Awuyewuye bí Malaysia ṣe fẹ́ padà sí lílo bẹntiró dípò afẹ́fẹ́ CNG fún mọ́tò

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni asiko yii ti ijọba orilẹede Naijiria n pe fun lilo afẹfẹ gaasi lati dipo epo bẹntiroolu fun awọn ọkọ, (CNG), idakeji rẹ lo fẹẹ bẹrẹ ni Malaysia bayii.
Wọn ko fẹẹ lo afẹfẹ mọ ni tiwọn, bi ko ṣe epo bẹntiroolu.
Ikede yii waye lati ọdọ ijọba Malaysia, pe nigba ti yoo ba fi di ọjọ akọkọ ninu oṣu Keje 2025, wọn yoo ti fofin de gbogbo ọkọ to n lo afẹfẹ .
Minisita fun igbokegbodo ọkọ ni Malaysia, Loke Fook, lo sọ eyi di mimọ nibi ipade awọn oniroyin kan to waye lorilẹede naa.
Ọgbẹni Fook sọ pe awọn ileeṣẹ elepo to tobi ju lọdọ awọn, yoo dẹkun ati maa ta epo NGV to ni i ṣe pẹlu CNG ati LPG.
Lori idi ti wọn fi fẹẹ gbe igbesẹ naa, o ni lati da aabo bo ẹmi awọn eeyan to n wọ ọkọ ati ẹni gbogbo ni Malaysia ni.
" O ti yẹ ki awọn ọkọ to n lo afẹfẹ yii sinmi, ọjọ ori wọn ti pe mẹẹẹdogun, ko si yẹ ki wọn maa ṣiṣẹ mọ. Fun idi eyi, a ni lati yọnda wọn." Fook lo sọ bẹẹ.
Ọdun 1995 ni wọn ronu afẹfẹ dipo epo rọbi fun mọto, wọn si bẹrẹ si i lo o ni Malaysia.
Nnkan bii 44,383 ọkọ ati awọn nnkan irinsẹ miran lo n lo afẹfẹ ni Malaysia bi minisita eto irinna wọn ṣe sọ.
O ni ijọba yoo ṣeto fawọn to n lo afẹfẹ lati pada si lilo epo bẹntiroolu.
Àríyànjiyàn bẹ̀rẹ̀ ní Naijiria lórí ìpinnu Malaysia
Bi ẹnikan ba n ti oko ẹru bọ ni ẹlomi-in yoo ṣẹṣẹ maa mura ibẹ ni awọn kan n sọ ni Naijiria lori ipinnu Malaysia yii.
Ọlọkan-o-jọkan ero lo ti n jade lori ayelujara.
paapaa bo ṣe jẹ pe asiko ti ijọba Aarẹ Tinubu n pe fun lilo afẹfẹ kan naa ni Naijiria, ni awọn kan n kọyin si i nitori aabo wọn.
Awijare ijọba Naijiria ni pe lilo afẹfẹ yii ko ba ewu de pupọ, bẹẹ lo si tun dinwo ju bẹntiroolu lọ.
Ṣugbọn bi ijọba Malaysia ṣe kọyin si ohun ti Naijiria n ki kaabọ yii ti mu ibẹru ati iyemeji wa si ọkan awọn eeyan lorilẹede Naijiria.
Ṣe awọn eeyan kan ko wulẹ fi ara mọ lilo afẹfẹ yii tẹlẹ.
Awọn kan fi ara mọ ọ ṣugbọn wọn ko ni agbara rẹ, bẹẹ ni awọn ti ko ri i ṣe pọ lọ jaara.
Ẹni kan to pe ara rẹ ni Tony Ajah, beere loju opo X rẹ pe "Ki ni awọn to n polongo CNG n ṣe?"
"King Bona ni tiẹ sọ loju opo naa pe ṣe pe ipo oku ni Naijiria ti wa lati 2015 ni abi bawo?
Malaysia fẹẹ kó ọkọ to n lo afẹfẹ kuro nilẹ nitori aabo awọn eeyan rẹ, ṣugbọn iyẹn ni Naijiria n ko mọra"
Ìjọba Naijiria fèsì
O fi kun un pe ipinnu ijọba Malaysia yii gan-an ko ti i di itẹwọgba.
O ni ida meji eeyan pere, (0.2 %) nikan lo ṣi da mọto wọn pada laaarin ọdun mẹẹẹdogun.
Onanuga sọ pe awọn orilẹede bii India, China, Iran ati Egypt ti ṣe aṣeyọri gidi lori igbesẹ naa ju Malaysia lọ.
Lati awọn ọdun 1990 ni Malaysia ti bẹrẹ eto lati maa lo afẹfẹ fun ọkọ ilẹ, nigba ti Naijiria ṣẹṣẹ bẹrẹ tiẹ ni 2024.
Loṣu Kẹjọ ọdun 2023 ni ijọba Tinubu buwọ lu ki ọkọ le lo afẹfẹ.
Wọn ṣe eyi lati din inira sọbsidi ti wọn yọ lori epo ku.
Wọn si ti jẹ ko di mimọ pe o ti le ni ẹgbẹrun ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn ti n lo afẹfẹ bayii, dipo epo.













