China yẹgi fún awakọ̀ tó wa ọkọ̀ pa èèyàn 35 níbi tí wọ́n ti ń ṣe eré ìdárayá

Oríṣun àwòrán, Reuters
Wọn ti yẹ igi fun arakunrin kan to pa ọpọlọpọ eeyan lẹyin to wa ọkọ rẹ kọlu awọn eeyan to n ṣe ere idaraya ni iwaju papa iṣire kan lẹkun gusu orilẹede China.
Ileeṣẹ iroyin ijọba orilẹede China gbe iroyin sita pe arakunrin naa Fan Weiqiu ẹni ọdun mejilelọgọta ṣekupa awọn eeyan ti ko din ni marundinlogoji, bẹẹni ogunlọg miran tun farapa lasiko ikọlu rẹ naa lọjọ kọkanla oṣu kọkanla ọdun 2024.
Iroyin sọ pe arakunrin naa ṣa dede wa ọkọ rẹ wọ oju opo ere idaraya kan ni ilu Zhuhai. Iṣẹlẹ yii ni ọpọ ti ṣe akawe rẹ gẹgẹbi eyi to buru julọ lori ilẹ orilẹede China laarin ọdun mẹwaa.
Ohun ti iroyin sọ pe o fa ikọlu yii nibi gbẹni Fan Weiqiu ṣe fi ẹhonu han lori aidunu rẹ lori bi ile ẹjọ ṣe pin dukia rẹ ninu ẹjọ ituka igbeyawo rẹ.
- TikTok ti ṣíwọ́ iṣẹ́ lórílẹ̀èdè America lẹ́yìn tí wọ́n fòfin dè é
- Àlàyé rèé lórí bí gbájúẹ̀ ṣe ń lu aráàlú ní jìbìtì ní UK, Amẹrika, Australia àti Canada
- Wo bí orílẹ́èdè China ṣe ń lo tẹlifísàn sátáláìtì láti fa ojú àwọn ọmọ ilẹ̀ Afirika mọ́ra
- Ipa wo ni ookòwò China ti ní lórí Áfíríkà àti ètò rẹ̀ fún adúláwọ̀ lọ́jọ́ iwájú?
Ọjọ Aje ni awọn alaṣẹ gbe igbesẹ lori idajọ iku ti ile ẹjọ da fun arakunrin naa.
Gẹgẹbi iroyin ṣe sọ, o din diẹ ni oṣu kan ti ile ẹjọ gbe idajọ kalẹ fun arakunrin naa.
Ile ẹjọ da Ọgbẹni Fan lẹbi ẹsun "dida ẹmi araalu legbodo", eyi ti ile ẹjọ naa ṣe akawe rẹ gẹgẹ bi "iwa ika to buru jai" ti wọn si ni ọna to gba "ba ni lọkan jẹ pupọpupọ"
Ikọlu ọkọ naa jẹ ọkan lara ikọlu mọkandinlogun ti wọn ṣe si awọn ajeji jakejado orilẹede China lọdun 2024, meji ninu wọn lo si waye ninu ọsẹ ti ikọlu to waye ni Zhuhai ṣẹlẹ.















