Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ẹlẹ́wọ̀n tí Gómìnà Adeleke dá sílẹ̀ tó tún padà dèrò ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́jọ tó gbòminira

Aworan gomina Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Senator Ademola Adeleke/Adeleke

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iroyin ọdọkunrin kan nipinlẹ Osun, Sunday Omisakin to wa lara awọn ẹlẹwọn ti Gomina Ademola Adeleke da silẹ loṣu Kejila to kọja mi ori ayelujara titi nitori bi o ṣe pada dero ẹwọn lẹyin ọjọ mẹjọ to gbominira.

Omisakin lo wa ni nọmba kẹjọ ninu iwe orukọ awọn ẹlẹwọn naa to le laadọta ti gomina ipinlẹ Osun da silẹ lọgba ẹwọn.

Ọpọ eeyan lo tiẹ n ro pe Segun Olowookere ti wọn ti dajọ iku fun ti gomina da silẹ ni Omisakin tun pada dero ẹwọn yii.

Lara iyatọ to wa laarin awọn mejeeji ni pe kii ṣe idajọ iku ni wọn da fun Omisakin to pada dero ẹwọn fun igba keji yii.

Ta a ni Sunday Omisakin to pada sọgba ẹwọn lẹyin ti gomina Osun da a silẹ tan?

Ọgbẹni Omisakin ni a gbọ pe o tun pada sọgba ẹwọn to wa niluu Ilesa bayii lori ẹsun pe o ji ẹrọ amohunmaworan ninu ile kan niluu Osogbo.

Ile ẹjọ majisireeti kan niluu Osogbo lo paṣẹ wi pe ki wọn ju Ọgbẹni Omisakin sọgba ẹwọn.

Omisakin lo wa ni nọmba kẹjọ ninu awọn ẹlẹwọn ti gomina ipinlẹ Osun paṣẹ idasilẹ wọn lọjọ kẹrinlelogun oṣu kejila ọdun 2024 to kọja.

Ọgbẹni Omisakin n ṣẹwọn tẹlẹ lẹyin to jẹbi awọn ẹsun ọdaran ti wọn fi kan an pẹlu Segun Olowookere ati Sunday Morakinyo ti wọn gba idajọ iku lori ẹsun idigunjale ati jiji adiẹ gbe niluu Oyan nipinlẹ Osun.

Omisakin pada sẹwọn lori ẹsun pe o ji tẹlifisan l'Osogbo

Iwe ipẹjọ tawọn oniroyin ri nile ẹjọ majisireeti niluu Osogbo lọjọ Iṣẹgun ṣafihan pe ọjọ kẹta oṣu Kinni ni Omisakin lọ jale ninu ile kan lagbegbe Iludun niluu Osogbo ti o si ji tẹlifisan ti wọn sọ pe owo rẹ to N600,000 gbe.

Ile ẹjọ sọ pe iwa ti Omaskin hu yii lodi si ofin to gbogun ti iwa ọdaran apa 411(1) ati ẹka ofin apa 34 ipinlẹ Osun.

Omisakin bẹ ile ẹjọ majisireeti lati fun un ni beeli nigba ti igbẹjọ rẹ kọkọ waye.

Olupẹjọ Kayode Adeoye tako ẹbẹ Omisakin eyi to fi n beere fun beeli.

Lẹyin naa ni Adajọ majisireeti A. Adeyeba yi ẹbẹ beeli naa danu ti o si paṣẹ pe ki wọn ju Omisakin si ọgba ẹwọn pada niluu Ilesa.

Adeleke tu Olowookere Segun ati ẹlẹwọn 52 mii silẹ lọgba ẹwọn

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti dariji Olookere Segun to gba idajọ iku lẹyin to digunjale nipinlẹ naa, to si ji adiye lọdun mẹrinla sẹyin.

Yatọ si ọdọkunrin ọhun, Adeleke tun foriji awọn ẹlẹwọn mii ti iye wọn to mejilelaadọta.

Agbẹnusọ gomina ọhun, Olawale Rasheed lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan.

Adeleke ni oun gbe igbesẹ naa gẹgẹ bii agbara ti ofin orilẹede Naijiria ti wọn kọ lọdun 1999 fun oun.

Awọn ẹlẹwọn ti Adeleke dariji lori ẹsun kekeke

1. Olabomiji Nurudeen

2. Mustapha Isah

3. Olalekan Abdullahi

4. Ayomide Olojede

5. Akeem Raphael

6. Adeyemi Abiodun

7. Oladipupo Segun

8. Omisakin Sunday

9. Ademola Adio

10. Tunde Olapade

11. Late Chief Wole Ola Rufus Ojo

12. Omoloye Olajide Olayemi

Awọn Ẹlẹwọn ti Adeleke ni ki wọn tu silẹ lẹsẹkẹsẹ

1. Olubo Sunday

2. Isah Umar Biodun

3. Fawas Kareem

4. Omirin Temitayo

5. Olarenwaju Ayomide

6. Dare Sunday

7. Oladapo Tunde

8. Ganiyu Saheed

9. Adewumi Sodiq

10. Adebayo Adeoye

Kehinde

11. Lasis Kazeem

12. Dauda Ojo

13. Ismaila Raji

14. Oseni Micheal

15. Ajayi Korede

16. Abiona Nurudeen

17. Oshi Samuel

18. Sheu Yusuf Olatunji

19. Ojo Aanu

20. Mustapha Kehinde

21. Lasis Abeeb

22. Alexandra Iorlaha

23. Ojo Taiwo

24. Azeez Mujeeb

25. Akinyemi David

26. Adeosun Adekunle

27. Olaobaju Samuel

28. Adura Adefemi

29. Paul Basil

30. Kunle David

Awọn ẹlẹwọn ti yoo gba itusilẹ nitori wọn ti yipada

1. Sunday Morakinyo

2. Segun Olowookere

3. Tunde Olapade

4. Demola Odeyemi

Awọn ẹlẹwọn ti wọn yoo gba itusilẹ nitori ilera wọn

1 Oluwafemi Fagbemi

2 Bewaji Sunday

3. Amehin George

4. Ayomide Arulogun

5. Taiwo Oluwatobi Stephen

6. Abubakar Abdulazeez

Ẹlẹwọn ti wọn yi idajọ iku rẹ si ọdun mẹẹdogun lẹyin to ti ṣẹwọn ọdun mẹwaa

Ijekunle Timothy