Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ dá ẹ̀bùn jọ fún olùkọ́ láti fi ẹ̀mí ìmoore hàn

Olùkọ́ Olagunju àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń fun ní ẹ̀bùn

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Wọ́n ti ní ìwà kankan kìí gbé yálà bó jẹ́ ire tàbí ibi.

Níṣe ni ìdùnnú ṣubú lu ayọ̀ fún olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Obafemi Awolowo University, OAU, Ile Ife, ìpínlẹ̀ Osun báwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ṣe dá ẹ̀bùn jọ fun lásìkò tí wọ́n wà ní kíláàsì.

Fídíò kan tó gba orí ayélujára èyí tí ẹnìkan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ @doxaleey gbé síta lórí TikTok ṣàfihàn báwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe ń dá ẹ̀bùn jọ fún olùkọ́ náà tó pe orúkọ rẹ̀ ní ọ̀mọ̀wé Olagunju.

Fídíò náà ṣàfihàn báwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún ṣe ń dìde ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, tí wọ́n sì ń olùkọ́ ọ̀hún lẹ́bùn sí ìyàlẹ́nu rẹ̀.

Ẹni tó fi fídíò náà léde kọ ọ́ sábẹ́ rẹ̀ pé àwọn ti ń wá ọ̀nà láti fi ẹ̀mí ìmoore hàn sí olùkọ́ náà fún iṣẹ́ takuntakun tó ń ṣe àti ìfarajìn rẹ̀ sí iṣẹ́.

Ó ní ọ̀nà táwọn le gbà fi ẹ̀mí ìmoore àwọn hàn ni àwọn ṣe náà.

"Pẹ̀lú gbogbo ìpèníjà láti máa kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ láti ipele àkọ́kọ́ sí ìpele tó kẹ́yìn, Dókítà Olagunju ní ìfarajìn sí ètò ẹ̀kọ́ wa. Gbogbo ìlàkàkà rẹ̀ ni a rí, a sì dúpẹ́ fún ipa rere tó ń ní lórí ẹ̀kọ́ wa.

"Inú wa dùn pé a ní àǹfàní láti fi ẹ̀mí ìmoore wa hàn, tí a sì gbèrò láti ṣe jù báyìí lọ."

Ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà, nínú fídíò náà, ló kọ́kọ́ dìde láti lọ fún olùkọ́ náà ní omi inú ike kí àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ mìíràn náà sì tó dìde láti máa dá ẹ̀bùn jọ síwájú olùkọ́ ọ̀hún.

Fídíò ọ̀hún ṣàfihàn bí olùkọ́ Olagunju ṣe ń rẹ́rìn-ín láti fi ìdùnnú rẹ̀ hàn lórí ìwà àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.