Àjọ SEC kìlọ̀ lórí àwọn ayédèrú iléèṣẹ́ olùdókòwò kan tó gbòde ní Naijiria

Aworan awọn ẹgbẹrun kan naira ti ọwọ kan ko dani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ to n ri si idokoowo ati paṣipaarọ lori ayelujara lorilẹede yii, Securities and Exchange Commission (SEC), ti kilọ fun awọn oludokowo lati ma ṣe ba ileeṣẹ kan ti a mọ si UYJ Multitrade da nnkan kan pọ rara.

Bakan naa ni wọn darukọ ileeṣẹ kan naa ti a mọ si MY SHARE, bii eyi ti ko forukọ silẹ rara labẹ ofin iṣẹ idokoowo.

SEC sọ lopin ọsẹ to kọja, pe ileeṣẹ ti ko ba ofin mu ni Uyj Multitrade ati AY SHARE.

Ninu atẹjade ti SEC fi sita ni wọn ti ṣalaye pe ayederu ileeṣẹ idokowo ni Uyj Multitrade to n pe ara ẹ ni oludamọran lagbo idokowo ati paṣipaarọ ni Naijiria.

Eyi ni wọn ṣe ni ki ẹnikẹni to ba n da owo pọ pẹlu ileeṣẹ meji yii lọọ mọ pe jibiti ni wọn n kọwe si.

" A fi eyi kilọ fun gbogbo eeyan lati ma ṣe ba ileeṣẹ MY SHARE ati UYJ MULTITRADE LIMITED da ohunkohun pọ lọna okoowo lọja idokowo ni Naijiria.

" Ajọ yii n tẹ ẹ mọ gbogbo ọmọ Naijiria leti, pe dida okoowo pọ pẹlu awọn ileeṣẹ ti ko fi orukọ silẹ yoo ko yin si wahala ati jibiti, o si le mu eeyan padanu pẹlu ."

" A n fi eyi ran awọn eeyan to n da okowo lawujọ wa leti, pe o ṣe pataki lati wadii ileeṣẹ ti wọn ba da nnkan pọ wo daadaa. Ki wọn fidi ẹ mulẹ pe orukọ ileeṣẹ naa wa lakọsilẹ lọdọ SEC.''

Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa ṣalaye.

Oju opo, www.sec.gov.ng/cmos, ni SEC fi sita lati ṣe iwadii ki eeyan too ba ileeṣẹ kankan da òwò pọ.