Àwọn ọlọ́jà àti iléeṣẹ́ panápaná ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ síra wọn lórí ọjà Aleshinloye tó jóná n'Ibadan

Aworan ijamba ina ninu ọja Aleshinloye

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọpọ awọn ara ọja Aleshinloye to wa niluu Ibadan to jẹ olu ilu ipinlẹ Oyo lo ti na ika abuku si ileeṣẹ panapana ipinlẹ naa fun bi wọn ko si ri ina to sẹyọ ninu ọja naa pa.

Ni aṣalẹ, ọjọ kọkanla oṣu kẹta ọdun 2025 ni ina sẹyọ ninu Ọja Aleshinloye, ti ọpọ nnkan ọja to le ni ọpọ milọnu si jona kọja idanimọ.

Ohun ti a ri gbọ ni pe iṣẹlẹ naa sẹlẹ ni nnkan bi ago mẹsan an alẹ, ti ina si bẹrẹ si ni ran gbogbo awọn ike, sọọbu ati awọn ọja to wa ninu rẹ.

Ohun pato to ṣokunfa ina ọhun ni a ko ti mọ.

Ọkan lara awọn to ba awọn akọroyin sọrọ ti ko darukọ rẹ ṣalaye pe ohun to jẹ ohun iyalẹnu ju ni pe ina ọhun bẹrẹ ni sọọbu kan to wa ni ẹgbẹ ileeṣẹ panapana to wa ninu ọja naa ṣugbọn wọn ko ri nnkan se si to fi di pe o tan kaakiri ọja.

"Nigba ti wọn pe wa, ti de si ibi bayii, sọọbu ẹyọkan lo bẹrẹ, lati ọdọ awọn ileeṣẹ ina, ọdọ wọn lo ti bẹrẹ, wọn ko dẹ ri ina naa pa, ti wọn fi pe Iseyin.

"Emi ti ẹ n wo yii, ọmọ mi ni sọọbu ọgbọn ni ibi bayii, ti gbogbo wọn si ti jona. Ibo ni ki ọmọ mi ti bẹrẹ.

"Nnkan ti a sọ ni pe, a ni ileeṣẹ panapana ni ibi bayii, wọn ko ri nnkankan se, wọn ko ni omi, o dẹ wa loju pe ijọba ti pese rẹ fun wọn. Owo ṣofo lana.

"Ki awọn ti wọn pe to de ibi bayii, ile ọla ti wo, ọmọ mi Kudirah ti wa ni Ile iwosan bayii."

Alhaja T.A Bello, naa ba awọn akọroyin sọrọ pe sọọbu mẹwaa ni oun ni ninu ọja Aleshinloye, to si jẹ pe apapọ ọja to wa ninu awọn sọọbu naa lo to aadọta milọnu naira.

Bello ni oun ko ba nkankan to sẹku ninu sọọbu rara, to si jẹ pe oun padanu gbogbo rẹ pata.

Bakan naa lo tẹnu bọrọ nigba ti wọn bi pe awọn kan n fẹsun kan ijọba ipinlẹ Oyo pe wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ naa, Bello ni lo ti tọ ni pe awọn ti n gbọ firi pe ijọba fẹ wo awọn apa ibi kan ninu ọja ṣugbọn ọpọ awọn lo ti rawọ ẹbẹ si ijọba pe ki igbesẹ naa ma waye.

"Sọọbu mẹwaa lo jọna, gbogbo nnkan t imo ni nibẹ lo jona, to di eru. Nigba ti wọn pe mi, m oni ko si nnkan ti mo fẹ se, koda ana yii a ṣẹṣẹ ja awọn ọja tuntun. Gbogbo nnkan mi to jona to milọnu aadọta naira.

"Lo tọ ni pe a n gbọ pe wọn fẹ wo sọọbu ninu ọja Aleshinloye, ti a n rawọ ẹbẹ si ijọba lai mọ pe eyi ma waye."

Ki i se pe ileeṣẹ panapana to wa ninu ọja ko ṣiṣẹ- Oludamọran si Gomina

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ ninu ọja Aleshinloye, olubadamọran fun gomina lori iṣẹlẹ naa, Adebayo Akinwade ni o se koko ki awọn araalu ki ijọba lọwọ ninu idagbasoke ilu, to jẹ ko di mimọ pe ina naa ti ba nnkan jẹ pupọ ki wọn to ransẹ pe ileeṣẹ panapana.

Akinwande rọ awọn araalu pe ki wọn ba nnkan ilu jẹ nitori wọn binu. O ni ki n se pe ileeṣẹ panapana to wa ninu ọja naa ko sisẹ, ṣugbọn o ṣe ni laanu pe awọn ara ọja ko mọ nọmba ileeṣẹ panapana.

"Ileeṣẹ panapana to wa ninu ọja yii lo ransẹ pe wa pe ina n jo, ki I se araalu.

"Ki se pe ileeṣẹ naa ko sisẹ rara, awọn eeyan to wa nibẹ lo kesi wa, ti a si dupẹ lọwọ awọn ileeṣẹ aladani to kun wa lọwọ."