Beartrice Ekweremadu, Ìyàwó igbákejì ààrẹ ilé aṣòfin Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, kúrò lẹ́wọ̀n nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, padà sí Nàìjíríà

Beartrice Ekweremadu

Oríṣun àwòrán, Andrian Dennis/Getty images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ wi pe iyawo igbakeji aarẹ ile aṣofin agba Naijiria tẹlẹ, Ike Ekweremadu, iyẹn Arabinrin Beartrice Ekweremadu ti gba itusilẹ kuro lọgba ẹwọn lorilẹede Gẹẹsi.

Ile ẹjọ kan ni ilẹ Gẹẹsi da Sẹnetọ Ekweremadu, iyawo rẹ Beartrice ati Dokita Obinna Obete lori ẹsun gbigbimọpọ lati ta kidinrin eeyan.

Ẹwọn ọdun mẹrin ati oṣu mẹfa ni wọn fun Arabinrin Beartrice Ekweremadu.

Ẹwọn ọdun mẹsan an ni wọn fun Sẹnetọ Ike Ekweremadu, ti Dokita Obeta si gba idajọ ẹwọn ọdun mẹwaa.

Idunnu ati ijo lo gbode kan ni idile wọn bayii pẹlu bi awọn ololufẹ gbajugbaja oloṣelu naa ṣe n dunnu fun itusilẹ iyawo rẹ.

Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan gbe fidio awọn iyalọja kan jade nibi ti wọn ti n ṣe ajọyọ ni ilu Enugu ẹkun ila oorun Naijiria.

"Oṣu mẹta sẹyin ni iyawo ọga ti gba itusilẹ kuro lọgba ẹwọn," gẹgẹ bi ọrọ ti ọkan lara awọn mọlẹbi rẹ ṣe sọ fun BBC.

Mọlẹbi naa ti ko fẹ ki a da orukọ oun sọ wi pe ọjọru ni arabinrin naa wọ orilẹede Naijiria.

Ko ti si ẹni tan imọlẹ si ọrọ itusilẹ rẹ nitori pe loṣu karun un ọdun 2023 ni ile ẹjọ ran ọ lọ si ẹwọn.