Ọ̀pọ̀ apànìyàn ló ń yan fanda kiri lórílẹ̀èdè yìí láì dọ́gbà ẹ̀wọ̀n - Trump ṣàlàyé Ìdí tó fi dáríjìn àwọn olùwọ́de 'Capitol Building'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹede Amẹrika ti ṣalaye idi to fi kede eto idarijin fun awọn oluwọde to ṣigun wọ ile igbimọ aṣofin apapọ orilẹede naa loṣu kinni ọdun 2021.
Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ lori idokoowo imọẹrọ igbalode AI lọjọ Iṣẹgun, awọn akọroyin bi Aarẹ Trump lere lori idi to fi fun awọn oluwọde naa ti wọn din diẹ ni ẹgbẹrun kan ati ẹẹdẹgbẹta.
Akọroyin kan beere lọwọ trump pe, "Ṣe ko jọ bi ẹni pe ẹ n sọ fun awọn eeyan pe ko buru ti wọn ba kọlu awọn agbofinro?"
Amọṣa esi tí aarẹ tuntun lorilẹede Amẹrika naa fun un ni pe awọn eeyan wọnyii "ti lo ọpọlọpọ ọdun lọgba ẹwọn" bẹẹ si ni ọpọ "awọn apaniyan ni ko tilẹ lọ si ẹwọn lorilẹede yii" fun iwa ọdaran wọn.
Bakan naa lo tun tẹsiwaju lori ọrọ rẹ nipa atilẹyin rẹ fun awọn ọlọpaa nipa titu awọn ọlọpaa meji silẹ kuro lọgba ẹwọn pẹlu lẹyin ti wọn dajọ ẹwọn fun wọn "fun lilepa ọdaran kan".
Awọn oluwọde to ṣigun wọ ile nla "Capitol building"

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Omilẹngbẹ awọn oluwọde to ṣigun wọ ile aṣofin apapọ Amẹrika, Capitol building lọdun 2021 ti dupẹ lọwọ Aarẹ Trump lẹyin to buwọlu iwe idarijin wọn ni kete to de ori oye.
Ijọba ana lorilẹede naa fi wọn jofin ti ọpọlọpọ wọn si ti di ero ẹwọn.
Awọn oluwọde naa ṣigun wọn ile aṣofin orilẹede naa to wa ni ilu Washinghton lọjọ kẹfa oṣu kinni ọdun 2021 nigba ti wọn n gbiyanju lati fi ipa mu awọn aṣofin orilẹede naa, ninu eyi ti igbakeji aarẹ nigba naa wa, lati wọgile esi idibo aarẹ orilẹede naa ti wọn ṣẹṣẹ kede eyi to fihan pe Joe Biden ti fi ẹyin trump nalẹ nigba naa.
Rachel Powell ti wọn fi ẹsun kan pe oun naa wa lara awọn to n paṣẹ fun awọn oluwọde lọjọ naa, ti oun gan pẹlu si tun fọ awọn gilasi ferese ile aṣofin naa.
"Gbese nla ni mo jẹ ẹ nitori pe oun lo tun mu ki ẹbi wa le pada pọ. Ẹ ṣeun o Aarẹ Trump."

Oríṣun àwòrán, screenshot
'Mi o kabamọ kankan nipa ipa ti mo ko ninu iwọde ikọlu Capitol Building'
Ẹlomiran lara awọn oluwọde ti wọn gba idarijin naa, Jacob Chansley ṣalaye fun BBCNewsnight pe, "n ko kabamọ ohunkohun ti mo ṣe lọjọ naa".
Chansley sọ pe wọn ti pa idalẹbi oun rẹ, nitorinaa oun n gbero lati lo ẹtọ oun lati ra ibn lẹẹkan si.
- Àǹfàní wo ni ìpadàbọ̀ Abìjà Donald Trump yóò ṣe fún gbogbo àgbáyé?
