ́tàlélọ́gbọ̀n lè kojú ìṣòro àìtó oúnjẹ ní Naijiria lọ́dún 2025''

Aworan ounjẹ, ẹni to n ta a ati awọn to fẹẹ ra a.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Lọwọlọwọ, nnkan le ni Naijiria pẹlu bi ọwọngogo ounjẹ ṣe gbode kan ti ko si sowo pupọ lọwọ araalu lati fi ra a.

Ṣugbọn pẹlu ẹ naa, abajade iwadii kan ti sọ pe yoo to eeyan miliọnu mẹtalelọgbọn ti yoo koju iṣoro airi ounjẹ to to jẹ ni Naijiria lọdun 2025.

Ajọ kan, Cadre Harmonisé, eyi ti ijọba apapọ lọwọ si, pẹlu awọn aladaani ati ajọ iṣọkan agbaye UN ni wọn gbe abọ iwadii naa jade.

Wọn kilọ pe ounjẹ gidi le ṣe ọwọn laaarin oṣu Kẹfa si Ikẹjọ ọdun 2025.

Awọn eeyan ti yoo fara gba a yoo le ni miliọnu meje ju bo ṣe ṣẹlẹ lọdun yii lọ.

Kí ni yóò fa àìto oúnjẹ?

Gẹgẹ bi awọn oluwadii naa ṣe wi, wọn ni ọrọ aje to ti le koko lọwọlọwọ, ai si owo, ayipada oju ọjọ ati ikọlu awọn agbesunmọmi to n ṣẹlẹ ni Ariwa-Ila-Oorun orilẹede yii ni yoo fa aito ounjẹ ni 2025.

Ajọ to n ṣe onka, National Bureau of Statistics (NBS) sọ pe iye ti wọn n ta ẹwa loṣu Kẹwaa 2024, le si i pẹlu ida 282, yatọ si iye ti wọn n ta a ni 2023.

Bakan naa, iye irẹsi le si i pẹlu ida 153%, si iye ti wọn n ta a ni 2023.

Naira to n ja walẹ ati dọla to n gunke si jẹ idi kan ti wọn sọ pe o fa eyi.

Yiyọ owo iranwọ ori epo ati arọọda ojo to ba ire oko jẹ, tun wa lara idi ti wọn ni ounjẹ yoo tun fi wọn si i.

Wọn ṣalaye pe laaarin oṣu Kẹwaa si Ikejila 2024, ko ni i din ni miliọnu mẹẹẹdọgbọn eeyan (25.1) ti yoo koju ai si ounjẹ.

Koda, lasiko ikore to yẹ ki ounjẹ pọ.

Pupọ ninu awọn eeyan ti yoo koju iṣọro naa ni iwadii sọ pe wọn n gbe ni Ariwa-Ila-Oorun Naijiria.

Lapapọ, ida ọgọrin (80%) ni ọwọngogo ounjẹ yoo fi gunke lasiko ọgbẹlẹ ni 2025 bi wọn ṣẹ sọ.

Àwọn ọmọdé, olóyún àti obìnrin tó ń fún ọmọ lọ́mú yóò fara gbá a

Aworan alubọsa, ata ati awọn ti wọn n ta a lọja

Oríṣun àwòrán, BBC/Jelilat Olawale

Abọ iwadii yii sọ pe awọn ọmọde ti wọn le ni miliọnu marun-un (5.4m), pẹlu oloyun ati iya to n fun ọmọ lọmu ti iye wọn jẹ 800,000 yoo faragba aitoounjẹ to n bọ naa.

Awọn ipinlẹ ti wọn ni yoo kan ju ni – Borno, Adamawa ati Yobe. Awọn wọnyi wa ni Ariwa -Ila-Oorun Naijiria.

Awọn yooku ni Sokoto, Katsina ati Zamfara ti wọn wa ni ẹkun-un Ariwa-Iwọ-Oorun Naijiria.

Iwadii naa sọ pe ebi buruku to n sọ ọmọ di idakuda, ’Severe Acute Malnutrition (SAM) ni yoo koju ọmọ ti ko din ni miliọnu kan ati ẹgbẹrun mẹjọ (1.8 million).

Itọju pajawiri ti yoo doola wọn ni wọn ni awọn ọmọ naa nilo lati bọ lọwọ ajaga ebi.

Gẹgẹ bi WFP ṣe wi, onka awọn eeyan ti ebi n pa lasiko yii yoo le si ni ida miliọnu kan nigba ti yoo ba fi di ọdun to n bọ.

Kí ni ọ̀nà abáyọ?

Pọnmọ, ẹran ati awọn to n ta a lọja

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Dokita Nuhu Kilishi Mohammed, Adari ẹka to n ri si anito ounjẹ, Dokita Temitope Fashedemi, Akọwe agba nileeṣẹ eto ọgbin ijọba apapọ pẹlu awọn alẹnulọrọ mi-in ṣalaye pe:

Iranwọ awọn ajọ agbaye ṣe pataki lasiko yii.

Aṣoju FAO ni Naijiria fun ajọ ECOWAS, Dominique Koffy Kouacou, sọ pe ajọ awọn n ṣiṣẹ pọ pẹlu Naijiria lati mọ kulẹkulẹ ai si ounjẹ to n waye.

Aṣoju UNICEF ni Naijiira, Cristian Munduate, tẹnu u mọ pe o ṣe pataki lati tete koju iṣoro yii.

“ Awọn ọmọde ni iṣọro yii kan ju, yoo nipa lorii ọpọlọ ati iṣesi wọn, to si le ja si iku pẹlu. Ojuṣe wa ni lati ri i pe a ko fi ẹtọ ọmọ kankan du un nipa ounjẹ to tọ si wọn.”

Cristian Munduate lo ṣalaye bẹẹ.

Bakan naa ni ajọ Iṣọkan Agbaye (UN) ke si ijọba Naijiria lati dena ìyàn kiakia.

Arọwa yii n waye lẹyin iranwọ $50m ti Banki Agabaye fi ṣọwọ si Naijiria lati koju aito ounjẹ.