'Mi ò mọ̀ pe òkú ìyá mi ni mò ń gbìyànjú láti dóòlà ẹ̀mí rẹ̀'
Abdulaziz Al-Bordini darapọ̀ mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ní ìlú Gaza láti lè máa raqn àwọn èèyàn lọ́wọ́ lásìkò ogun tó ń wáyé láàárín Gaza àti Israel.
Lásìkò tó ń ṣiṣẹ́ náà ni wọ́n pè é láti lọ mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì kan níbi tí àdó olóró tí Israel jù ti ṣọṣẹ́.
Nígbà tó ń gbìyànjú láti ran àwọn èèyàn náà lọ́wọ́ ni ó rí ìyá rẹ̀ tó ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìkọlù ọ̀hún.
Abdulaziz ní òun kò ti ẹ̀ tètè ìyá òun mọ̀ nítorí òun kò lérò pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà le kan òun rárá.
Ó ní kàyéfì ńlá ló jẹ́ fún òun nígbà tí òun rí òkú ìyá òun lára àwọn èèyàn tí àdó olóró pa lásìkò nínú ọkọ̀ kan ní ààrin gbùngbùn Gaza.
Ó ṣàlàyé pé òun gbé òkú èèyàn náà lọ sí ilé ìgbókùúsí tí òun sì ń dúró àwọn dókítà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹni náà ti kú ní tòótọ́, tí òun kò mọ̀ pé ìyá òun ni.
“Lẹ́yìn tí mo gbé òkú náà sórí àga gbọ̀ọ̀rọ̀, mo ṣí ojú rẹ̀ àmọ́ mi ò tètè da mọ̀ pé ìyá mi ni.
“Bóyá nítorí pé ó bá mi lójijì ni mi ò ṣe da mọ̀, kò yé mi rárá.”
Nígbà tí ó fẹ́ lọ fi orúkọ òkú náà sílẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọn kò dá mọ̀ ni iyè rẹ̀ tó sọ wí péd ìyá òun ni òkú tó wà nílẹ̀ tí ọkàn rẹ̀ sì gbọgbẹ́.
Bí Abdulaziz ṣe pàdánù ìyá rẹ̀ nìyí, tó sì di ọmọ òrukàn nítorí bàbá rẹ̀ ti ṣáájú jáde láyé.






