Wo àwọn Musulumi tí kìí gbààwẹ̀ tàbí gbàdúrà ojojúmọ́

Diourbel, Senegal, April 2024

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Rukia Bulle
    • Role, BBC News Komla Dumor Award winner
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Bi ilẹ ṣe n ṣu ni Mbacke Kadior, abule kan ni aringbungbun Senegal, awọn Musulumi bẹrẹ adura irọlẹ.

Niwaju Mọṣalaṣi ti adura naa ti n lọ lawọn kan korajọ si ti wọn si n kọ orin.

Awọn eeyan naa ti wọn mọ si awọn alatilẹyin Baye Fall n jo ti irun dada ori wọn si n fi si ọtun ati osi.

Wọn le kọ orin naa fun nnkan bii wakati meji, ti ẹmi a si maa gbe wọn lọpọ igba.

Musulumi lawọn eeyan naa, amọ wọn ki ṣe bii awọn Musulumi to ku.

Ẹya Musulumi tiwọn kere pupọ, koda ida diẹ ni wọn ko lara miliọnu mẹtadinlogun eeyan orilẹede Senegal, to jẹ ọkan lara awọn ilẹ ti Musulumi pọ si julọ nilẹ adulawọ.

Irisi wọn mu ki wọn yatọ, bẹẹ ni ọpọ gbagbọ pe iṣe wọn yatọ si ti awọn Musulumi ẹgbẹ wọn.

Àkọlé fídíò, Fidio: Awoon Musulumi naa re bi soe n kọ orin

Fun awọn Musulumi Baye Fall yii, jijẹ Musulumi ko ni nnkan lati ṣe pẹlu irun igba marun run lojumọ tabi lati maa gbaawe ninu oṣu Ramadan.

Fun wọn, iwa rere lawujọ atawọn nnkan ti eeyan n ṣe fun ẹlomiran ni ẹsin.

Ọpọ awọn Musulumi ẹgbẹ wọn ni ko gba tiwọn, awọn kan tilẹ gbagbọ pe awọn eeyan naa maa n fa igbo, bẹẹ ni wọn tun maa n mu ọtin.

Fun wọn, iwa ree ati iṣẹ ti eeyan n ṣe ni ẹsin.

Itan wọn fi han pe ẹni to da ẹka ẹsin naa silẹ, Ibrahima Fall, kọkọ pade Cheikh Ahmadou Bamba, ni ọpọ ọdun sẹyin, lati da ẹgbẹ kan ni Sufi Islam silẹ, eyii to milẹ titi ni Senegal.

A gbọ pe ṣe ni Fall yii n sin Bamba titi ti ko fi gbọ ti ara rẹ, koda wọn ni ko ri aye fun ounjẹ, aawẹ gbigba, irun kiki ati itọju ara rẹ.

Ifaraẹnijin olori wọn yii ni awọn ọmọlẹyin rẹ n tẹle titi di oni yii.

Mbacke Kadior

Awọn ọkunrin wọn mura siṣẹ gidi, iṣẹ adirẹ ni wọn si yan laayo lati maa fi aṣọ da oniruru ara.

Ọkan ninu wọn, Ọgbẹni Samba sọ fun BBC pe eeyan le jẹ Musulumi ko ma si sọ aṣa rẹ nu.

O ni "Ṣugbọn kii ṣe gboggbo eeyan ni oye yii ye… A maa n sọ pe ti eeyan ko ba korira awọn alatako, ko le ni itẹsiwaju."

Nigba ti awọn Musulumi mii ba n gbaawẹ lasiko oṣu Ramadan, awọn lo maa ṣeto ounjẹ ti wọn yoo fi ṣinu.

Yatọ si eyii, wọn ti da oniruru ẹgbẹ adojutofo silẹ, to fi mọ awọn ileeṣẹ atawọn ajọ ti kii ṣe ti ijọba ti wọn fi n ran awọn eeyan lọwọ.

Samba sọ pe "A ni awọn ile ẹkọ, ile iwosan ati ibi ti a ti n pese iṣẹ fun awọn eeyan."

Maam Samba
BBC
We want to create more employment - because young people need it here in Senegal"
Maam Samba
Leader of a Baye Fall group in Mbacke Kadior

Amọ ṣa, awọn eeyan ti bu ẹnu atẹ lu ẹgbẹ naa pe wọn n tọrọ owo larin ilu.

Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe eewọ ninu ẹsin wọn lati tọrọ owo, igbagbọ wa pe ṣe ni wọn maa n pin owo naa fun awọn alaini lawujọ.

Lara awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni Keaton Sawyer, ọmọ ilẹ Amẹrika to darapọ mọ wọn lasiko abẹwo rẹ sibẹ lọdun 2019.

O ni igba ti oun darapọ mọ ẹgbẹ naa ni igbeaye oun yipada.

 Baye Fall members

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọdọdun ni wọn maa n bura atilẹyin fun olori wọn ti wọn n pe ni 'caliph' tabi 'grand marabout.'

Awọn naa lo n bojuto Mọṣalaṣi nla ilu Touba ni Senegal.

Ni Touba, awọn lo n ṣiṣẹ ẹṣọ alaabo ni gbogbo ti isin nla ba n waye ni Mọṣalaṣi ọhun ti ọpọ eeyan ba peju si.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ Musulumi ni Senegal ni ko gba ti wọn, ojojumọ ni wọn n pọ si.

Baye Fall followers

Oríṣun àwòrán, Getty Images