Èèyàn 18 pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàm̀bá ọkọ̀ n'Ilorin

Aworan Ijamba Oko niluu Ilorin
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

O kere tan eeyan mejidinlogun lo padanu ẹmi wọn lana nibi iṣẹlẹ jamba ọkọ to ṣẹlẹ ni ilu Ilọrin, ipinlẹ Kwara.

Iṣẹlẹ ijamba ọkọ naa waye ni nnkan bii ago mẹrin irọlẹ ana ọjọru ọjọ kejilelogun oṣu kinni ọdun 2025.

Opopona marosẹ Ẹyẹnkọrin si oko-olowo ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Ọpọlọpọ maluu lo ba iṣẹlẹ naa lọ.

Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ ijamba ọkọ naa soju ẹ, Ọgbẹni Jamiu Ayinde to ba aṣoju kọroyin ile iṣẹ BBC Yoruba sọrọ nipa iṣẹlẹ naa sọ pe, ọkọ Ajagbe to ko maluu ati eeyan n bọ lati oke ọya lo lọ kọlu ọkọ Ajagbe mi ati ọkọ akero to n bọ lati Oko-Olowo.

Aworan oko

Ninu ọrọ rẹ, Alukoro ajọ to n mojuto igbokegbodo ọkọ loju popo nipinlẹ Kwara, KWATMA Ọgbẹni Ọlawuyi sọ pe, iṣẹlẹ naa bani lọkan jẹ pupọ, o wa parọwa sawọn ọlọkọ lati ma se pẹlẹ pẹlẹ lojupopo.

Ọgbẹni Ọlawuyi fìdi ẹ mu lẹ pe ,eeyan mejidinlogun lo ba iṣẹlẹ na lọ.

Lasiko to n sọrọ lori iṣẹlẹ na, Ọga agba ajọ to n mojuto igbokegbodo ọkọ Enginner Michael Bamidele parọwa sawọn ọlọkọ lopopona mọnrose Ẹyẹkọrin lati ma se pẹlẹ pẹlẹ lopopona na.

Enginner Bamidele wa ba awọn mọlẹbi awọn to padanu ẹmi wọn kẹdun lori iṣẹlẹ na.

Eyi kọ ni iṣẹlẹ akọkọ ijamba ọkọ ti yio gbẹmi ọpọlọpọ eyan lagbegbe na latari ere asapajude awọn ọlọkọ lopopona mọnrose na.

Osi ti pẹ tawọn eeyan agbagbe naa ti rọ ijọba ipinlẹ Kwara lati bawọn wa ikan se si ki adinku le de ba iṣẹlẹ to n gba ẹ,i awọn eeyan.

Se ni wọn ja ewe bo oku awọn to padanu ẹmi wọn ni ibi iṣẹlẹ naa, tawon eeyan si n sun ẹkun asungba