Charly Boy sọ̀rọ̀ lórí ìlérí tó ṣe láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ tí Trump bá wọlé ìbò ààrẹ Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Charly Boy Area Fada 1/X
Gbajugbaja akọrin takasufee, Charles Oputa, ti ọpọ mọ si Charky Boy ti sọrọ lori ileri to ṣe wi pe oun yoo fun iyawo oun ni iwe ikọsilẹ ti oludije ẹgbẹ oṣelu Democrat, Kamala Harris, ba kuna lati jawe olubori ninu ibo aarẹ orilẹede Amẹrika.
Lẹyin ti Harris fidirẹmi tan ninu eto ibo ti alatako rẹ Donald Trump ti jawe olubori lọpọ eeyan lori ayelujara ti n reti lati gbọ nipa igbesẹ Area Father1.
Amọ, ninu ọrọ rẹ, Charly Boy kọkọ ki gbogbo ololufẹ Kamala lori bi o ti fidirẹmi ninu eto idibo aarẹ Amẹrika.
O ni Kamala ṣiṣẹ takun takun ninu ipolongo ibo to sẹ fun ọgọrun ọjọ, ṣugbọn pabo naa ni gbogbo akitiyan rẹ yii pada jasi.
Charly Boy ni o ṣeni laanu wi pe awọn eeyan ti ko dantọ to lo n jẹ olori kaakiri gbogbo agbaye.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Ninu ọrọ mii ti Area Fada1 tun fi lede loju opo ayelujara rẹ ni o ti sọ pe awọn eeyan o mọ pe iyatọ laarin ọrọ ti eeyan ba sọ lasiko ipolongo ibo yatọ si eyi ti eeyan ba sọ nigba ti kii ba ṣe akoko ibo.
‘’Ṣe Tinubu ti ṣe gbogbo ohun to ṣeleri lati ṣe ni Naijiria ni?
Loootọ ni mo ni igbagbọ ati igboya ninu Kamala Harris.
Ọrọ dantọ lẹnu Kamala, o mọ bi eeyan ṣe n bawọn eeyan sọrọ.
Ni ṣe lo maa n mu mi ranti ẹgbọn mi obinrin to ti ku.
Amọ, orilẹede Amẹrika ti jẹwọ ara wọn fun Kamala bayii.
Fun ẹyin ti ẹn duro de mi lati kọ iyawo mi silẹ, ẹ o duro pẹ o,’’ Charly Boy ṣalaye.
Agbaọjẹ naa fikun ọrọ rẹ wi pe oun sọ nipa Peter Obi naa wi pe ti ko ba jawe olubori ninu ibo aarẹ Naijiria pe oun yoo fi ilu silẹ lọ orilẹede Ghana.
Charly Boy ni ‘’emi a wa fi Naijiria silẹ tori ẹnikan fi owo ra INEC ti o si mu un jẹ?
Irọ nla ni o, ibi ni gbogbo wa maa tẹẹ pa si,’’ Charly Boy ṣalaye.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2















