Adájọ́ fagilé èròńgbà Biden láti sọ àwọn àjòjì tó fẹ́ ọmọ Amerika di ọmọ onílùú

Oríṣun àwòrán, AFP
Adajọ ile ẹjọ apapọ kan lorilẹede America, Campbell Barker, ti fagile erongba Aarẹ Joe Biden lati sọ awọn ajoji to fẹ ọmọ Amerika di ọmọ oniluu.
Ero ọkan Biden ni lati ran awọn ajoji ti iwe wọn ko pe naa lọwọ, ki wọn le di ọmọ Amerika nigba ti ẹni ti wọn fẹ ti jẹ ọmọ oniluu.
Ṣugbọn Adajọ Campbell Barker, ọkan lara awọn ti Donald Trump, yan, ti paṣẹ pe iṣakoso Biden ko lẹtọọ labẹ ofin lati ṣe eto naa.
Ọmọ ẹgbẹ Republican mẹrindinlogun lo pe ẹjọ yii, ninu eyi ti wọn ti ni ki Biden ma yi ofin to de awọn ajoji pada, nitori ati sọ wọn di onile.
Adajọ Barker fofin de igbesẹ naa fun ẹgbẹrun eeyan to n gbe America lai ni iwe to pe, eyi si ti bẹrẹ lati oṣu kẹjọ.
Ìjọba America sọ̀rọ̀
Ijọba ilẹ America to ṣi wa labẹ idari Joe Biden, sọ pe awọn lodi si idajọ naa.
“ Awọn ọmọ ẹgbẹ Republican ni idajọ yii gbe.
“ Awọn ni wọn fẹẹ fipa le awọn ọmọ America ati idile wọn jade kuro niluu yii. Awọn eeyan to ti lo ju ọdun mẹwaa lọ l’America, wọn waa fẹẹ yà wọn ya idile wọn, tabi ki wọn fi wọn sinu ibẹru idapada si orilẹede wọn"
Agbẹnusọ ile ijọba America, Angelo Fernández Hernández, lo sọ bẹẹ.
"Iṣakoso tiwa gbagbọ ninu ki mọlẹbi wa papọ" Angelo Fernández Hernández lo fi kun ọrọ rẹ bẹẹ.
Bakan naa ni ẹka Homeland Security, sọ pe ijakulẹ gbaa ni idajọ Adajọ yii.
"Ki idile wa papọ ni a wa fẹ, ki wọn duro ṣinṣin labẹ ofin. A si n tẹle ofin ilẹ America."
Ṣugbọn ẹgbẹ kan to n ṣe atilẹyin fun Donald Trump, America First Legal, fi idunnu wọn han si idajọ yii, wọn si ṣe ajọyọ rẹ.
Gene Hamilton, adari ẹgbẹ naa sọ pe, “Lati ibẹrẹ pẹpẹ ni ijọba Biden ati Harris ti fẹẹ yẹyẹ ofin to de awọn ajoji nilẹẹ wa, ti wọn ti fẹẹ pa ẹnu ibode wa rẹ.
"Ẹgbẹ Republican ti ṣẹgun wọn lori igbesẹ ti ko ba ofin mu ti wọn fẹẹ gbe lati sọ ajoji di ọmọ onilẹ."
Eto to gba awọn ajoji to fẹ ọmọ America laaye, lati duro niluu naa ni Biden kede rẹ loṣu kẹjọ, paapaa fun awọn ti wọn ti lo ju ọdun mẹwaa lọ l’America.
O fẹẹ ki wọn le gbA iwe igbeluu, ki wọn si maa ṣe aye wọn lọ nibẹ.
Ijọba Biden sọ pe yoo to idaji miliọnu eeyan to le jẹ anfaani yii.
Ṣaa, o ṣee ṣe ki ijọba Biden pe ẹjọ Ko-tẹ -mi-lọrun lori idajọ Adajọ Barker, ṣugbọn ẹjọ naa le ma ni ẹsẹ nilẹ, nitori Donald Trump lo n bọ waa ṣe’jọba.
Trump ti kede rẹ saaju, pe oun yoo le awọn ajoji ti ko laṣẹ lati gbe l’America.
O ni ko ṣẹlẹ ri ni lile toun yoo le wọn yoo jẹ ninu itan.














