Ṣé lóòótọ́ ni Trump yóò lé àwọn àlejò kúrò ní Amẹ́ríkà?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, By Bernd Debusmann Jr, Mike Wendling & Valentina Oropeza
- Role, BBC
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Láti ìgbà tí wọ́n ti kéde Donalod Trump bíi ẹni tó jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò ilẹ̀ Amẹ́ríkà ni àwọn tó jẹ́ àlejò ní orílẹ̀ èdè náà ti wà nínú inú fu àyà fu.
Nora, ẹni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta ni ọkàn òun kò balẹ̀ mọ́ láti alẹ́ ọjọ́ ìbò tí àwọn ti mọ̀ pé Trump ló wọlé ìbò.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ọdún mẹ́rìnlélógún sẹ́yìn ló ti ń gbé ilẹ̀ Amẹ́ríkà, táwọn ọmọ rẹ̀ méjéèjì sì jẹ́ ọmọ Amẹ́ríkà, òun fúnra rẹ̀ kò ní ìwé ìgbélùú.
Láti Nicaragua ló ti kó lọ sí Amẹ́ríkà lásìkò tí ìjì líle kan wáyé ní orílẹ̀ èdè wọn nígbà náà.
Ó sọ fún BBC pé òun kò rí oorun sùn láti ìgbà ìbò náà àti pé iní ìbẹ̀rùbojo ni òun wà.
Nora ń bẹ̀rù pé Trump yóò mú ìlérí tó ṣe lásìkò ìpolongo ìbò rẹ̀ ṣẹ pé gbogbo àwọn ará ìlú tí kò ní ìwé àṣẹ ìgbélùú ni òun máa lé kúrò ní Amẹ́ríkà.
Níbi ètò kan ni Trump ti sọ pé àwọn máa lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn kúrò ní Amẹ́ríkà bí òun bá wọlé ìbò gẹ́gẹ́ bí ààrẹ.

Oríṣun àwòrán, Courtesy of Christell and Leah
Ẹni tó jẹ́ igbákejì Trump, JD Vance náà kín ọ̀rọ̀ Trump lẹ́yìn nígbà tó ń bá iléeṣẹ́ ìròyìn ABC News sọ̀rọ̀ pé mílíọ̀nù kan èèyàn ni àwọn máa kọ́kọ́ lé dànù.
Àmọ́ àwọn onímọ̀ wòye pé irú ìgbésẹ̀ yìí le ṣòro díẹ̀ nítorí ìpèníjà òfin àti ètò ìrìnnà.
Èèyàn mélòó ló ń gbé Amẹ́ríkà láì ní ìwé ìgbélùú?
Àkọ́ọ́lẹ̀ iléeṣẹ́ Department of Homeland Security and Pew Research lọ́dún 2022 ní èèyàn mílíọ̀nù mọ́kànlá ló ń gbé orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà láì ní ìwé ìgbélùú.
Èyí ló jẹ́ ìdá 3.3% àpapọ̀ iye èèyàn tó ń gbé Amẹ́ríkà.
Àkọ́ọ́lẹ̀ náà fi kun pé àwọn èèyàn tí Amẹ́ríkà bojú àánú wò láti Cuba Venezuela, Haiti àti Nicaragua ni ó ṣeéṣe kí wọ́n má sìí ní àkọ́ọ́lẹ̀ náà.
Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé Amẹ́ríkà láì ní ìwé ìgbélùú ni wọ́n ti ń gbé Amẹ́ríkà fún ọdún pípẹ́, ọ̀pọ̀ wọn ló ti lé ni ọdún mẹ́wàá ti wọ́n ti ń gbé níbẹ̀.
Ọ̀pọ̀ wọn ló jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Mexico, Guatemala, El Salvador àti Honduras.
Ìpínlẹ̀ mẹ́fà ni wọ́n pọ̀ sí jùlọ ní Amẹ́ríkà: California, Texas, Florida, New York, New Jersey àti Illinois.
Ìpèníjà òfin
Òfin Amẹ́ríkà fàyè gba àwọn èèyàn tí kò ní ìwé ìgbélùú láti lo gbogbo ìlànà òfin tó yẹ pé kí wọ́n fi má lé àwọn kúrò nílùú.
Kí iléeṣẹ́ tó ń rí sí ìwọlé wọ̀de tó le lé àwọn èèyàn kúrò nílùú, àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò abẹ́lé ní ìpínlẹ̀ náà nílò láti pèsè ìrànwọ́ fún wọn.
Ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ òfin Amẹ́ríkà ni kò fàyè gba àwọn ẹ̀ṣọ́ Immigration àti ọlọ́pàá láti ní àjọṣepọ̀ tó dán mọ́rán.
Onímọ̀ nípa ètò ìwọlé wọ̀de ní Amẹ́ríkà kan, Kathleen Bus-Joseph wòye pé àjọṣepọ̀ tó lágbára gbọ́dọ̀ wáyé láàárín iléeṣẹ́ ọlọ́pàá àti Immigration tí orílẹ̀ èdè náà bá fẹ́ lé ọ̀pọ̀ èèyàn kúrò.
Bush-Joseph ní ó ṣeéṣe kí ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ ọlọ́pàá má ṣe àtìlẹyìn fún èrò Trump nítorí ìkéde kan táwọn olórí agbègbè kan bíi Florida Broward àti Palm Beach ti ṣe pé àwọn kò ní rán igbákejì àwọn láti ṣe ìrànwọ́ fún èròńgbà láti lé ọ̀pọ̀ èèyàn kúrò.
