Àwọn ohun tí Donald Trump ń gbèrò láti ṣe kété tí wọ́n bá búra fún un tán gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Amẹrika lónìí

Aworan Donald Trump ati aya rẹ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Aaya bẹ silẹ o bẹ sare ni Donald Trump fẹ fi ipadabọ rẹ sipo ipo aarẹ orilẹede Amẹrika lẹẹkeji ṣe lẹyin to sẹleri lati buwọlu awọn eto kan kete ti wọn ba ti bura fun un tan lọjọ Aje ogunjọ oṣu Kinni yii.

Trump ti kede pe lara awọn eto toun yoo ṣiṣẹ le lori naa ni ọrọ awọn eeyan to n wọ orilẹede Amẹrika lọna aitọ, ọrọ oju ọjọ, eto lori ẹlẹyamẹya atawọn eto mii.

Ohun to wọpọ ni ki aarẹ Amẹrika ti wọn ba ṣẹṣẹ bura fun un tan buwọlu awọn eto kan kete lẹyin iburawọle ijọba rẹ.

Igbesẹ ti Trump ba buwọlu yoo dofin lẹsẹ kẹsẹ, amọ, aarẹ mii to ba jẹ lọjọ iwaju si le ṣe ayipada rẹ.

Wọnyi lawọn eto ti Trump fẹ ṣiṣẹ le lori lonii ọjọ ogunjọ oṣu Kinni ti wọn ba ti bura fun un tan:

Ọrọ ibode ati wiwọ Amẹrika lọna aitọ

Trump ti sẹleri lati gbe eto kan kalẹ eyi to yii ri si bi ijọba rẹ yoo ṣe le awọn to n gbe orilẹede Amẹrika lọna aitọ.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Fox News sẹ sọ, Trump yoo paṣẹ pe kawọn ọmogun lọ maa ṣọ ibode guusu orilẹede Amẹrika.

Bakan naa ni Trump tun kede oun yoo fopin si ofin to dena mawọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si wiwọle si Amẹrika lati fọwọ ofin mawọn eeyan nile ṣoọṣi ati lawọn ile ẹkọ.

Lara awọn ofin ti Trump yoo tun fopin si ni awọn to ba bimọ si Amẹrika ti iru awọn ọmọ naa maa di ọmọ ilu Amẹrika.

Trump tun ṣetan lati kede awọn to n gbe egboogi oloro gẹgẹ bii ẹgbẹ agbesunmọmi bii Al Qaeda, IS ati Hamas.

O tun ṣee ṣe ki Trump tẹsiwaju kikọ odi si ibode Amẹrika eyi to bẹrẹ nigba to jẹ aarẹ Amẹrika fun igba akọkọ lọdun 2016 si 2020.

Okowo ati ọrọ aje

Trump tun ti ṣeleri afikun owo ori lori awọn ọja ti wọn n ko wọ orilẹede Amẹrika lati le ṣe koriya fawọn ileeṣẹ to wa l'Amẹrika.

Trump ṣe agbekalẹ eto owo ori kan ni saa rẹ akọkọ eleyii ti Joe Biden naa tẹle.

Amọ, lọwọ yii ida 10% owo ori ni Trump n gbero lati fi sori gbogbo nnkan ti wọn n ko wọ Amẹrika, ida 25% owo ori lori ọja to n wa lati Canada ati Mexico nigba ti owo ori ida 60% yoo wa lori awọn ọja to n wọle lati orilẹede China.

Trump ti sọ lọjọ kete lẹyin iburawọle ijọba oun loun yoo buwọlu eto yii, bo tilẹ jẹ pe awọn kan ti kọminu wi pe igbesẹ yii le fa ọwọngogo nnkan l'Amẹrika.

Ọrọ oju ọjọ ati ohun amuṣagbara

Trump ti kede pe oun ṣetan lati fopin sawọn igbesẹ kan ti ijọba Aarẹ Joe Biden gbe lori ọrọ oju ọjọ ati ohun amuṣagbara.

Ijọba Aarẹ Biden buwọlu awọn ofin kan ati owo kan ti ijọba yoo lo lati gbogun ewu inu afẹfẹ.

Trump ti sọ pe gbogbo ofin yii ni ijọba oun yoo ṣe ayipada wọn.

