Ẹ̀mí ṣòfò, èèyàn mẹ́rin farapa, ọ̀pọ̀ dúkìá jóná nínú ìjàmbá iná lórí afárá Otedola l'Eko

Ẹmi eeyan kan ti sọnu, eeyan mẹrin mii farapa, nigba ti ọpọ dukia ṣofo lẹyin ti ọkọ ajagbe to gbe afẹfẹ gaasi ṣubu lulẹ lagbegbe afara Otedola, niluu Eko.
Ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri l'Eko, LASEMA lo fidi iroyin naa mulẹ ninu atẹjade to fi ṣọwọ si awọn akọroyin.
Adari LASEMA, Femi Oke-Osanyintolu sọ ninu atẹjade naa pe, gende ọkunrin mẹta ti ina jo lawọn ti gbe lọ sile iwosan ijọba to wa ni Gbagada bayii, nigba ti wọn ri oku ọkunrin kan yọ jade nibẹ.
O ni awọn ṣe iṣẹ takuntakun lati ri daju wọn pa ina naa.
"A si rọ gbogbo awakọ lati wa ọna mii ti wọn le gba lọna ati yago fun ibi ti iṣẹlẹ yii ti bẹrẹ."
Ṣaaju atẹjade naa ni Oke-Osanyintolu sọ pe ẹka Tiger Response Team ajọ naa ti de agbegbe ọhun lati bẹrẹ iṣẹ.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, wọn ti di gbogbo ọna to wọ agbegbe naa lati daabo bo awọn awakọ mii.

Yatọ si LASEMA, ileeṣẹ to n ri si irinkerindo ọkọ niluu Eko, LASTMA tun fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ.
Ẹwẹ, akọroyin BBC to lọ sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye jabọ pe ọpọ dukia lo ba iṣẹlẹ ọhun lọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ọpọ Kẹkẹ Maruwa atawọn ọkọ mii lo jona nibẹ.

Akọroyin wa tun ba awọn ti dukia wọn jona nibẹ sọrọ, nibi ti awọn eeyan ọhun ti sọ pe iṣẹlẹ naa da omi tutu si ọkan awọn.
Ọkan ninu awọn eeyan naa sọ pe "Ẹ wo Kẹkẹ Maruwa mi, o ti jona guruguru. Kẹkẹ yii ni mo fi n bọ awọn mọlẹbi mi o.
"Wọn gbọdọ ra Kẹkẹ mii fun mi ni, bi bẹẹ kọ mo maa ba ileeṣẹ gaasi naa fa wahala."
Lẹyin naa lo ke si ijọba ipinlẹ fun iranlọwọ fun dukia ti oun padanu.