Èrò láti lé àwọn ọ̀pọ̀ èèyàn kúrò ni ó ṣeéṣe kí àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn àti iléeṣẹ́ Immigration takò.
Àmọ́ ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Amẹ́ríkà lọ́dún 2022 gbé òfin kan kalẹ̀ pé ètò lílé àwọn èèyàn kúrò ní Amẹ́ríkà le máa lọ bí ètò ìgbẹ́jọ́ bá ṣe ń wáyé.
Ìpèníjà ìrìnnà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lábẹ́ ìṣèjọba Biden, ẹnu ibodè Amẹ́ríkà ni wọ́n fojúsùn láti fi máa dá àwọn èèyàn tí kò láṣẹ láti wọ orílẹ̀ èdè náà padà, tó sì jẹ́ pé iye èèyàn tí wọ́n lé kúrò nínú Amẹ́ríkà gangan kò ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún lọ.
Onímọ̀ nípa ètò ìwọlé wọ̀de kan, Aaron Reichlin Melnick sọ pé láti mú àlékún bá iye náà di mílíọ̀nù kan láàárín ọdún kan yóò gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó.
Àwọn onímọ̀ ní bí àwọn òṣìṣẹ́ Immigration kò ju 20,000 lọ, ó máa ṣòro fún iléeṣẹ́ náà láti lè rí iṣẹ́ ṣe bí Trump ṣe fẹ́.
Reichlin Melnick ní ìgbésẹ̀ lílé àwọn èèyàn kúrò ní ìlú jẹ́ èyí tó gùn gan, tó sì gba kí wọ́n kọ́kọ́ ṣàwárí àwọn èèyàn ọ̀hún, kó tó di pé wọ́n fi póró òfin gbé wọn.
Lẹ́yìn náà ni wọ́n máa fi àwọn èèyàn náà sí àhámọ́ kí adájọ́ tó pàṣẹ pé kí wọ́n kúrò ní orílẹ̀ èdè náà, tí èyí sì lè wáyé fún odidi ọdún kan.
Bákan náà ni wọ́n nílò àtìlẹyìn orílẹ̀ èdè tí wọ́n fẹ́ dá àwọn èèyàn náà padà sí lásìkò tí gbogbo ìgbésẹ̀ náà bá fi ń lọ lọ́wọ́.
Owó tí yóò bá ètò náà lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn onímọ̀ sọ pé líl’[e àwọn èèyàn kúrò ní orílẹ̀ èdè nílò ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó, tó sì lè wọ ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ bílíọ̀nù dọ́là.
Ìsúná iléeṣẹ́ Immigration láti fi lé àwọn èèyàn kúrò ní Amẹ́ríkà lọ́dún 2023 jẹ́ $420m. Èèyàn 140,000 ni wọ́n rí lé kúrò ní Amẹ́ríkà lọ́dún náà.
Reichlin Melnick ní kíkọ́ ibùdó tí wọ́n máa kọ́kọ́ kó wọn sí àti owó ọkọ̀ òfurufú tí wọ́n fi máa gbé wọn jẹ́ èyí tó máa gba owó gọbọi.
Ṣé lílé àwọn èèyàn lọ́pọ̀ yanturu ní Amẹ́ríkà ti wáye rí?
Lásìkò sáà ọdún mẹ́ẹ́rin àkọ́kọ́ tí Trump ṣe ní ọdún 2016 sí 2020, èèyàn mílíọ̀nù kan àbọ̀ ni wọ́n lé kúrò ní Amẹ́ríkà.
Ààrẹ Biden nínú ìgbésẹ̀ tirẹ̀ náà ti fẹ́ ẹ̀ bá iye yìí.
Nígbà tí Obama fi ṣe ààrẹ Amẹ́ríkà lọ́dún mẹ́jọ, èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́ta ni wọ́n lé kúrò ní Amẹ́ríkà.
Àmọ́ líle èèyàn kúrò ní orílẹ̀ èdè tó pọ̀ jùlọ láàárín ọdún kan ni èyí tó wáyé lọ́dún 1954 n’[ibi ti wọ́n ti lé èèyàn mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún. Àwọn èèyàn Mexico ni ó fara kásá rẹ̀ jùlọ nígbà náà.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ náà nítorí àwọn èèyàn tó ní ìwé ìgbélùú wà lára àwọn tí wọ́n lé.
Ìpinnu tó le
Fún Nora, pípadà sí Nicaragua jẹ́ ohun ìbẹ̀rù fún-un.
Ó ní láti odún mẹ́rìnlélógún ti òun ti ń gbé ní US ni òun ti ń ṣiṣẹ́, tí òun sì ń san owó orí bó ṣe yẹ.
“Ó ṣòro fún mi láti ronú pé kí n padà sí Nicaragua”
Àwọn ọmọ rẹ̀, Leah àti Christell, tí wọ́n dìbò fún ìgbà àkọ́kọ́ ní US ní tó bá kí àwọn tẹ̀lé ìyá àwọn, àwọn máa tẹ̀le.
Leah ní gbogbo nǹkan tó bá gbà ni òun fi máa ṣe àtìlẹyìn fún ìyá òun.