Bakan naa ni Trump tun ṣeleri lati ṣe afikun ipese ohun amuṣagbara lorilẹede Anmẹrika.

Trump tun ṣeleri loti fopin si akanṣe iṣẹ to n lọ lọwọ lori iji.

O tun ni oun ṣetan lati da siṣe ọkọ ayọkẹlẹ ti yoo maa lo ina ẹlẹtitiki duro.

Rogbodiyan ile aṣofin Capitol

Ọpọ eeyan lo ti foju wina ofin nitori rogbodiyan to bẹ silẹ nile aṣofin Capitol lọdun 2021.

Awọn eeyan yii lo n reti ikede idasilẹ wọn lọgba ẹwọn kete ti Trump ba ti ṣe iburawọle tan lonii ọjọ Aje.

Ṣaaju ni Trump ti sọ fun CNN pe oun yoo kede ominira fun ọpọ awọn eeyan naa.

Eeyan to le ni ẹgbẹrun kan ati abọ lawọn agbofinro mu nibi rogbodiyan naa.

O kere tan eeyan bi ẹgbẹta ni fẹsun kan wi pe wọn ṣe ikọlu sawọn agbofinro.

Iwe aṣiri iṣẹlẹ ipaniyan

Trump sọ lọjọ Aiku ọjọ kọkandinlogun oṣu Kinni pe oun yoo gbe awọn akọsilẹ aṣiri kan lori iṣekupani Aarẹ John F. Kennedy lọdun 1963.

Ọpọ eeyan lo ti n sọ oriṣiiriṣii nnkan nipa iṣẹlẹ naa.

Trump tun ni oun yoo tun gbe iwe akọsilẹ aṣiri lori iṣekupani Sẹnẹtọ Robert Kennedy ati ajafẹtọọ Martin Luther Jr.

Ọrọ ilẹ okeere

Ti ẹ o ba gbagbe, Trump ṣeleri lasiko ipolongo ibo pe oun yoo fopin si ogun to n lọ laarin orilẹede Russia ati Ukraine.

Amọ, o tun sọ pe o le to oṣu mẹfa ki oun to ri ogun naa pari patapata.

Bakan naa, Trump tun le lo agbara gẹgẹ bi aarẹ Amẹrika lati fagile igbesẹ Aarẹ Biden to yọ Cuba kuro ninu awọn orilẹede to n ṣagbatẹru igbesunmọmi.

O tun le da ofin ti Amẹrika fi de orilẹede Venezuela naa pada.

Ọrọ lori oyun siṣẹ

Gẹgẹ bi awọn aarẹ to jẹ ṣaaju rẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Republican, Trump yoo da ofin ti ko faye gba oniruuru ẹgbẹ lati maa gba awọn eeyan ni imọran lori oyun siṣẹ.

Bakan naa, Trump ṣetan lati da ofin ti ijọba fi de awọn ile iwosan lati maa sọ nipa oyun siṣẹ fawọn eeyan.

Igbesẹ yii yoo jẹ ki ọpọ ajọ to n ṣagbatẹru oyun siṣẹ padanu ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu dọla.

Trump tun ṣetan lati fopin si awọn ko-sakọ-ko-sabo lati maa kopa ninu ere idaraya awọn obinrin.

TikTok

Oju opo ikansiraẹni TikTok ti pana lorilẹede Amẹrika, wakati diẹ si gbedeke ifidimulẹ odin to wọgile e lorilẹẹdẹ naa.

Atẹjiṣẹ kan jade lori opo ayelujara naa fun awọn to n lo o lorilẹẹdẹ Amẹrikape wọn ti ṣe ofin kan to de TikTok nibẹ nitorinaa, "o ko le e lo TikTok lọwọ yii".

Aarẹ Joe Biden ti sọ pe oun yoo fa igbesẹ to kan lori ọrọ naa le Donald Trump ti yoo gba ipo lọwọ oun lọwọ.

Amọṣa o Trump ti sọ pe bi oun ba ti gba ọpa aṣẹ ipo aarẹ lọjọ Aje, o ṣeeṣe ki oun fun ileeṣẹ TikTok ni anfani aadọrun ọjọ lati wa nnkan ṣe lori ọrọ naa.