Njẹ́ o mọ̀ pé ìjọba kìí pa àwọn tílé ẹjọ́ bá dájọ́ ikú fún ní Naijiria? Ìdí rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Láìpẹ́ yìí ni adarí àjọ tó ń rí sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Nàìjíríà, Sylvester Nwakuche di ẹ̀bi báwọn ẹlẹ́wọ̀n ṣe ń lékún ní ọgbà ẹ̀wọ̀n káàkiri Nàìjíríà ru àwọn gómìnà.
Nwakuche, nígbà tó ń bá ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ abẹ́lé Nàìjíríà ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà sọ̀rọ̀, sọ pé àwọn gómìnà kìí fẹ́ buwọ́lu pípa àwọn tí ilé-ẹjọ́ ti dájọ́ ikú fún tàbí yí ìdájọ́ náà padà sí ẹ̀wọ̀n gbére.
Ó ní iye àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ilé ẹjọ́ ti dájọ́ ikú fún ti tó wà láwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n káàkiri Nàìjíríà ni wọ́n ti pé 3,688 báyìí àmọ́ ti ohunkóhun kò ṣẹlẹ̀ sí wọn.
Ó kọminú pé èyí mú àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n máa kún ju bí ó ṣe yẹ lọ àti pé àwọn nílò ìgbésẹ̀ ní kíákíá láti mú àdínkù bá iye èèyàn tó wà ní àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n.
Ó wòye pé táwọn gómìnà bá buwọ́lu pípa àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n dájọ́ ikú fún náà tàbí yí ìdájọ́ wọn padà sí ẹ̀wọ̀n gbére yóò ṣe ìrànwọ́ fún mímú àdínkù bá èrò tó pọ̀ jù láwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n.
Èyí ló mú wa ṣe ìwádìí ohun tó fà á gan táwọn gómìnà kìí fẹ́ buwọ́lu pípa àwọn tí ilé-ẹjọ́ bá dájọ́ ikú fún.
Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni wọ́n máa ń gbé ìdájọ́ ikú kalẹ̀ fún?
Lábẹ́ ìwé òfin ìwà ọ̀daràn Nàìjíríà, ìwà ìpànìyàn, ìgbéṣùmọ̀mí, ìdigunjalè, ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ fún ìpànìyàn lọ́nà àìtọ́, ìdìtẹ̀gbàjọba jẹ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ilé ẹjọ́ fi le gbé ìdájọ́ ikú kalẹ̀ fún ọ̀daràn.
Tí ilé ẹjọ́ bá ti lè rí àwọn láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn jẹ̀bi ọ̀kan nínú àwọn ìwà tó wà lókè yìí, adájọ́ ní àṣẹ láti dájọ́ ikú fún irú ẹni bẹ́ẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí abala kẹtàlélọ́gbọ̀n ìwé òfin Nàìjíríà ṣe sọ, aláboyún tàbí ọmọdé tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò ì tíì pé ọdún méjìdílógún ni òfin yọ sílẹ̀ bíi ẹni tí wọ́n le dájọ́ ikú fún, tí wọ́n fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn yìí.
Ẹ̀wọ̀n gbére ni wọ́n máa fi aláboyún àti ọmọdé bẹ́ẹ̀ sí.
Gẹ́gẹ́ bí òfin, ọ̀nà mẹ́rin ni wọ́n lè gbà láti fi pa ẹni tí wọ́n bá dájọ́ ikú fún.
Ó le jẹ́ nípa yíyẹgi fún èèyàn, èyí tí wọ́n máa so ọrùn ọ̀daràn náà mọ́ òkè títí tí ẹ̀mí yóò fi bọ́ lọ́rùn rẹ̀ tàbí kí wọ́n fi ẹ̀yìn rẹ̀ ti àgbá tí wọ́n sì máa yìnbọn pa á.
Ọ̀nà mìíràn ni nípa sísọ òkúta lu ọ̀daràn títí ẹ̀mí yóò fi bọ́ lọ́rùn rẹ̀. Èyí tó gbẹ̀yìn tí ìjọba Nàìjíríà buwọ́lu lọ́dún 2015 ni fífún ọ̀daràn lábẹ́rẹ́ ikú kí ẹ̀mí fi tètè bọ́ lọ́rùn rẹ̀ láì jẹ ìrora tó pọ̀.
Àwọn ọ̀nà tí wọ́n máa ń gba pa ẹni tí wọ́n bá dájọ́ ikú fún

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Amòfin kan, Kingdom Chikezie Collins sọ fún BBC pé èèyàn mẹ́ta ló máa ń lọ́wọ́ nínú bí wọ́n ṣe máa pa ẹni tí ìdájọ́ ikú bá wà fún.
