PDP kọ èsì ìbò gómìnà tí INEC kéde nípìnlẹ̀ Ondo, wọ́n ní ìdìbò kò wáyé l'áwọn ibì kan

Ẹgbẹ oṣelu PDP ti kọ esi ibo gomina ipinlẹ Ondo lẹyin ti ajọ eleto idibo INEC kede Lucky Aiyedatiwa, oludije ẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu eto idibo naa.
Ọjọ Abamẹta, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla, ni idibo naa waye.
PDP ni oun yoo lọ sile ẹjọ lori esi idibo ọhun ninu eyi ti oludije wọn Agboola Ajayi ti fidirẹmi.
Ọrọ yii jẹyọ lẹyin ti aṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP ni ijọba ibilẹ Idanre sọ pe eto idibo ko waye lagbegbe Ofosun Oniseri.

Oríṣun àwòrán, Agboola Ajayi/X
Bakan naa ni o tun sọ pe wọn le awọn ọmọ ẹgbẹ PDP kuro lagbegbe Alade ti wọn si tun ji ibo wọn ko lọ.
Adele akọwe iroyin fun PDP, Alhaji Abdullahi Ibrahim, ni eto idibo gomina ipinlẹ Ondo tako ilana ati alakalẹ ijọba awaarawa.
Alhaji Ibrahim ni idi eyi gan an ni PDP yoo fi gbe igbesẹ to kan bayii.
‘’A n lọ ile ẹjọ lori esi ibo yii, a kọ ikede ajọ INEC to ni Aiyedatiwa lo wọle eto idibo gomina ipinlẹ Ondo.’’
PDP ti sọ ṣaaju loju opo X rẹ pe awọn n ṣe agbeyẹwo eto idibo naa ati esi ti INEC kede kawọn to mọ igbesẹ to kan lati gbe.
PDP sọ ninu atẹjade to fi lede loju opo X rẹ pe eto idibo gomina Ondo ni ibo to mẹhẹ julọ ninu gbogbo eto idibo ti ajọ INEC ti ṣakoso rẹ.
Ẹgbẹ oṣelu PDP sọ pe APC ṣe kata-kara ibo ninu eto idibo naa pẹlu ẹsun pe APC fawọn eeyan lowo lati le dibo fun oludije wọn.
PDP ni ijọba APC lo agbara wọn lati ma jẹ ki erongba araalu ninu eto idibo naa wa si imuṣẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
APC fesi sọrọ PDP lori ibo gomina Ondo
Nigba ti o n fesi sawọn ẹsun ti PDP fi kan ẹgbẹ oṣelu APC, adari eto iroyin fun APC, Malam Bala Ibrahim, sọ pe bi Aiyedatiwa ti jawe olubori ninu ibo gomina Ondo fihan pe awọn eeyan ipinlẹ naa mọ riri iṣẹ ti ijọba to wa lode n ṣe ni.
Malam Ibrahim sọ pe ara lo n ta ẹgbẹ osẹlu PDP lo jẹ ki wọn maa sọrọ.
O ni kii ṣe tuntun ki ẹgbẹ oṣelu atalako maa sọrọ lẹyin eto idibo.
‘’Gbogbo ẹsun ti PDP ka silẹ kii ṣe ẹsun ti ẹnikan ko tii gbọ ri.’’
Lapapọ, ajọ INEC kede pe ibo 366,781 ni Aiyedatiwa ri to fi jawe olubori ninu eto idibo naa, nigba ti Agboola oludije PDP to ṣe ipo keji ninu eto idibo naa ri ibo 117,845.
Gẹgẹ bi esi ibo ti ajọ INEC kede, gbogbo ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa ni ipinlẹ Ondo ni Aiyedatiwa ti jawe olubori.















