Wo iye owó oṣù tuntun tí àwọn gómìnà Naijiria fẹ́ẹ́ san fún òṣìṣẹ́

Oríṣun àwòrán, Facebook/Gov Sanwo-Olu, Seyi Makinde ati Dapo Abiodun
Bi ijọba Aarẹ Bola Tinubu ṣe kede afikun owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ loṣu keje ọdun 2024 yii, lati ẹgbẹrun lọna ọgbọn (30,000) si ẹgbẹrun lọna aadọrin (70,000), awọn ipinlẹ kan ni awọn yoo san ju bẹẹ lọ.
Bakan naa ni awọn ipinlẹ kan si wa ti wọn ko ti i maa sanwo oṣu tuntun naa rara.
Èyi ni àwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n ní àwọn yóò san ju 70,000 lọ.
- Eko: Afikun ẹgbẹrun mẹẹẹdogun naira ni ijọba fi le 70,000, eyi to tumọ si pe N85,000 ni ijọba Gomina Babajide Sanwo-Olu kede pe oun yoo maa san gẹgẹ bii owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ. Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹwaa ọdun 2024 ni Sanwo-Olu kede eyi. O ni nnkan wọn pupọ niluu Eko, igbeaye ibẹ gara ju ti ibomi-in lọ. Gomina Sanwo-Olu waa sọ pe afojusun oun ni lati sọ owo naa di ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira, (100,000) nigba ti yoo ba fi di oṣu kin-in-ni ọdun 2025.
- Oyo: Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti buwọlu N80,000 gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ nipinlẹ naa. Kọmiṣọna eto iroyin, Ọmọba Dotun Oyelade lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita. Kọmiṣọna eto iroyin ṣalaye ninu atẹjade naa wi pe gomina ipinlẹ Oyo fi ontẹ lu owo oṣu tuntun naa lẹyin ti igbimọ kan ti ijọba gbe dide lori ọrọ owo naa jabọ iṣẹ ti wọn ṣe fun ijọba. Ọmọba Oyelade ni awọn oṣiṣẹ yoo bẹrẹ si ni gbowo oṣu tuntun naa lẹyin ti igbimọ to n ri si ọrọ owo oṣu naa ba ti pari iṣẹ atunṣe ti wọn n ṣe lori owo oṣu tuntun naa tan. Awọn abẹnugan ninu ẹgbẹ oṣiṣẹ atawọn aṣoju ijọba lo wa ninu igbimọ ọhun.
- Ogun: Ẹgbẹrun mẹtadinlọgọrin naira (77,000) ni gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapo Abiodun loun yoo maa san gẹgẹ bii owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ. Gomina Abiodun kede bẹẹ lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024, ninu atẹjade kan ti Akọwe ijọba rẹ, Tokunbo Talabi, fi sita.
- Rivers: Gomina Siminalayi Fubara ti ipinlẹ Rivers, naa kede pe oun yoo maa san ẹgbẹrun marundinlaadọrun-un (85,000) gẹgẹ bii owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ fun awọn oṣiṣẹ ijọba. Ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹwaa ọdun 2024 ni Fubara kede bẹẹ.
- Ondo:73,000, iyẹn ẹgbẹrun mẹtalelaadọrin naira ni Gomina Lucky Aiyedatiwa, ti ipinlẹ Ondo, kede pe oun yoo maa san fun oṣiṣẹ ijọba to ba gbowo kere ju. Nibi ipolongo ibo rẹ lati di gomina afiboyan l’Ondo ni Aiyedatiewa ti ṣe ileri naa lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024.
- Gombe: Owo to le ṣenji diẹ ni ẹgbẹrun mọkanlelaadọrin; N71,451.15, ni ijọba ipinlẹ Gombe ati awọn ajọ oṣiṣẹ ibẹ fẹnuko si, lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa, 2024.
- Kogi: Ẹgbẹrun mejilelaadọrin ataabọ (72,500) ni gomina ipinlẹ Kogi, Usman Ododo, buwọ lu lati san gẹgẹ bii owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ. Bakan naa lo si ni ijọba ko ni i yọ owo ori lori owo naa fun ọdun kan gbako.
Àwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti gbà láti san 70,000 rèé
*Anambra: Bẹrẹ lati ipari oṣu Kẹwaa yii, Gomnina ipinlẹ Anambra, Chukwuma Soludo, ni oun yoo maa san ẹgbẹrun lọna aadọrin tijọba apapọ buwọ lu.
* Adamawa: Lati oṣu kẹjọ 2024 ni Gomina Ahmadu Fintiri, ti Adamawa ni oun yoo ti bẹrẹ si i san 70,000 fun awọn oṣiṣẹ ijọba.
*Ebonyi:Gomina Francis Nwifuru, kede pe oun yoo san 70,000, bẹrẹ lati oṣu kẹsan-an ọdun 2024.
Katsina: Gomina Dikko Radda, ti ipinlẹ Katsina naa ni oun yoo san 70,000.
Oyo: Ijọba Gomina Seyi Makinde naa ṣalaye pe oun yoo san ẹgbẹrun lọna aadọrin naira, bi gbogbo ohun to rọ mọ atunṣe owo oṣu sisan ba ti yanju.
Osun: Gomina Ademola Adeleke ti ipinlẹ Osun naa loun ti ṣetan lati san owo oṣu tuntun, N70,000.
*Borno: Ipari oṣu Kẹwaa ọdun 2024 yii ni Gomina Babagana Zulum, loun yoo bẹrẹ si i san 70,000 fun awọn oṣiṣẹ ọba ipinlẹ Borno.
*Benue: Gomina Hyacinth Alia, ti ipinlẹ Benue naa ni oun ti ṣetan lati san 70,000.
Ẹwẹ, awọn ipinlẹ bii Bayelsa, Jigawa, Akwa Ibom ati Zamfara ko ti i sọ boya awọn yoo bẹrẹ si i sanwo oṣu tuntun naa.