Ó ṣàlàyé pé àkọ́kọ́ ni adájọ́ tó gbé ìdájọ́ náà kalẹ̀. Ó ní adájọ́ gbọdọ̀ sọ ọ̀nà tí wọ́n máa gbà láti pa ọ̀daràn tí wọ́n bá dájọ́ ikú fún.
Lẹ́yìn náà ló kan gómìnà tó máa buwọ́lu àṣẹ ilé ẹjọ́ láti ọ̀daràn bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n bá gbé ìwé ẹni bẹ́ẹ̀ lọ síwájú rẹ̀.
Ẹni tó gbẹ̀yìn ni ẹni tí yóò ṣekúpa ọ̀daràn tí wọ́n bá dájọ́ ikú fún.
Collins ṣàlàyé pé ní kété tí òfin bá ti gbé ìdájọ́ kalẹ̀, ó pọn dandan fún àwọn aláṣẹ láti ṣàgbékalẹ̀ ìlànà tí ìdájọ́ náà fi máa wá sí ìmúṣẹ ní ìlànà àti ìbámu pẹ̀lú òfin.
Ó ní tí òfin bá sọ pé nípa yíyẹgi ni kí wọ́n fi pa ọ̀daràn, wọn ò gbọdọ̀ ṣe àmúlò ìlànà mìíràn, táwọn aláṣẹ sì gbọdọ̀ wá ẹni tí yóò ṣe àmúṣẹ ìdájọ́ ọ̀hún.
Ó fi kun pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kàn wá, bíi ìdìtẹ̀gbàjọba, tí àwọn gómìnà kò láṣẹ lórí rẹ̀, pé ìjọba àpapọ̀ nìkan ló ní àṣẹ láti buwọ́lu pípa ẹni bẹ́ẹ̀.
Kí ló dé táwọn gómìnà kìí fẹ́ buwọ́lu ìdájọ́ ikú fáwọn ọ̀daràn?
Nítorí àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn ni ọ̀pọ̀ àwọn gómìnà kìí fẹ́ buwọ́lu ìdájọ́ ikú fáwọn ọ̀daràn.
Dípò bíbuwọ́lu ìdájọ́ ikú wọn, wọ́n máa ń fi wọ́n kalẹ̀ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n láì ní gbèdéke kankan.
Kí wọ́n tó lè pa ọ̀daràn lọ́gbà ẹ̀wọ̀n kan, wọ́n nílò láti gba àṣẹ lọ́wọ́ gómìnà ìpínlẹ̀, tó sì jẹ́ pé ọ̀pọ̀ gómìnà ni kìí tọwọ́bọ ìwé àṣẹ náà.
Láti ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n tí ọ̀daràn náà bá wà ni wọ́n ti máa gbé ìwé náà ránṣẹ́ sí gómìnà fún ìbuwọ́lù.
Amòfin Adata Bio-Briggs sọ fún BBC pé ọ̀pọ̀ àwọn gómìnà kìí fẹ́ buwọ́lu ìwé náà nítorí ó ṣòro láti buwọ́lu pé kí wọ́n lọ pa èèyàn.
Amòfin náà ṣàlàyé nǹkan mìíràn tó fi máa ń ṣòro fáwọn gómìnà láti buwọ́lu ìdájọ́ ikú nib í wọ́n ṣe máa ń kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n bá dájọ́ ikú fún láti ìpínlẹ̀ kan lọ sí òmíràn.
Ó ní òfin fi ààyè gba àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n láti kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n wà lábẹ́ ìdájọ́ ikú láti ìpínlẹ̀ kan lọ sí òmíràn.
Ó ní gómìnà ìpínlẹ̀ tí wọ́n sì ti ṣe ìdájọ́ ẹlẹ́wọ̀n sì ni ó láṣẹ láti buwọ́lu ìdájọ́ ẹni bẹ́ẹ̀. Ó ní ìdíwọ́ ni fún gómìnà láti buwọ́lu ikú ẹni tí kò sí ní ìpínlẹ̀ rẹ̀, tí gómìnà ìpínlẹ̀ míì kò sì lè sẹ é.
Nǹkan mìíràn tó lè ṣe ìdíwọ́ pípa ẹni tí wọ́n dájọ́ ikú fún ni tí kò bá sí ẹni tí yóò pa ọ̀daràn náà. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ṣáájú pé ipele mẹ́ta ni ọ̀nà pípa ọ̀daràn máa ń gbà wáyé.
Ọ̀pọ̀ àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn ló ti ń pè fún pé kí ìjọba pa òfin pípa èèyàn rẹ́ ní Nàìjíríà dípò bẹ́ẹ̀ kí wọ́n máa fi àwọn ọ̀darà sẹ́wọn gbére.
Wọ́n ní pípa ọ̀daràn kò ní sọ pé kí ẹni tó ti kú dìde àmọ́ wọ́n yóò lo gbogbo ìgbé àye tó kù nínú ẹ̀wọ̀n.















