Ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí tuntun ti wọ Naijiria, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣọsẹ́ – Iléeṣẹ́ ọmọ ogun

Major General Edward Buba

Oríṣun àwòrán, prnigeria

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ti kede pe ẹgbẹ agbesumọmi miran ti n ṣọṣẹ ni Naijiria.

Orukọ ẹgbẹ naa ni wọn pe ni ‘Lukarawas.’

Ileeṣẹ ologun ni, agbegbe Sokoto ati Kebbi ni wọn ti n ṣọṣẹ lọwọ yii.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ l’Abuja, agbẹnusọ ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria, Edward Buba sọ pe, awọn ọmọ ogun ti n kọju ija si awọn agbesumọmi ọhun.

O ni “Awọn ọmọ ogun ti n koju ẹgbẹ agbesumọmi tuntun ni iwọ oorun ariwa.

“Orukọ ẹgbẹ naa ni Lukawaras, wọn si ti n ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn agbesumọmi lagbegbe Sahel ti wọn wa lati Mali ati Niger Republic.”

“Wọn ti bẹrẹ si n yọ kẹlẹ wọ agbegbe ariwa Naijiria, paapaa ipinlẹ Sokoto ati Kebbi. ”

O fi kun pe ẹgbẹ naa lo ṣokunfa idaduro iṣẹ to waye laarin ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ati orilẹede Niger.

Ẹwẹ, ileeṣẹ naa ti kede pe oun n wa awọn ọmọ ẹgbẹ agbesumọmi mẹsan an kan fun ipa ti wọn ko ninu dida omi alaafia Naijiria ru.