Nọ́ọ̀sì alábẹ́rẹ́ tó ń fi èdè Yorùbá kọ́ aráàlú nípa ìlera wọn
Nọọsi alabẹrẹ to kọṣẹmọṣẹ ni Adejọkẹ Ogunbiyi ohun to sọ ọ di gbajugba lori ayelujara ni bi o ti ṣe n kọ eto ilera ati iṣegun oyinbo.
Lori ayelujara, Nọọsi Tiwantiwa ni wọn maa n pe Nọọsi Adejọkẹ loju opo ayelujara, ko si si ọrọ ilera kankan ti kii sọrọ le lori lede Yoruba.
O ni idi ti oun fi pinnu lati maa kọ awọn eeyan nipa ilera pẹlu ede Yoruba ni wi pe oun gbagbọ pe yoo tubọ mu ki ọpọ nnkan ti idape wọn lede oyinbo mu ki ọrọ ilera naa da bi idan o tubọ ye awọn eeyan sii.

Oríṣun àwòrán, Noosi tiwańtiwa/instagram
- Àìrí onímọ̀ràn gidi, fífi ojú olóore gúngi, kún ara ohun tó fa ìjákulẹ̀ mi - Olajumoke Oníbúrẹ́dì
- Ṣó o Láyà: Peller kópa nínú ìdánwò tó dá lórí àṣà àti èdè Yorùbá
- Wo iléẹ̀kọ́ tó ń pèsè ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọ aláìní, ṣùgbọ́n tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun ní àwọn kò tíi dá a mọ̀
- 'Mo kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní fásitì, àmọ́ aṣọ ìtìjú mi ti fàya bí mo ṣe n fi súùtù kiri mọ́ín-mọ́ín'
O fi kun un pe ọpọ igba lawọn eeyan maa n fẹ ki oun sọ nipa ogun ti wọn le lo fun ọrọ ilera ti oun ba ṣalaye lori ayelujara, ṣugbọn oun maa n fẹ ko ye wọn pe igbesẹ idanilẹkọ oun ko si fun mimu ki awọn eeyan dẹkun lilọ ileewosan bikoṣe lati le dari wọn si ile iwosan pẹlu idaniloju nipa ipenija ilera ti wọn ba n dojukọ.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC, o ni lilo ede yoruba lati kọ oun ti oun pẹlu fi oyinbo kọ, bi awọn eeyan kan to n gbọ ọ ṣe maa n faake kọri pe bi awọn ti ṣe maa n ṣe lati igba atẹyinwa ni ko si ohun ti oun le ṣe lati da a nu.