- Trump di Ààrẹ kẹtàdínláàádọ́ta ti ilẹ̀ America
- Àwọn ohun tí Donald Trump ń gbèrò láti ṣe kété tí wọ́n bá búra fún un tán gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Amẹrika lónìí
- China yẹgi fún awakọ̀ tó wa ọkọ̀ pa èèyàn 35 níbi tí wọ́n ti ń ṣe eré ìdárayá
'Itiju nla ni fun mi bi mo ba tẹwọ gba idarijin Trump'
Ki i ṣe gbogbo awọn oluwọde to kopa ninu ikọlu ile aṣofin Capitol Building lọjọ kẹfa oṣu kinni ọdun 2021 lo fara mọ igbesẹ aarẹ orilẹede naa, Donald Trump lati darijin gbogbo awọn oluwọde naa.
Ọkan lara awọn eeyan naa, ti oun pẹlu ti lọ ṣe ẹwọn fun kikopa ninu iwọde ati ikọlu naa ti faake kọri pe oun o ni tẹwọ gba idarijin naa nitori pe "iwa buruku la hu lọjọ naa".
Pam Hemphill, to jẹwọ pe oun jẹbi niwaju ile ẹjọ, ti ile ẹjọ si ran an lọ si ẹwọn ọgọta ọjọ ṣalaye fun eto BBC World Service Newsday pe ko yẹ ki idarijin kankan wa fun ẹnikẹni ninu awọn to kọlu ile aṣofin apapọ orilẹede Amẹrika lọjọ naa.
"Titẹwọ gba idarijin kankan yoo jẹ iwọsi fun awọn ọlọpaa ile aṣofin apapọ naa, eto ofin ati orilẹede wa."
"Mo jẹwọ pe mo jẹbi niwaju ile ẹjọ nitori pe mo gba pe jẹbi, bẹẹni titẹwọ gba idarijin naa yoo tun pa kun ara iroyin ayederu" to n lọ kiri lori iṣẹlẹ naa.
"Ohun ti a ṣe ko tọna rara, a tẹ oju ofin mọlẹ ni – ko yẹ ki idarijin kankan wa fun wa."
Idarijin ti aarẹ kede n fihan pe oṣelu bori iṣẹ idaabo ati ifidimulẹ ofin lawujọ - Ọga ọlọpaa ile aṣofin apapọ orilẹede Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa to n mojuto eto abo ile aṣofin apapọ orilẹede Amẹrika, Thomas Manger ti sọ pe igbesẹ Aarẹ Trump lati kede idarijin fun awọn oluwọde to kọlu ọlọpaa ti wọn si tun ṣigun kọlu ile nla Capitol Buildin ti mu ki oun maa ro wi pe aarẹ n jẹ ko di mimọ ni fun gbogbo onwoye pe " ọrọ oṣelu lo ṣe pataki ju idaabo bo ilu lọ".
Ninu atẹjade kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin CBS pe ọkan oun n gbọgbẹ fun awọn agbofinro to n daabo bo ile aṣofin naa nitori irufẹ itumọ ti igbesẹ yii yoo maa ni si wọn.
Ninu atẹjade to fi sita gbẹyin, ileeṣẹ eto idajọ ijọba Amẹrika sọ pe ẹgbẹrun kan ati ọrinlelẹẹdẹgbẹta o le mẹta, (1,583) lawọn eeyan ti wọn ti fi panpẹ ofin mu tabi ran lọ si ẹwọn laarin awọn oluwọde to kọlu ile nla 'Capitol Building'.
O le lẹgbẹta ninu wọn ti wọn fi ẹsun kikọlu ọlọpaa kan, awọn marundinlọgọsan miran si tun jẹjọ fun lilo ohun ija oloro tabi ṣiṣe ọlọpaa leṣe.
Ohun ti Aarẹ trump n wi gẹgẹ bi awijare ni pe "awọn eeyan wọnyi ti lo ọpọ ọdun lẹwọn".
Amọṣa manger n sọ pe pupọ ninu awọn agbofinro naa ni inu wọn ko dun si igbesẹ idarijin ti aarẹ fun awọn eeyan naa.
"Inu n bi wọn gidigidi, emi naa o da le da wọn lẹbi,"















