Ẹ yé lo fọ́tò ìhòhò àwọn ọmọdé pawó lórí ayélujára, àwọn òbí ọmọkùnrin tó gbẹ̀mí ara rẹ́ kìlọ̀

- Author, Angus Crawford and Tony Smith
- Role, BBC News Investigations
- Author, Chigozie Igbo and Monday Idara
- Role, BBC News Pidgin
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Awọn obi ọdọmọkunrin Ilẹ Gẹẹsi kan, Murray Dowey, to gbẹmi ara lẹyin tawọn ọdaran kan ni Naijiria dunkoko mọ ọn pe awọn yoo gbe fọto nnkan ọmọkunrin rẹ sita ti rawọ ẹbẹ sawọn to ṣiṣẹ laabi ọhun wi pe ki wọn jawọ ninu iwa yii.
Ọmọ ọdun mẹrindinlogun ni Dowey nigba to gbẹmi ara rẹ lọdun to kọja.
Baba ati iya Murray di ẹbi iku rẹ ru awọn ileeṣẹ itakun ayelujara wi pẹ ẹjẹ wa lọwọ wọn tori wọn o maa daabo bo awọn ọdọmọde to lori ayelujara.
Ohun tawọn eeyan naa maa n ṣe ni pe wọn maa n fi fọto tabi fidio ihoho ranṣe sawọn eeyan ti wọn yoo si sọ pe ki iru eeyan bẹẹ naa fi ti wọn naa ranṣẹ.
Lẹyin naa ni wọn maa dunkoko mọ iru eeyan bẹẹ lati ṣe ohun ti wọn ba beere fun, bi bẹẹ kọ awọn yoo pin fọto tabi fidio ihoho rẹ to fi ranṣẹ si wọn pẹlu ẹbi atawọn ọrẹ rẹ.
Igbagbọ wa pe ohun to ṣẹlẹ si Murray niyi to fi gbẹmi ara rẹ.

Arakunrin Mark ati arabinrin Ros Dowey ti wa ṣe fidio kan lori iwa ọdaran yii.
Wọn sọ ninu fidio naa pe ‘’ẹ jawọ ninu ipalara ti ẹ n ṣe fawọn ọdọ.
Ẹyin ni ẹ ṣeku pa Murray.
Bawo lo ṣe maa ri lara ẹyin naa to ba jẹ pe ọmọ, ọrẹ tabi aburo yin ni iru nnkan bayii ṣẹlẹ si?
Iwa to buru jai ni ẹ n hu sawọn ọmọde, ipalara lẹ n ṣe fun wọn.’’
‘’Ẹ n dunkoko mawọn eeyan tori owo, ko si ibi ti iru iwa yii ti jẹ itẹwọgba.’’
Didunkoko mọ ni nipa lilo fọto tabi fidio ihoho awọn eeyan wọ pọ ni Naijiria laarin ọpọ ọdọkunrin ti wọn n pe orukọ wọn ni ‘’yahoo boys.’’
Ilana lori ati bi eeyan sẹ le maa huwa ọdaran yii wa lori itakun ayelujara, gẹgẹ bi iṣẹ iwadii BBC ti ṣafihan rẹ ni ibẹrẹ ọdun yii.

BBC fi ọpọlọpọ oṣu ba ọkunrin kan to n hu iru iwa bayii ni Naijiria sọrọ lati ṣalaye bi wọn ṣe maa n ṣe e.
Ọkunrin naa to ko fẹ ki a darukọ rẹ sọ fawọn oṣiṣẹ BBC niluu Eko wi pe oun naa mọ wi pe ohun ti ko dara loun n ṣe, amọ, ọna atijẹ naa gbogbo ẹ.
Ọkunrin naa ni lilo fọto ihoho awọn eeyan lati gbowo dabi okowo lorilẹede Naijiria bayii.
‘’Iru ẹja ti a ba fẹ mu lo maa sọ ọna ti a o gbe gba. Ti a ba ju iwọ sinu okun, o le mu ẹja kekere ati ẹja nla,’’ ọkunrin naa ṣalaye.
Amọ, Ros ati Mark fi ọgbọn ba a sọrọ ti wọn si ka ohun rẹ ati tiwọn silẹ.
Iyalẹnu lo jẹ fun un nigba ti o mọ nipa ohun ti Ros ati Mark ṣe.
O ni diẹ loku koun bu sẹkun lẹyin toun mọ.

Oríṣun àwòrán, Dowey family
Awọn obi Murray ko di gbogbo ẹbi iku ọmọ wọn ru awọn ọdaran to dunkoko mọ ọmọkunrin wọn.
Wọn ni awọn ileeṣẹ imọ ẹrọ naa lẹbi ti wọn ninu iku Murray.
Awọn to n fọto ihoho eeyan maa n lọ sori ayelujara lati wa ẹni ti wọn le dunkoko mọ.
Ros sọ fun BBC pe ẹjọ wa lọwọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ itakun ori ayelujara tori wọn ni imọ ẹrọ lati dẹkun iwa ọdaran yii.
Mark ati Ros ko lanfaani lati ran Murray lọwọ
Iwadii ajọ to n gbogun ti iwa ọdaran ni Ilẹ Gẹẹsi fihan pe gbogbo eeyan lawọn ọdaran yii maa n dunkoko mọ lori itakun ayelujara, amọ, awọn ọdọkunrin ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹrinla si mejidinlogun lo maa n saba fara kaasa julọ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni iroyin ko maa gbe awọn iṣẹlẹ yii daadaa tori ẹru maa n ba awọn to ṣẹlẹ si lati sọrọ sita.
Mark sọ fun BBC pe oun ati iyawo oun ko mọ pe iru nnkan bayii n ṣẹlẹ si ọmọ awọn, o ni awọn kan ṣadeedee ri oku rẹ ninu ile ni laarọ.
Iya rẹ Ros ni oun ati baba rẹ ko ni anfaani rara lati ṣe iranwọ kankan fun ọmọkunrin awọn.

Ẹbi Dowey yoo kopa ninu eto ti ifilọlẹ rẹ yoo waye ni Edinburgh laipẹ, eyi ti wọn fi kilọ fawọn ọdọ nipa awọn ọdaran to maa n lo fọto ihoho eeyan pawo.
Wọn yoo tun lo eto naa lati gbawọn ọdọ ni imọran ohun ti wọn le ṣe tabi ibi ti wọn le lọ ti iru nkan bayii ba ṣẹlẹ si wọn.
Awọn tọkọ taya naa rọ awọn ti iru nnkan ba ṣẹlẹ sai pe ko si iru nnkan to le ṣẹlẹ si eeyan to le mu gba ẹmi ara rẹ..
Wọn ni awọn ko fẹ ki iru nnkan to ṣẹlẹ si Murray tun maa ṣẹlẹ sawọn ọdọmọde mii.















